BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ṣé lóòtọ́ ni pé Tinubu lọ́wọ́ nínú wàhálà oyè Emir nílùú Kano nítorí ìyà Ado Bayero?
Ọjọgbọn Hashimu lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC, nibi to ti sọ pe oun ni ẹri maa jẹ mi rinṣo lati kin ọrọ oun lẹyin.
Wo ìlú tí àwọn kan ti ń pa ìrọ́ mọ́ àwọn arúgbó pé àjẹ́ ni wọ́n láti dọ́gbọ́n gba ilẹ̀ wọn
Africa Eye ṣawari ohun to fa a ti wọn fi n ṣeku pa awọn eeyan yii.
Wo bí wíwá omi mímu káàkiri láti pọn ṣe ń ṣàkóbá fáwọn obìnrin ní India
Ajọ WHO to n ri si eto ilera lagbaaye ati UNICEF to n ri si ọrọ awọn ọmọde sọ lọdun 2023 pe eeyan to din diẹ ni biliọnu meji (1.8b) lo n wa omi kiri tori ko si omi nile ti wọn n gbe.
Wo ìdí tí ṣíṣe nǹkan oṣù ṣe ń nira fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lórílẹ̀èdè Nàìjíríà jú àwọn akẹgbẹ́ wọn lágbáyé
Khairat Badamasi, olugbe ilu Abuja ba BBC sọrọ lori ohun to n dojukọ lori ọrọ paadi lasiko yii.
Èsì ìbò jáde ní France, ẹgbẹ́ òṣèlú Ààrẹ Macron fìdírẹmi, kò s’ẹ́gbẹ́ tó lè dá ìjọba ṣe, Báwo ni ọ̀rọ̀ àkóso ìṣèjọba ṣe fẹ́ rí báyìí?
Esi ibo yii fihan pe ko si eyikeyi ninu ẹgbẹ oṣelu yii to le da duro ṣe ijọba funrarẹ lai fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu miran.
Wo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ti fí orúkọ sílẹ̀ fún ẹ̀yáwò tí ìjọba gbé kalẹ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́
Nelfund ni inu awọn dun lati gbe ikede naa sita fun awọn akẹkọọ lati jẹ anfani.
Hijrah: Kí ni pàtàkì ọdún tuntun yìí fún àwọn mùsùlùmí
Iyatọ to wa laarin ọdun musulumi ati ọdun yooku ni pe wọn ko kii ṣe e papọ pẹlu awọn yooku ati pe orukọ wọn yatọ.
ECOWAS kéde Ààrẹ Tinubu gẹ́gẹ́ bí alága fún sáà kejì
Ọjọ kẹsan an oṣu keje ọdun 2023 ni wọn kọkọ kede Aarẹ Tinubu gẹgẹ bii Alaga ECOWAS.
Ọwọ́ NDLEA tẹ Baálẹ̀ tó ń gbé igbó ní ìpínlẹ̀ Osun
Agbẹnusọ ajọ, Femi Babafemi lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi lede sita fawọn akọroyin
Yóò lé ní ọgọ́rin míliọ̀nú ọmọ Nàìjíríà tí yóò máa kojú ebi ni ọdún 2030- MDD
Bakan ni MDD tun kesi orilẹede Naijiria lati wa ojutu si iṣoro oju ọjọ, iṣoro kokoro ati awọn nnkan mii to n dunkoko mọ eto ọgbin lorilẹede Naijiria.
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìlú ńlá kan wà lórí òkè Idanre?Duration, 10,00
A fi ẹsẹ kan de Oke Idanre, nibẹ ni a ti mọ pe ilu mii si n bẹ lori oke Idanrẹ.
Ọkọ la ikún Òjòlá láti gbé òkú aya rẹ̀ tó di àwátì láìpẹ́ jáde
Lasiko to n ba BBC sọrọ, alakoso ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa , Idul, sọ pe ọkọ Arabinrin naa lo ri ejola ọhun laaye, to si ge ori rẹ soju ọna.
Ta ni Sir Keir Starmer, olóòtú ìjọba tuntun ilẹ̀ Gẹẹsi?
Sir Keir Starmer, to jẹ oloṣelu ati agbẹjọro ni olootu ijọba tuntun fun ilẹ Gẹẹsi.
Keir Starmer di Olóòtú ìjọba tuntun ní UK, kéde pé iṣẹ́ ìyípadà bẹ̀rẹ̀ lọ́gán
Ọlọla Keir Starmer lo farahan fun igba akọkọ ni ile Olootu Ijọba to wa ni ojule kẹwa, Downing Street lẹyin ti Ọba Charles Kẹta sọ fun pe ko lọ se agbekalẹ ijọba tuntun.
Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko pa ajínigbé mẹ́sàn án, gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Benjamin Hundeyin fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Ẹti lo ti sọ bẹẹ.
Ayàwòrán tó dáná sun fọ́to Ààrẹ gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méji
Ayaworan ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) yii ko jiyan ni kootu, o loun huwa naa loootọ, ko si sọ awijare kankan lati gba ara rẹ silẹ nigba ti wọn ni ko rojọ.
Ọmọ ogun 25 gba ìdájọ́ ikú torí wọ́n jẹ́ ojo tó sá lójú ogun
Agbẹjọro awọn ologun naa ti meji ninu wọn jẹ ọgagun ti sọ pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun.
Ẹ fura o lórí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá! Ìpínlẹ́ 21 yóò kojú ẹ̀kún omi, àrùn Kọ́lẹ́rà sì lè pọ si - Ìjọba àpapọ̀
Minisita to n ri si ọrọ omi ati imọtoto ayika sọ pe agbara ojo to n pọ yii le mu ki aisan Kọlẹra pọ si i lorilẹ-ede yii.
Àwọn darandaran kọlù ikọ̀ Amotekun l'Ondo, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn
Ohun to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe awọn darandaran yi se ikọlu naa lasiko ti awọn ikọ Amotekun lọ se iṣẹ wọn nipa ofin ti ijọba gbe kalẹ
Ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ ní Nàíjíríà, JAMB rí 3000 ayédèrú akékọ̀ọ́ fásitì - Oloyede
Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, ọga to n ri si igbaniwọle ni JAMB, sọ pe awọn eeyan naa ko de yunifasiti ri, debi ti wọn yoo tilẹ kẹkọọ yege.
Ìdí rèé tí ọkùnrin tó tíì fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ jùlọ ní Nàíjíríà ṣe fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ìgba méjìlélọ́gọ́rin
Micheal Mzega, nigba to n ba BBC sọrọ, sọ ohun to fa a, to se n fi fi ẹjẹ silẹ fawọn eeyan nileewosan fun bii igba mejilelọgọrin (82).
Ìyàlẹ́nu ló ṣì n jẹ́ fún mi bí Nàíjíríà ṣì ṣe dúró pẹ̀lú adúrú owó tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ti jí gbé – Alága EFCC
Alaga EFCC lo sọrọ yii lasiko to n gba igbimọ iṣakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ pinpin owo ilu ati ina nina lorileede yii, RMAFC ti Mohammed Shehu jẹ alaga wọn lalejo laipẹ yii.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Móríwú
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìgbéyàwó fún àwọn ọmọ òrukàn 105 yóò wáyé ní Zamfara
Aṣofin Abdulmalik Zubaim Bungudu to se agbatẹru igbeyawo naa sọ fun BBC pe awọn gbe igbimọ kalẹ lati se ohun to tọ nipa awọn ti yoo jẹ anfani yii
Halal àbí Haram? Wọ́n ti ibùdó ìtọ́jú omi ọyàn pa lẹ́yìn ẹ̀hónú àwọn ẹlẹ́sìn Islam
Igbiyanju awọn eeyan kan ni Pakistan lati da ibudo ti wọn yoo maa ṣe omi ọyan obinrin lọjọ si lo ti foriṣanpọn bayii, lẹyin ti ijọ ẹlẹsin Islam kan lati Karachi lodi si i.
Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria fòǹtẹ̀ lu ìbálòpọ̀ akọsakọ nípasẹ̀ àdéhùn Samoa tó buwọ́lù?
Amọ ṣa, adehun ọhun mẹnuba igbeṣe lati dẹwọ idunkomọni latari ẹsin ti eeyan n sin, tabi ẹni to ba yan lati ni ibalopọ pẹlu.
Ẹni tó bá ti ṣíwọ́ ọmọbíbí, yóò máa gba owó lọ́wọ́ ìjọba ní ìlú yìí
Eyi waye latari bo ṣe jẹ ijọba ilu naa lo gbe igbesẹ ai ni i bimọ mọ fawọn eeyan ilu yii lati ọdun pipẹ.
Kí ló dé táwọn òbí ṣe ń ti ara wọn mọ́ ẹ̀wọ̀n nítorí ọmọ?
Àwọn òbí kan ní South Korea ń fi ara wọn sínú túbú láti mọ bó ṣe ń rí fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ń dá ara wọn yà sọ́tọ̀.
Ọmọbìnrin ààrẹ Cameroon fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí àṣepọ̀ abo-sí-abo
Ọmọbinrin aarẹ orilẹede Cameroon,Brenda Biya, ti fi aworan kan sori ayelujara, nibi to ti n fi ẹnu ko obinrin bii tiẹ, Layyons Valenca, lẹnu.
Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé lórí ẹ́jọ́ tó ń tako yíyọ Soun Ogbomoso lóyè
Agbẹjọrọ agba to ṣoju Ọba Ghandi nile ẹjọ naa, Mallam Yusuf Ali, SAN, ṣe alaye fun akọroyin BBC Yoruba pe igbaradi saaju idajọ ti yoo waye l'opin ọdun yii, ni awọn wa ṣe lonii.
Wo àwọn ìwà àìmọ̀kan tí ò ń hù lójúmọ́, tí o fi ń kópa nínú ìlòkulò òògùn láì mọ̀
Dokita onimọ iṣegun kan sọ pe ti o ba ti ri i pe aṣilo oogun ti n fa oriṣiiriṣii iṣoro fun ọ, tete lọ ri dokita.
Wo bí o ṣe lè fi ojú òpó Facebook rẹ gba owó
Awọn eeyan tẹnikan ko mọ tẹlẹ ni wọn ti tipasẹ awọn oju opo yii di gbajumọ ati oju to pawo.
Àwọn wo ni ìdádúró owó orí kàn àti àǹfààní tó wà nínú rẹ̀?
Alaga igbimọ aarẹ to n ri sọrọ bi ijọba ṣe n na owo ati atunto owo ori (Fiscal Policy and Tax Reforms), Taiwo Oyedele lo sọ eyi di mimọ lori ikanni ‘X’ rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.