Orin la lọ kọ tí ọ̀kan nínú wa fi kú nínú ìjàmbá mọ́tò – Ayan Jesu

Àkọlé fídíò, Onírúurú ìpèníjà ló wà nínú iṣẹ́ wa, a ti ní ìjàmbá ọkọ̀ rí tí ọ̀kan nínú wa sì kú
Orin la lọ kọ tí ọ̀kan nínú wa fi kú nínú ìjàmbá mọ́tò – Ayan Jesu

Ẹgbẹ olorin ẹmi, Ayan Jesu, ti sọ pe oniruru ipenija lawọn maa n ri nidi iṣẹ naa ti wọn yan laayo, koda, wọ ti ni ijamba ọkọ ri lẹnu iṣẹ, ti ọkan ninu wọn si jade laye.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, wọn da ẹgbẹ naa silẹ lati ṣe ipolongo iyinrere Jesu Kristi.

Ọkan ninu wọn, Babatunde Ibigbami sọ pe lọpọ igba ni awọn eeyan kii fẹ gbọ iwaasu ni awọn ṣe n fi orin ṣe iwaasu fun araye.

Inu eto isin ‘Holy Ghost Service’ ti ijọ RCCG to waye lọdun 2003 ni ẹgbẹ olorin ẹmi naa kọkọ ti bẹrẹ si n laluyọ.

Iriri ẹgbẹ Ayan Jesu

Nigba to n sọ ohun ti oju wọn ti ri lẹnu iṣẹ naa, Ibigbami sọ pe “ṣe ọjọ to jẹ pe ki eeyan ti mọto lati Gbọngan de ‘Toll Gate’ Ibadan ni, tabi ọjọ ti eeyan a maa wa mọto lọ loju ọna morosẹ ti awọn ole yoo fọ igi mọ gilaasi ẹyin mọto ti wọn yoo si gba gbogbo foonu.

“Ṣe ọjọ to jẹ pe lọna Abuja ti awọn ole yoo da mọto duro ti a maa sare lọ ninu igbo ni.

“Tabi ọjọ ti a ni ijamba ọkọ ti ọkan ninu wa si wa lọdọ Ọlọrun bayii... Ohun ti a ti la kọja, o jẹ nnkan to lagbara, nitori naa ẹgbẹ yii ko gbọdọ tu.”

Nipa imisi ti wọn fi n kọ orin, ẹgbẹ Ayan Jesu sọ pe ọdọ Ọlọrun lo ti n wa.

Ọmọ ẹgbẹ naa mii to ba BBC sọrọ, Olugbenga Ige sọ pe ọrọ owo kii da ija silẹ laarin awọn.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ BBC Yoruba pẹlu ẹgbẹ Ayan jesu.