Ta a ni Nick Imudia, ọ̀gá iléeṣẹ́ Konga tẹ́lẹ̀ tó jáde láyé?

Ooogbe Nick Imudia

Oríṣun àwòrán, Nick Imudia @google

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi ẹ mulẹ, pe ọkunrin oniṣowo nla nni, Nick Imudia to jẹ ọga patapata nileeṣẹ Konga atawọn ileeṣẹ nla nla mi-in ti jade laye.

Benjamin Hundeyin, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, fidi iku Nick Imudia mulẹ fun BBC l’Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2024 yii.

Ohun pato to pa oniṣowo nla naa ko ti i han saye, nitori awọn ẹbi rẹ paapaa ko ti i kede iku naa, bẹẹ ni awọn ọlọpaa ko sọ kulẹkulẹ iku ọhun.

Ṣugbọn awọn ẹka iroyin abẹnu kan n gbe e kiri pe ile Nick to wa ni Lekki, l’Ekoo lo ku si, ninu iṣẹlẹ kan to waye ninu ile naa.

Ta a ni Nick Imudia?

Loju opo ayelujara LinkedIn Nick Imudia nigba aye rẹ, o ṣapejuwe ara rẹ bii akọṣẹmọṣẹ oniṣowo to fẹran idagbasoke okoowo, to si maa n reti esi ire.

Ẹkọ nipa epo rọbi ati afẹfẹ idana lo gboye le lori, o si tun kẹkọọ yege nipa amojuto okoowo ṣiṣe.

Oloogbe Nick Imudia ṣiṣẹ nileeṣẹ elẹrọ ibaraẹnisọrọ Nokia, ko din ni ọdun mẹtadinlogun to fi ba wọn ṣiṣẹ.

O di ọga pata fun gbogbo Iwọ Oorun ati Aarin gbungbun ilẹ Adulawọ ko too kuro ni Nokia.

Imudia tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọga ni TCL/Alcatel, ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ to fidi kalẹ si Hong Kong.

Ki Oloogbe Imudia too pajude, oun ni ọga patapata ni ileeṣẹ d light, ileeṣẹ to n ri si ọrọ agbara.

Nick ati ikeji rẹ, Anthony Imudia, gbe ajọ kan kalẹ ti wọn pe ni Imudia Foundation, eyi to waye ni iranti baba wọn to jade laye ni 2011.

Ajọ ọhun wa fun iranlọwọ alaini niluu wọn ti i ṣe ipinlẹ Delta, paapaa julọ, agbegbe wọn ti wọn n pe ni Ika, nijọba ibilẹ Guusu Delta.

Wọn n ran awọn eeyan lọwọ lẹka ẹkọ ati ilera wọn.

Nipa igbeyawo, iroyin sọ pe Oloogbe Nick ni ọmọbinrin kan ninu igbeyawo rẹ akọkọ, ṣugbọn igbeyawo naa pada foriṣanpọn.

Bo tilẹ wa jẹ pe ko ti i sẹni to fidi ohun to pa Nick Imudia mulẹ, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe ibanujẹ ọkan, idaamu olowo ti wọn ki i le sọ fun eeyan lo pa ọkunrin naa.