Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọpọlọ wa lẹ́yìn ikú?

Aworan dokita to n wo ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Iku lopin ẹda ati ohun gbogbo to ba ti ni ẹmi ninu. Igbagbọ ọpọ eeyan si ni pe bi iku ba ti de, gbogbo ẹya ara yoo daṣẹ silẹ.

Ṣugbọn oyinbo oniṣẹ iwadii kan to jẹ dokita ọpọlọ, Jimo Borgin, ṣalaye fun BBC pe o ṣee ṣe ki ọpọlọ eeyan ma ku tan lẹyin iku ẹni naa.

Dokita Borgin sọ pe iwadii toun ṣe lori awọn eku meji lẹyin iku wọn, fi han pe ọpọlọ ọkan ninu wọn ko ku.

O ni niṣe lo da bii pe ọkan ninu awọn eku ọhun ṣi n da sọrọ, nitori ọpọlọ rẹ ṣi n gbe eroja Serotonin to ni i ṣe pẹlu keeyan maa da sọrọ jade.

‘’Ohun ti mo ri yii jọ mi loju, mo waa bẹrẹ si i wadii si i, o si ye mi pe diẹ bayii ni ohun ti a mọ nipa iku.’’

Bẹẹ ni Dokita Borjigin lati Yunifasiti Michigan, wi.

Ìtumọ̀ iku

Aworan ina alaranbara

Oríṣun àwòrán, Getty image

Dokita Borjigin ṣalaye pe bi ọkan eeyan ba daṣẹ silẹ (heart attack), wọn yoo kede ẹni naa pe o ti ku.

O ni ṣugbọn wọn ko ni i kede pe ọpọlọ rẹ ku.

Borjigin sọ pe sayẹnsi woye pe o le dabii pe ọpọlọ eeyan ko ṣiṣẹ mọ lẹyin iku, nitori oku naa ko kuku le sọrọ, ko le dide bẹẹ ni ko le jokoo mọ.

Ati pe ọpọlọ nilo afẹfẹ eemi, iyẹn Oxygen, to pọ ko too le ṣiṣẹ.

Bi ọkan ko ba si ti tu ẹjẹ kari ara mọ, ẹjẹ ko ni i de ọdọ ọpọlọ naa.

Ṣugbọn ṣe a le tori eyi gba pe ọpọlọ ti ku ṣaa ni ibeere ti Dokita naa sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.

Iwadii kan ti wọn ṣe ni 2013, fi han pe ilọpọ ọgọta ni eroja Serotonin ati Dopamine to n mu ara ya gaga fi lekun si i lara awọn eku lẹyin iku wọn bi Dokita Borjigin ṣe wi.

O ni o si ṣoro lati ri iru onka bẹẹ nigba ti awọn ẹranko ọhun ṣi wa laaye.

Ida ọgọrun-un (100% ) ẹranko lo fi jiji pepe ọpọlọ han lẹyin iku bo ṣe ṣalaye.

Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ló rí fún ọmọ èèyan pẹ̀lú?

Aworan oku to to lori ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ni 2023, wọn gbe iṣẹ iwadii kan jade lori eeyan mẹrin ti wọn ti wọ kómà (Coma), ti wọn ko mọ ibi ti wọn wa mọ, to si jẹ pe eemi atọwọda (Ventilator) ni wọn fi n mi.

Awọn ẹbi wọn panupọ pe kawọn dokita yọ afẹfẹ atọwọda naa kuro, ki wọn jẹ ki wọn lọọ sinmi lajule ọrun.

Awọn oluwadii ba bẹrẹ iṣẹ lori ọpọlọ awọn eeyan mẹrin naa, wọn si ri i pe ọpọlọ awọn meji ninu wọn ṣi n ṣiṣẹ daadaa.

Ki ni wọn lo fa eyi, wọn ni ọlọpọlọ pipe eeyan to ni oye lori ni awọn meji naa nigba aye wọn.

Wọn tun tọka si kinni kan ti wọn pe ni Gamma. Wọn ni kinni naa lo n ṣiṣẹ fun aditu ọrọ ati keeyan maa ranti nnkan daadaa.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó súnmọ́ kí ẹ̀mí bọ́

Aworan Dokita Jimo Borjigin

Oríṣun àwòrán, University of Michigan

Àkọlé àwòrán, Aworan Dokita Jimo Borjigin

Awọn eeyan ti wọn ti ni iriri ohun to le gba ẹmi eeyan ri, sọ pe lasiko naa, awọn nnkan pataki to ti kọja sẹyin bẹrẹ si i wa si iranti awọn.

Ọpọ to sọ iriri wọn nipa eyi sọ pe awọn ri imọlẹ nla kan, bẹẹ lawọn mi-in sọ pe awọn ri i ti ara awọn n dide ninu agọ ara to sun silẹ.

" O kere tan, eeyan ogun si mẹẹẹdọgbọn ti wọn ti ri firfiri iku ri ni wọn sọ pe awọn ri imọlẹ funfun abi nnkan kan.

Iyẹn fi ye wa pe ohun to n ṣiṣẹ ninu ọpọlọ wọn ṣi wa sibẹ niyẹn.’’

Dokita Borjigin lo sọ bẹẹ.

O loun naa mọ pe iṣẹ iwadii oun nipa ohun to n ṣẹlẹ si ọpọlọ eeyan lẹyin iku kere, ṣugbọn awọn oluwadii miran naa nilati ṣiṣe nipa imọ yii.

Dokita Borjigin sọ pe oun gbagbọ saa, pe ọpọlọ n ṣiṣẹ lọ lasiko ti ọkan eeyan ba daṣẹ silẹ.

Ki lo wa maa n ṣẹlẹ si ọpọlọ nigba ti eemi ko ba debẹ mọ? Borjigin ni ko ti i si agbekalẹ kankan lori eyi.

O ni ṣugbọn fun eku ati eeyan, oun gbagbọ pe ọpọlọ wọn ki i daṣẹ silẹ kia lẹyin iku.

Omi ń bẹ lámu, ìwàdìì ń tẹ̀ síwáju

Dr Borjigin tẹsiwaju pe perete ni abọ iwadii oun ati awọn ẹlẹgbẹ oun lori ipo ti ọpọlọ wa lẹyin iku.

O ni gẹgẹ bii oluwadii tawọn jẹ, omi n bẹ lamu, iṣẹ ṣi pọ gidi fawọn eeyan awọn lati ṣe.