Wo bí wíwá omi mímu káàkiri láti pọn ṣe ń ṣàkóbá fáwọn obìnrin ní India

Sunita Bhurbade

Oríṣun àwòrán, BBC/MANGESH SONAWANE

Àkọlé àwòrán, Sunita Bhurbade maa n lo wakati mararun un lojoojumọ lati pọn omi.
  • Author, Anagha Pathak
  • Role, BBC Marathi

Omi pipọn jẹ iṣẹ to le fun ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn obinrin lorilẹede India.

Lojoojumọ ni wọn maa n rin ọpọ mẹẹli lati wa omi fun lilo nile wọn.

"Ojoojumọ ni a maa n ṣe wahala yii.

Mo maa n ṣubu lulẹ ni lẹyin ti mo ba ṣe wahala wa omi tan," Sunita Bhurbade, obinrin kan to wa lati abule Tringalwadi ti o to mẹẹli 112 si ilu Mumbai ni India lo sọ bẹẹ.

Bhurbade maa n lo wakati mẹrin si marun un lati pọn omi sinu awọn ikoko rẹ.

"Ni ọdọọdun lawa obinrin maa daamu wa omi kiri fun oṣu mẹrin si marun un," Bhurbade lo sọ bẹẹ.

Niṣe ni ẹyin ati ọrun maa n ro Bhurbade pẹlu wahala to n ṣe lori omi lojoojumọ.

Wahala omi yii gan an ni ko le jẹ k'awọn obinrin yii maa ṣiṣẹ ti wọn maa fun wọn lowo nibẹ.

Bhurbade ni "ko si ẹni to maa gba mi ṣiṣẹ tori wọn o ni fun mi laye lati maa de ibi iṣẹ lọsan an.

Ti mo ba n wa omi kiri, mi o ni le ṣiṣẹ, ti mo ba si n ṣiṣẹ, o tumọ si pe ẹbi mi ko ni ri omi mu."

Aworan obìnrin pẹlu omi lori rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wiwa omi kiri ko jẹ k'awọn obinrin India raye ṣe iṣẹ mii

Ajọ WHO to n ri si eto ilera lagbaaye ati UNICEF to n ri si ọrọ awọn ọmọde sọ lọdun 2023 pe eeyan to din diẹ ni biliọnu meji (1.8b) lo n wa omi kiri tori ko si omi nile ti wọn n gbe.

Ajọ naa sọ pe meje ninu idile mẹwaa, awọn obinrin lo maa n wa omi kiri.

Ọjọgbọn Ashwini Deshpande to jẹ onimọ nipa ọrọaje to tun jẹ olukọ ni ile ẹkọ giga fasiti Ashoka niluu Delhi sọ pe "awọn obinrin ko le maa ṣiṣẹ gbowo tori iṣẹ ile.

Bi wọn ba si sọ pe awọn fẹ ṣiṣẹ, ko sí iṣẹ to le kari awọn obinrin to n gbe ni igberiko.

Banki SBI to jẹ ile ifowopamọ to tobi julọ ni India sọ iye owo iṣẹ t'awọn obinrin ni India n ṣe yoo to $276.8m.

Awọn onimọ sọ pe t'awọn obinrin ba no asiko ti wọn fi n ṣiṣẹ ile ṣe iṣẹ ti wọn maa gba owo níbẹ, ọpọ ninu wọn ni yoo lowo ti ara wọn lọwọ, eyi yoo si tun jẹ ki ọrọaje gbe pẹẹli si.

Ijọba orilẹede India ti sọ pe oun n gbiyanju lati ri pe omi to mọ wa fawọn eeyan kaakiri orilẹede naa.

Ijọba ni oun ti pese omi ẹrọ fun ida 74% awọn olugbe igberiko ni India ni oṣu Kinni ọdun 2024.

Ọpọ awọn to n wa omi kaakiri tẹlẹ ni omi ti wa nile won bayii.

Amọ, ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan ni India ni ko si ri omi ẹrọ mu.

Aworan awọn eeyan to n mu omi ni Kolkata

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ni ko ro omi to mọ gaara mu ni India

Indrayani Javarkar to jẹ baalẹ abule Aaki lẹkun Amaravati ni India maa n lo ọpọ akoko rẹ lojoojumọ lati wa omi.

O maa n le gan an lati ri omi ninu ẹrun.

Iṣẹ meji ni Indrayani maa n ṣe - akọkọ ni lati wa omi fun idile rẹ.

Ekeji ni lati ri pe awọn ọkọ to n gbe omi wa ja omi fawọn eeyan abule rẹ.

Bhurbade ni tiẹ sọ pe ati ri omi ẹrọ mu ṣi dabi ala foun.

Lati igba ewe l'awọn obinrin ti maa n bẹrẹ wahala omi pipọn ni India.

Lati jgba ewe yi si ni yoo ti pọn omi titi ti yoo fi ku.

Bhurbade ko le ranti ọdun kan ti ko ti i rin ọpọ mẹẹli lati wa omi kiri fun ẹbi rẹ.

Ileeṣẹ iroyin BBC Africa Eye beere lọwọ rẹ pe kinni ko ba maa ṣe ti ko maa wa omi kiri lojoojumọ.

Bhurbade ni orin loun o ba maa kọ.

Ṣugbọn orin nipa omi lo n kọ bayii.

"Radu nako bala mi panyala jate," Bhurbade kọ orin fún BBC eyi to tumọ si pe, "ma sọkun ọmọ mi, mo n lọ pọn omi."