Kí ni àwọn ànfàní tí George yóò mú fún Nàìjíríà nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje àgbáyé?

Aworan Olukoni Nigeria, Finidi George

Finidi George yoo koju idanwo pataki rẹ akọkọ lati igba ti wọn ti yan an gẹ́gẹ́ bi olukọni agba fun ikọ agbabọọlu lorilẹede Naijiria.

Eyi yoo waye nigba ti ikọ Super Eagles ba n koju South Africa ati Benin ninu idije komẹsẹoyọ ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026 ni ọsẹ to n bọ.

George ti lewaju ikọ Super Eagales ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ meji gẹgẹ bii olukọni fidiẹ ni oṣu Kẹta, o ṣẹgun lori Ghana, to si ri iya he nigba to koju Mali.

Sibẹsibẹ, Ajọ Bọọlu afẹsẹgba Naijiria (NFF) ti ṣapejuwe awọn ifẹsẹwọnsẹ to n bọ, ni ọjọ Ẹti ati ọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 gẹgẹ bii “ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gbọdọ-bori” lẹyin ti ikọ Super Eagles ni maaki meji ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba ni abala C.

Agbabọọlu lọwọ iwaju fun Napoli, Victor Osimhen ni ko ni anfaani lati kopa nitori o farapa ṣugbọn George si le gbẹkẹle agbawọwaju fun Atalanta, to gba idije Europa League laipẹ yii, Ademola Lookman ati Victor Boniface, ẹni to jẹ agbaboolu to mi awọn ju fun ikọ agbabọọlu Bayer Leverkusen ti idije meji lorilẹede Germany ni saa yii.

George gbadun iṣẹ gbigba ere bọọlu lasiko to wa ni ewe.

Lati igba to ti fẹyìntì, o ti ṣamọna bi Enyimba se gba liigi ilẹ Naijiria.

Bakan naa nigba to lo ogun oṣu gẹgẹ igbakeji ọlukọni akọnimọgba Naijiria tẹlẹ, Jose Peseiro, ẹniti o ṣe amọna bi ikọ Super Eagles kopa nini ipele aṣekagba ni idije ife ẹyẹ AFCON ti ọdun 2023 to waye Ivory Coast.

Ṣugbọn kini awọn alatilẹyin Super Eagles le reti lati ọdọ George níbi ifagagbada yii?

Okunrin fun asiko nla

Aworan  Nwankwo Kanu ati Finidi George

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn bi niluu Port Harcourt ni guusu orilẹede Naijiria.

George jẹ ọkan ninu awọn agbabọọlu to lamilaaka ni orilẹ-ede naa.

O jẹ ọkan lara ikọ Super Eagles to lokiki lọdun 1994 eyiti o gba idije ifẹ ẹyẹ AFCON, to si kopa fun igba igba akọkọ ni Ife Agbaye to waye ni Amẹrika lọdun naa, to si de ipele round of 16.

Ẹni ọdun 53 naa gba ifẹsẹwọnsẹ akoko ni ọdun 1991, to si gba apapọ ifẹsẹwọnsẹ 62, pẹlu goolu mẹfa fun Super Eagles.

Lẹyin to gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu mẹta ni Naijiria, George gbe lọ si Ajax ni 1993, to si gba idije le Eredivisie mẹta ni itẹlera pẹlu idije Uefa Champions League labẹ Louis van Gaal.

“O jẹ agbabọọlu to mu ra siṣẹ to si jẹ alakitiyan,” akẹgbẹ rẹ ninu ikọ Super Eagles tẹlẹ Mutiu Adepoju sọ fun BBC Sport Africa.

"O mọ bi o ṣe le ge awọn alatako rẹ, to si tun le gbe wọn saare.”

Ogbontarigi yii lo ma n taayọ fun ni akoko ifẹsẹwọnsẹ nla, to si mi awọn lati gbe orilẹede Naijiria lọ si idije ife ẹyẹ agbaye.

George pese iranwo fun Rashidi Yekini lati gba ami ayo akọkọ orilẹ-ede wọle ninu idije pẹlu Bulgaria, ti oun naa si mi awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Greece ni ami ayo meji si odo eleyii to mu ki Super Eagles pari gẹgẹ eni to bori ninu saaju Argentina ati Bulgaria wa.

George fi Ajax silẹ ni ọdun 1996 o si lọ si Spain, pẹlu Real Betis ati Real Mallorca, ati ni England pẹlu Ipswich Town.

Agbabọọlu Ipswich tẹlẹ ri, Jim Magilton ranti bi inu ẹgbẹ naa se dun ní Portman Road nígba ti wọn ra agbabọọlu agbaye to jẹ ọmọ Naijria lọdun 2001.

"Finidi gbọdọ wa ni awọn agbabọọlu mẹwaa to dara ju ni Afirika ti o ti gba ere naa," Magilton sọ fun BBC Sport Africa.

“Awọn ara ololufẹ Ipswich ko gbagbọ pe a ti fowo ra agbabọọlu nla.

"Finidi dakẹ ninu yara iyipada ṣugbọn eyi ko tumọ si pe ko kii ṣe olori, o jẹ eeyan to ma fi iṣẹ sọrọ ju ki ko ma sọrọ lasan.

"O ga, ṣugbọn o jẹ ere idaraya pupọ ati pe o ni ọna iyanu yii taa fi ni anfani lati ṣe kanmọkanmọ."

George kopa fun Naijiria ni awọn ife ẹyẹ AFCON mẹrin, tun pari si ipo keji ni ọdun 2000 ati ipo kẹta lọdun 1992 ati 2002.

“O jẹ agbabọọlu alaṣeyọri ti awọn agbabọọlu yooku bọwọ fun,” Sam Sodje agbabọọlu Naijiria tẹlẹ sọ fun BBC Sport Africa.

“Finidi ni aye lati se daada pẹlu awọn agbabọọlu to wa ni arọwọ to rẹ s ṣugbọn yoo nilo atilẹyin lati ọdọ NFF ati awọn agbabọọlu lati ṣaṣeyọri.

"O mọ ohun ti awọn ololufẹ n reti lati ọdọ rẹ ati pe o ni agbara lati fi eyi ranṣẹ."

Awọn to sisẹ pọ pẹlu George ni Daniel Amokachi, agbabọọlu Naijiria to jẹ ti ikọ ẹgbẹ Super Eagles ti 1994.

Bawo ni Naijiria yoo se duro labẹ George?

Aworan iko Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Jijẹ olukọni fun George ni ko bẹrẹ bi o ṣe bẹrẹ ere bọọlu ati igba to n gba bọọlu.

O ni iriri, o ti jẹ olukọni fun ikọ awọn ọdọ ni Mallorca ati ẹgbẹ agbabọọlu PEC Zwolle, ati pe o tun ṣiṣẹ bi oludari bọọlu ni Betis.

NFF kọ lati fun ni iṣẹ ni ẹẹmeji ṣugbọn George ti ni aṣeyọri diẹ tẹlẹ loriẹedeNaijiria.

Lẹyin ti o gba iṣakoso ikọ Enyimba ni Oṣu Kẹsan ọdun 2021, George gba liigi akọkọ rẹ ni saa ikeji rẹ - laibikita pe o pa iṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ pẹlu iṣẹ gẹgẹ bi oluranlọwọ si Peseiro.

“O dabi baba fun wa,” Olorunleke Ojo ti Enyimba, ọkan ninu awọn amule mẹta ti wọn pe fun idije ife ẹyẹ agbaye lọwọlọwọ, sọ fun BBC Sport Africa.

"O fun wa ni anfani lati sọ ẹdun ọkan wa. O ma bawa ṣe ere ati awada nigba to yẹ ṣugbọn nigba to ba de ibi iṣẹ, ko ṣe awada. Ohunkohun to sọ, ni a ma ṣe.

"O ṣe iwuri, to si igbagbọ ninu siṣẹ takuntakun, Mo gbagbọ pe oun yoo ṣe aṣeyọri ninu ikọ Super Eagles."

Agbabọọlu Barcelona tẹlẹri, Emmanuel Amuneke ni gbogbo eeyan gbagbọ pe yoo gba iṣẹ olukọni lati gbe iṣẹ Naijiria, paapaa pẹlu aṣeyọri rẹ ni idije agbaye labẹ-17 ni ọdun 2015 pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu to pese awọn agbabọọlu bii Osimhen ati Samuel Chukwueze.

Ṣugbọn George, ti amọye kan ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi ọkunrin to “mọ bọọlu Naijiria” ti ajọ NFF si le gbagbọ.

"Ti o ba ro awọn olukọni to ti kọ ati awọn agbabọọlu to ba gba bọọlu paapọ, o ni ọpọlọpọ iriri ati oye," Magilton,olukọni Northern Ireland's Cliftonville, sọ.

"Ti o ba le gbe oye ati imọ rẹ fun awọn agbabọọlu rẹ, ko jẹ iyalẹnu fun mi pe o ti bẹrẹ si ni sisẹ olukọni ẹgbẹ agbabọọlu nla bi ti ikọ agbabọọlu orilẹede Naijiria.”