Ìdí rèé tí ọkùnrin tó tíì fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ jùlọ ní Nàíjíríà ṣe fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ni ìgba méjìlélọ́gọ́rin

Aworan Micheal nileewosan
Àkọlé àwòrán, Micheal Mzega to fi ẹjẹ silẹ nigba mejilelọgọrin

Ẹjẹ ara eeyan jẹ ko ṣee ma ni fun ẹni to ba fẹẹ gbele aye pẹlu alaafia.

Bo tilẹ jẹ pe ara wa lo n pese ẹjẹ lati inu egungun bọọgọ, sibẹ, awọn eeyan mi-in maa n nilo afikun ẹjẹ to wa lara wọn ki wọn too le ni alaafia, paapaa awọn ti wọn ba ni aisan f’eni ku-fọla dide ti a mọ si sickle cell anaemia.

Isọri awọn eeyan mi-in ti wọn tun maa n nilo ẹjẹ ni pajawiri ni awọn ti aidape kan n da laamu, abi awọn ti wọn ba padanu ẹjẹ latari ijamba to ṣẹlẹ si wọn.

Nitori awọn idi yii ni ọkunrin kan, Micheal Mzega, sẹ n fi ẹjẹ silẹ kaakiri lorilẹ-ede Naijiria lai gbowo lọwọ awọn to nilo rẹ.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, Micheal ṣalaye pe igba mejilelọgọrin (82) ni oun ti fi ẹjẹ silẹ.

O ṣalaye ohun to fa a to fi n fẹjẹ silẹ fawọn eeyan nileewosan.

Bakan naa lo sọ iriri rẹ nipa fifi ẹjẹ silẹ, ati bo ṣe maa n ri lara rẹ nipa gbigba ọpọ ẹmi la lọwọ iku ojiji.

"Àìsàn f’òní kú-f’ọ̀la dìde ló pa ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin"

Micheal Mzega to jẹ ọkan lara awọn eeyan ti wọn ti fẹjẹ silẹ ju ni Naijiria, ṣalaye pe iku ẹgbọn oun to jẹ ọkunrin bii toun lo jẹ koun maa fi ẹjẹ silẹ fun awọn eeyan ti wọn nilo rẹ.

O ni aisan f’oni ku- f’ọla dide ti a mọ si sickle cell lo pa ẹgbọn naa.

Ọgbẹni Mzega tẹsiwaju pe ni gbogbo igba ti inira aisan naa ba de si ẹgbọn oun lawọn yoo maa wa eeyan to le fun un lẹjẹ, oṣooṣu si leyi bo ṣe wi.

O ni ifẹ ti awọn eeyan ni si ẹgbọn ati ẹbi awọn nigba naa ti wọn fi n fi ẹjẹ wọn silẹ maa n wu oun lori gan-an.

‘’Loṣooṣu la maa n pe eeyan meji si mẹta lati waa fi ẹjẹ silẹ fun ẹgbọn mi ko too di pe o pada ku.

’’Mo ṣi kere pupọ nigba yẹn ṣugbọn mo maa n sọ ọ ninu ọkan mi pe ti mo ba dagba, emi naa yoo maa fẹjẹ silẹ fawọn eeyan to nilo rẹ. Nigba ti anfaani naa si ṣi silẹ fun mi, mo bẹrẹ si i fẹjẹ silẹ niluu Abuja.’’

Ọkunrin yii sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko ni anfaani lati fẹjẹ silẹ fun ẹgbọn oun titi to fi kun ni 2008, inu oun dun pe oun pada ni anfaani lati fun awọn to nilo ẹjẹ bayii, oun si n gba ọpọ ẹmi la.

" Ọdun 2016 ni mo bẹrẹ si i fi ẹjẹ silẹ fun awọn eeyan, ẹgbọn mi ku ni 2006.

’’Mi o ni anfaani lati fẹjẹ silẹ fun ẹgbọn mi nitori Abuja lemi wa, nigba toun wa labule.

Ṣugbọn ko too ku lọjọ naa, awọn ara abule gbiyanju, o to igo ẹjẹ meje tawọn dokita fa si i lara lọjọ naa, ṣugbọn o pada ku.

‘’Ifẹ ti wọn fi han si i yii lo jọ mi loju to si jẹ ki n pinnu pe emi naa yoo maa fẹjẹ silẹ.

Ti mo ba ti fẹẹ fi ẹjẹ mi silẹ bayii ti mo si ranti ẹgbọn mi, o maa n wu mi lori lati tẹsiwaju."

Bẹẹ ni Ọgbẹni Micheal sọ fun BBC.

Nigba to n sọ iriri rẹ lọjọ to kọkọ fi ẹjẹ silẹ, o ni ayọ kun inu oun gidi.

Idunnu ko si jẹ koun tiẹ mọ pe wọn n gba ẹjẹ lara oun rara, nitori ohun to ti wu oun lati kekere loun dagba ṣe.

" Mo ti fẹjẹ silẹ fawọn eeyan ti mo mọ atawọn ti mi o tiẹ mọ ri rara, awọn mi yè, awọn mi-in si ku.

Ohun to ṣaa maa n jẹ idunnu fun mi ni pe mo wa lara awọn to n fẹjẹ silẹ kawọn ẹlomi-in le wa laaye."

Mi ò kojú àilera tó lágbára kankan rí látìgbà tí mo ti ń f’ẹ̀jẹ̀ sílẹ́

Aworan Micheal ati Dokita Ijeoma
Àkọlé àwòrán, Aworan Micheal ati Dokita Ijeoma

"Bi ajọ NBSC ṣe da mi mọ bii ọkan lara awọn to n fẹjẹ silẹ ju ni Naijiria dun mọ mi ninu gan-an lọjọ ti wọn ya sọtọ fun fifi ẹjẹ silẹ lagbaaye"

Ninu iriri rẹ naa ni Micheal ti sọ pe ara ko ni oun lara ri lati igba ti oun ti n fi ẹjẹ silẹ fawọn eeyan.

O ni ailera to le, ko koju oun ri lati 2016 toun ti n ba a bọ.

O fi kun un pe eyi ri bẹẹ nitori idanilẹkọọ ti ajọ ‘National Blood Service Commission’ (NBSC) to n ri si ọrọ ẹjẹ maa n fun awọn to ba fẹẹ fi ẹjẹ silẹ.

" Wọn kọ wa pe ka yee lo oogun oloro, ka yee mu siga, ka ma ṣe gbe igbesi aye buruku.

Lẹyin iba, ko si aisan kan to tun ṣe mi, wọn ko da mi duro sileewosan, ara mi le daadaa."

Nipa awọn ti wọn maa n sọ pe awọn ko le fẹjẹ silẹ ki ọsibitu waa maa ta a, ki wọn maa gbowo, Micheal sọ pe ko ri bẹẹ

O ni NBSC ki i ta ẹjẹ, owo teeyan yoo fi forukọsilẹ ni wọn yoo gba, ohun to si wa fun naa ko ju ki wọn fi mọ riri ẹjẹ tawọn eeyan fi silẹ lọ.

‘’Bi ajọ NBSC ṣe da mi mọ bii ọkan lara awọn to n fẹjẹ silẹ ju ni Naijiria dun mọ mi ninu gan-an lọjọ ti wọn ya sọtọ fun fifi ẹjẹ silẹ lagbaaye, eyi to waye niluu Abuja’’

Aworan oṣiṣẹ ilera to n kọwe lọsibitu

'A kì í ta ẹ̀jẹ̀ ni NBSC,ẹ̀jẹ̀ tó bá pọ̀jù là ń gbà’

Ọga to n ri si iṣẹ ti wọn n ṣe nileeṣẹ ijọba apapọ ti i ṣe National Blood Service Commission, (NBSC) l’Abuja, Dokita Ijeoma Leo-Nnadi, fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni Ọgbẹni Michael Mzega jẹ ọkan lara awọn eeyan ti wọn ti fẹjẹ silẹ daadaa lorilẹ-ede yii.

"Bi akọsilẹ wa ṣe wi, Micheal Mzega ti bẹrẹ si i fẹjẹ silẹ nibi lati ọdun 2006. Mo mọ ọn daadaa, o ti fẹjẹ silẹ nigba mejidinlọgọrin fun ajọ yii.

Nipa tita ẹjẹ awọn eeyan ni NBSC, Dokita Ijeoma sọ pe,

" A ki i ta ẹjẹ ni NBSC,owo kekere la maa n gba lori ẹ, a si maa n pe e ni owo anfaani lati gba ẹjẹ, ẹgbẹrun mẹwaa naira pere ni.

Awọn igbesẹ kan wa fun ẹjẹ tawọn eeyan n gba yii, a si maa kọkọ ṣe ayẹwo fun ẹni ta a fẹẹ gbẹjẹ lara rẹ naa.

‘’Owo la fi n ra awọn nnkan elo ta a maa fi gba ẹjẹ, owo la fi n ra apo ta a maa fi ẹjẹ naa si, owo la fi n ra nnkan ta a fi n ṣe ayẹwo ẹjẹ. A nilo ina lati fi ṣe ẹjẹ naa lọjọ sibi ti ko ti ni i bajẹ ati bẹẹ bẹẹ bẹẹ lọ’’

O ni owo kekere kọ ni awọn nnkan wọnyi bawọn ba fẹẹ ṣi iye rẹ, ṣugbọn ijọba n ṣe iranwọ, idi niyẹn tawọn ko ṣe ki n ta ẹjẹ naa.

Fun awọn ti wọn n sọ pe ẹni to ba fẹjẹ silẹ ko ni i lẹjẹ lara mọ, yoo ku, Dokita Ijeoma sọ pe irọ gbuu ni.

" Awọn kan maa n ro pe ẹjẹ ara awọn maa tan bawọn ba fi ẹjẹ silẹ, pe awọn maa ku. Awọn mi-in yoo sọ pe awọn ko mọ ibi ti wọn n gbe ẹjẹ awọn lọ, boya wọn maa lọọ fi ṣetutu ni. Ko ri bẹẹ.

‘’A maa n tóju ẹjẹ yii sibi ti ko ti ni i bajẹ, nitori a mọ pe nnkan ọ̀wọ̀ ni ẹjẹ, a ki i ṣe radarada pẹlu ẹjẹ awọn eeyan rara. Awọn ti ẹjẹ ara wọn ba pọju la n gba tiwọn.’’

Irú èèyàn wo ló lè fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ́?

Aworan ibi ti wọn ti n gba ẹjẹ

*Dokita Ijeoma ṣalaye pe ẹni to fẹẹ fi ẹjẹ silẹ gbọdọ ni ilera pipe.

*Ohun ti a mọ si haemoglobin to n pese ẹjẹ pupa gbọdọ to lara ẹni naa.

*O ko gbọdọ ni aisan kankan lara to fi mọ iba.

* Ti o ba n lo oogun iba lọwọ, a ko ni i gba ọ laye lati fi ẹjẹ silẹ titi di ẹyin ọsẹ meji si mẹta.

*Ẹni to ni aisan jẹjẹrẹ, ẹjẹ riru ti ko gbọ itọju, ẹni to ṣẹṣẹ ya tatoo tabi to lu iho sara ti ko ti ju oṣu mẹfa lọ ko le fi ẹjẹ silẹ, nitori o ṣee ṣe ki kokoro arun ti wọ ara rẹ latari iho to lu sara naa.

Bi iwọn rẹ ko ba to aasdọta (50kg), o ko le fi ẹjẹ silẹ.

Bẹẹ ni olori ẹka iṣẹ nileeṣẹ ijọba NBSC naa ṣalaye fun BBC.

*O fi kun un pe ẹẹmẹta pere ni aaye wa fun obinrin lati fẹjẹ silẹ laarin ọdun kan, eyi ti i ṣe ẹẹkan laarin oṣu mẹrin, eyi ri bẹẹ nitori nnkan oṣu ti wọn maa n ṣe.

O ni ọkunrin le fẹjẹ silẹ nigba mẹrin laaarin ọdun kan.

Gẹgẹ bi Dokita Ijeoma ṣe wi, awọn ki i gba ju apo ẹjẹ kan lara eeyan lẹẹkan naa, bo ti wu ki ẹjẹ ara ẹni naa pọ to.

" A ki i gba ki ẹni to ti fẹjẹ silẹ lẹẹmẹrin lọdun tun fẹjẹ silẹ mọ, a n ṣe eyi ki egungun bọọgọ ara eeyan le pese ẹjẹ miran, kawọn ẹjẹ naa si dagba to bo ṣe yẹ ko ri, ko ma lọọ jẹ pe ẹjẹ ti ko kun to la maa gba fun ẹlomi-in to nilo ẹjẹ.’’

Ìpele ẹ̀jẹ̀ gbígbà

Ki i pẹ rara lati fi ẹjẹ silẹ, Dokita Ijeoma sọ pe ko ju iṣẹju marun-un lọ. Ṣugbọn keeyan too fa ẹjé naa, eyi ni awọn igbesẹ ati ipele to rọ mọ ọn:

*Wíwá ẹni tó fẹ́ẹ́ fẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: Eyi ni lati wa ẹni to fẹẹ fi ẹjẹ silẹ, boya wọn ba eeyan sọrọ nipasẹ alaye ipolongo ni abi ki ẹni naa fi ẹsẹ ara rẹ rin lọ sileewosan lati fi ẹjẹ silẹ.

*Riri oludanilẹkọọ ti yoo la ọ lọyẹ ti yoo si beere ibeere lọwọ rẹ.

*Iwọ yoo kọwọ bọwe lati sọ nipa ara rẹ. Ninu eyi ni wọn yoo ti mọ boya o ti ni awọn ailera nla ri.

*O gbọdọ kọwọ bọwe pe o gba lati fi ẹjẹ odiwọn kan pato silẹ lati gba ẹmi awọn eeyan la.

*Wọn yoo yẹ ifunpa rẹ wo lati mọ bi ẹjẹ rẹ ṣe n lọ si lara, wọn yoo wo odiwọn ẹjẹ ti o ni, odiwọn haemoglobin, iwọn ara rẹ (body weight), bi eemi rẹ ṣe n lọ si ati bẹẹ bẹẹ lọ.

*Bi o ba kunju oṣunwọn, wọn yoo mu ọ lọọ ba ẹni ti yoo gba ẹjẹ lara rẹ.

*Ẹni naa yoo fi ọ lara balẹ, iwọ yoo maa wo ẹrọ amohunmaworan lati gbe ọkan rẹ kuro nibi ẹjẹ fifa naa bi wọn ṣe n fa a.

*Bi o ba ṣetan, wọn yoo fun ọ ni nnkan ipanu.