Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé oníwàásù, ògbufọ̀, tó tún n sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò,
Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́mọdé oníwàásù, ògbufọ̀, tó tún n sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní èdè Yorùbá

Yoruba bọ, wọn ni ọmọ ti yoo ba jẹ aṣamu, kekere ni yoo ti maa ṣe ẹnu ṣamu-ṣamu.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun Zion ati Fiyinfoluwa Kupolati , tẹgbọn-taburo to n waasu ọrọ Ọlọrun lori ayelujara.

Zion ọmọ ọdun meje ni ẹgbọn, oun si ni oniwaasu. Nigba ti aburo rẹ, ọmọ ọdun marun-un, jẹ ogbuf to n tu iwaasu wọn si ede Yoruba.

Yatọ si pe awọn ọmọ yii jẹ onwaasu, wọn tun mọ bi a ṣe n lo elo orin, paapaa duru.

Nigba to n ba BBC sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo, baba wọn, Ọgbẹni Oluwatoba Kupolati sọ pe ipe ọlọrun tootọ lo wa lori aye awọn ọmọ naa.

Zion fẹran lati maa tẹ duru, ati lati maa waasu.

Ọmọ ọdun marun-un aarin wọn ni oun fẹran lati maa gbadura, waasu ati lati maa ṣe ogbufọ.

Ẹbun wọn lo si bi ileeṣẹ iṣẹ iranṣẹ Z-Gold Ministries, eyi to jẹ oju opo ori ayelujara ti wọn ti n waasu.

Nigba to n sọ bi riinajo wọn sẹ bẹrẹ, iya awọn ọmọdebinrin naa, Arabinrin Olayemi Kupolati ṣalaye pe ere ni awọn ọmọ naa fi bẹrẹ, pẹlu lilo awọn nnkan elo idana bi orogun, lati waasu ninu ile wọn.

Lati ibẹ ni awọn obi wọn ti n fi awọn fidio iwaasu wọn si ori ayelujara, titi ti wọn fi di ilumọọka.

Awọn obi awọn ọmọ naa gbagbọ pe o ṣe pataki fun obi lati jẹ ki ọmọ lo ẹbun rẹ, ati pe ko si ẹbun ti ọmọ ni, ti ko gbọdọ sin Ọlọrun.