Ìdí rèé tí ìdìbò ilẹ̀ UK ṣe yẹ kó jẹ́ ilẹ̀ Áfíríkà lógún

Àkọlé fídíò, UK Election: Wo ìdí tí àwọn èèyàn adúláwọ̀ ṣe mú ìdìbò ilẹ̀ UK tó ń bọ̀ ní ọ̀kúnkúndùn
Ìdí rèé tí ìdìbò ilẹ̀ UK ṣe yẹ kó jẹ́ ilẹ̀ Áfíríkà lógún

Ọjọbọ, ọjọ Kẹrin osu Keje ọdun 2024 ni ilẹ United Kingdom (UK) yoo se eto idibo rẹ.

Lasiko eto idibo naa ni wọn yoo dibo yan awọn ọmọ ile asofin latinu ẹgbẹ oselu to wa nilẹ UK.

Diẹ lara awọn ẹgbẹ oselu ti yoo kopa ninu ibo ti yoo waye naa ni Republican, Conservative ati ẹgbẹ oselu Labour.

Sugbọn ibo ti ọla yii ni nnkan se pẹlu orilẹede ni Afrika nitori irufẹ ẹgbẹ oselu to ba gba akoso ilẹ UK yoo sọ bi ibasepọ rẹ pẹlu ilẹ Afrika yoo se ri.

Bakan naa, irufẹ ijọba ẹgbẹ oselu naa si lo seese ko se ofin ti yoo ni ipa nla lori awọn eeyan ati orilẹede to wa nilẹ adulawọ.

Eyi lo mu ki BBC se akojọpọ iroyin yii lati sọ diẹ lara iddi ti eto idibo nilẹ UK se yẹ ko mumu laya awọn eeyan ati orilẹede nilẹ Adulawọ.

Ìdí rèé tí ìdìbò ilẹ̀ UK ṣe yẹ kó jẹ́ ilẹ̀ Áfíríkà lógún

Awọn igbesẹ to se koko nipa ilẹ Africa to seese ki ijọba tuntun ni UK se ipinnu le lori

RWANDA

Awọn atipo lati orilẹede Rwanda to wa nilẹ UK le ni ẹgbẹta loju Kẹfa ọdun 2024 nikan, ori ọkọ oju omi kekere to n kọja lori okun si ni wọn gba wọle.

O si le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun awọn ọmọ ilẹ Rwanda to wọle silẹ UK lọna aitọ.

O si seese ki ijọba tuntun toi ba gba akoso nilẹ Uk lẹyin eto idibo naa le wọn pada si orilẹede Rwanda.

Wọle-wọde eeeayn silẹ UK (Immigration)

Ojoojumọ ni awọn ọmọ Afrika n ya lọ si ilẹ UK lati lọ fori pamọ sibẹ.

Lọdun 2023 nikan, o le ni miliọnu kan ati igba osisẹ lawọn orilẹede miran to wọ ilẹ UK wa.

Orilẹede Naijiria si lo ni eeyan to pọ julọ lẹyin orilẹede India to wọle silẹ UK.

Ọmọ ilẹ Naijiria to to ẹgbẹrun lọna mọkanlelogoje (141,000) si lo wọle si UK lọdun 2023.

Eyi si lo pọ julọ laarin awọn orilẹede adulawọ to lọ si UK lọdun 2023, to si se ipo keji laarin awọn orilẹede ti ko si ninu ẹgbẹ European Union.

Ẹgbẹ oselu Conservatives ati Reublican si ti kede pe iye awọn ajeji to n wọle si UK ti pọ lapọju.

Wọn wa kede pe awọn yoo mu gbigba awọn ajeji to jẹ osisẹ to poju owo ni ọkunkundun.

Bakan naa ni gbogbo ẹgbẹ oselu ni UK sọ pe awọn yoo fopin si asa gbigbe ara le awọn osisẹ to jẹ alejo to n sisẹ nilẹ UK.

Eto Ẹkọ awọn ajeji nilẹ UK

Ofin ilẹ UK lo n fi aaye gba awọn alejo to ba wa kawe nilẹ naa, ni anfaani ọdun meji lati sisẹ , ti wọn ko si le ko idile wọn wa si UK mọ.

Kikida awọn alejo to n kawe PHD nikan si ni ofin faaye gba lati mu idile rẹ wa silẹ UK.

Awọn ẹgbẹ oselu ninu idibo naa si ti ni ayipada ko ni ba awọn ofin yii.

Amọ oludije kansoso, Nigel nikan lo kede pe oun yoo fi ofin de gbogbo akẹkọ to ba wa lati orilẹede miran wa kawe nilẹ Uk lati ko ẹbi wọn wa pẹlu wọn.

Ibasepọ pẹlu awọn orilẹede miran

Lara ohun to se koko ninu eto idibo to n bọ naa ni bi ilẹ UK yoo se ni ibasepọ to pegede pẹlu awọn orilẹede miran nilẹ Afirika.

Awọn eeyan to n dije ibo ni UK si lo saayan pe awọn yoo gba awọn akẹkọ to dantọ wọle si UK.

Afojusun wọn naa si ni lati ri daju pe awọn akẹkọ yii yoo sisẹ sin ijọba ilẹ UK, ti wọn yoo si tun se ifẹ awọn orilẹede ti wọn ti wa.

Awọn onwoye ni igbasẹ naa ni yoo mu ki ajọsepọ to loorin waye larin ijọba ilẹ UK ati awọn orilẹede ilẹ adulawọ.