Àdó olóró Israel pa èèyàn mẹ́rìndínlógun nílé ẹ̀kọ́ Gaza

Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan, eeyan mẹrindinlogun lo ti jade laye latari ado oloro ti Israel ju si ile ẹkọ kan ti ajọ UN n ṣakoso rẹ lagbegbe Gaza Strip.

Ile ẹkọ naa lo wa ninu ile kan ti awọn aṣatipo Nuseirat wa ṣaaju ikọlu ọhun.

Ṣaaju ni Israel ti kọkọ sọ pe oun ju ado oloro si awọn agbesumọmi Hamas to farapamọ sagbegbe ile ẹkọ Al-Jaouni.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe yara ti ado oloro ọhun balẹ si lo jẹ eyii ti awọn ọlọpaa Hamas n lo.

Obinrin kan to n gbẹnusọ fun ẹka UN to n ri si ọrọ awọn aṣatipo ti sọ pe o yẹ ki iwadii waye lori ikọlu naa.

Ikọlun yii lo n waye lasiko ti awọn eeyan n reti ki adehun alaafia laarin igun mejeji to n kọju ija sira wọn wa si imuṣẹ.

Israel ti sọ pe oun yoo ran awọn aṣoju si Gaza lọsẹ to n bọ lati jiroro lori itusilẹ awọn to wa ni ahamọ Hamas.

Ọkan lara awọn adari Hamas sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ẹgbẹ naa ti ṣẹtan lati bẹrẹ ijioro naa pẹlu Israel.

Aworan lati ibi ti ikọlu naa ti waye ṣafihan bi awọn obinrin atawọn ọmọde ṣe pohunrere ẹkun ti eefin si gba gbogbo ayika ile ẹkọ ọhun.

Ẹwẹ, a gbọ pe nnkan bii ẹgbẹrun meje eeyan lo n gbe ninu ile ẹkọ ti ado oloro naa balẹ si.

Ko din ni ọgọrun akọroyin ti ẹmi wọn ti sọnu sinu ikọlu to n waye laarin Israel ati Hamas ni Gaza lati oṣu Kẹwaa ọdun to kọja ti inja wọn ti bẹrẹ.