Mi ò ṣetán láti fi ipò àarẹ sílẹ̀ – Biden sọ̀rọ̀

Aare Biden ati igbakeji re, Harris

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden ti fi ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ati awọn oṣiṣẹ ipolongo idibo rẹ balẹ wi pe oun ko tii ṣetan lati fi ipo naa silẹ, gẹgẹ bi awọn iroyin kan ṣe n kọ ọ jade.

Awọn iwe iroyin naa lo ni o ṣee ṣe ki Biden wo ọjọ ọla rẹ lẹyin ohun to ba pade nibi itakurọsọ pẹlu Donald Trump lọsẹ to kọja.

Biden lo sọ eyi l’Ọjọru, ọsẹ yii nibi ounjẹ ọsan to jẹ ninu ile pẹlu igbakeji rẹ, Kamala Harris nile agbara funfun.

Ipade naa si lo da lori awuyewuye to n lọ kaakiri igboro wi pe boya ni yoo yan ẹlomiran lati ba dije ninu idibo to n bọ loṣu kọkanla, ọdun yii.

Aarẹ Biden ati igbakeji rẹ, Harris ti wa sọ fun gbogbo awọn alatilẹyin rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Democratic wi pe, oun ṣi wa ninu idije naa, ati pe igbakeji oun naa tun ti fi atilẹyin han.

Ero araalu ti ileeṣẹ iroyin CBS to n ṣiṣẹ pẹlu BBC gbe jade fihan pe Trump n bori pẹlu ami ayo mẹta, to si n lewaju Biden lawọn ipinlẹ ti eto idibo yoo ti ṣe daadaa

“Emi ni ẹgbẹ oṣelu Democratic fa kalẹ. Ko ṣi enikẹni to fẹẹ le mi jade.

Mi o kuro lọ sibi kankan.”

Ọrọ yii ni wọn tun fi ranṣẹ sori ikanni atẹjiṣẹ imeeli ti wọn n fi bẹbẹ fun owo lẹyin wakati diẹ lati ileeṣẹ ipolongo ti Biden-Harris.

“Ẹ jẹ ki n sọ eyi daju bi mo ṣe le sọ ọ pe: Mo n dije ninu idije yii titi de opin.”

Oriṣiriṣi ibeere lo ti n lọ kaakiri igboro ati ori ayelujara wi pe boya ẹni ọdun mọkanlelọgọrin naa yoo ṣi tẹsiwaju lẹyin itakurọsọ to ṣe pẹlu Trump, eyi ti wọn ni ko sọrọ daadaa, ati pe awọn idahun kan wa ninu ọrọ rẹ ti yoo ṣoro lati tẹle.

Wọn ni ọrọ Biden n kọ awọn eeyan lominu wi pe boya lo tọ lati tun wa nipo naa, tabi ko tun yege ninu idibo to n bọ naa.

Ọpọ lo ti n rọ Biden lati jawọ ninu idije naa lẹnu ọjọ meloo kan sẹyin pẹlu bi alatako rẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu Republican ṣe n lewaju.

Ninu eto idibo ayelujara ti New York Times gbe jade l’Ọjọru, ọsẹ yii lẹyin itakurọsọ naa, fi han pe Trump lo n bori pẹlu aami mẹfa.

Bakan naa ni ero araalu ti ileeṣẹ iroyin CBS to n ṣiṣẹ pẹlu BBC gbe jade laipẹ yii fi han pe Trump n bori pẹlu aami ayo mẹta, to si n lewaju Biden lawọn ipinlẹ ti eto idibo yoo ti ṣe daadaa.

Ibo ọhun fi han pe kaakiri orileede naa ni Trump tun ti n bori.

Ibo ọhun ti ko lọ bo ṣe yẹ lo ti n mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic ati awọn aṣofin maa pe aarẹ wọn lati pe ko lọ jokoo.

Ramesh Kapur, to jẹ alẹnulọrọ nilẹ Indian ati Amerika to n gbe ni Massachusetts, ti gbe ọpọ eto ipawo-wọle kalẹ fun ẹgbẹ oṣelu Demcratic lati ọdun 1988.

“Mo lero wi pe o ti to asiko lati jawọ,” Ọgbẹni Kapur sọ fun BBC. “Mo mọ pe o ni ọkan lati ṣiṣẹ, ṣugbọn eeyan ko le ba ara rẹ ja.”

"Awọn iroyin kan sọ pe aarẹ sọ fun alafọrọlọ rẹ pe oun naa mọ pe ipadasipo oun lẹẹkeji wa labẹ ewu"

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic meji ti wọn wa nibi ipade to waye ni wọn sọ pe ki ẹgbẹ naa tikẹẹti kuro lọwọ ẹni ti wọn fun. Raul Grijalva to n ṣoju Arizona, sọ fun New York Times wi pe asiko ti to fun ẹgbẹ wọn lati “fi oju si ibomiran”.

Lẹyin gbobo eyi, White House ti Amẹrika ati igbimọ olupolongo Biden ti tako awọn iroyin to n jade wi pe ọkunrin naa n wo ọjọ iwaju rẹ, to si ni oun ṣetan lati fidi Trump rẹmi lẹẹkeji lọjọ karun-un, oṣu kọkanla.

Ileeṣẹ iroyin New York Times ati CNN l’Ọjọru ti gbe iroyin sita wi pe Biden ti sọ fun alafọrọlọ rẹ kan wi pe oun ṣi n ṣagbeyẹwo boya oun yoo ṣi tẹsiwaju ninu idije naa.

Awọn iroyin naa sọ pe aarẹ sọ fun alafọrọlọ rẹ ọhun oun naa mọ pe ipadasipo oun lẹẹkeji wa labẹ ewu, ati pe awọn ibi toun yoo ti farahan nibi ifọrọwerọ, to fi mọ ti ileeṣẹ iroyin ABC, ati ti ipolongo ọjọ Ẹti ni Wisconsin ṣe pataki pupọ si ipolongo oun.

Agbẹnusọ rẹ kan ti tako awọn iroyin naa wi pe “irọ lasan ni���, iyẹn nigba to ku asiko diẹ di akọwe iroyin White House, Karine Jean-Pierre koju awọn ibeere nipa bi Biden yoo ṣe farajin fun idibo naa.

O ni awọn iroyin wi pe Biden le jawọ ninu eto idibo naa kii ṣe otitọ” A beere lọwọ aarẹ, o si dahun daadaa wi pe ko le ri bẹẹ, ati pe irọ to jinna si otitọ ni.”

Ninu ipe si ọkan lara awọn oṣiṣẹ White House l’Ọjọru, olori awọn oṣiṣẹ aarẹ, Jeff Zients gba wọn lamọran lati fọkan balẹ, gẹgẹ bi iroyin CBS ṣe gbe e.

“Ẹ mu iṣẹ eyi ṣe. Ẹ bẹrẹ iṣẹ. Ẹ bẹrẹ iṣẹ. Ẹ bẹrẹ iṣẹ.

“Ọpọ nnkan lo wa to gbọdọ maa mu imuri ba a yin, ati pe ọpọ nnkan la le ṣe papọ labẹ iṣakoso aarẹ yii.”

Ọmọ ẹgbẹ kan sọ fun BBC pe awọn fẹ ki wọn fa igbakeji Aarẹ, Harris kalẹ bii oludije sipo aarẹ bi Biden ba ni oun ko ṣe mọ

Ọgbẹni Biden ti ba gomina Democratic ogun kaakiri orileede naa ṣepade, to fi mọ gomina Gavin Newsom ti California ati Gretchen Whitmer ti Michigan l’Ọjọru.

Awọn meji yii ni wọn ti n gbero nipa wọn wi pe wọn yoo ṣe daadaa bi Biden ba sọ pe oun ti jawọ.

“Aarẹ maa n duro ti wa, awa naa yoo si duro digbi lẹyin aarẹ”, gomina Maryland, Wes Moore sọ eyi fawọn akọroyin lẹyin ipade.

Gomina New York, Kathy Hochul sọ pe awọn gomina to ṣẹṣẹ pari ipade pẹlu aarẹ ni wọn ṣeleri atilẹyin lati duro ti aarẹ, bẹẹ si ni Ọgbẹni Biden ṣeleri lati pe “oun wa ninu idije lati bori.”

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ṣi n ṣagbeyẹwo boya ki wọn rọpo Arabinrin Harris, ṣugbọn atilẹyin rẹ lo fi ojoojumọ ga sii laarin awọn oloṣelu Democrats latigba ti itakurọsọ Biden-Trump ti bẹrẹ.

Loju ẹsẹ lẹyin itakurọsọ ni igbakeji aarẹ ti lọ ṣe ifọrọwerọ pẹlu CNN, nibi to ti n fi da awọn eeyan loju pe digbi loun wa lẹyin aarẹ lati

ṣatilẹyin fun un.

“Ko si ohunkohun to fẹẹ yi pada”, ẹnikan to sunmọ Arabinrin Harris sọ fun BBC, to si tun ni obinrin naa yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ojuṣe rẹ lori ipolongo.

“Gbogbo igba lo n jẹwọ ara rẹ lati jẹ olubaṣiṣẹpọ tootọ fun aarẹ,” alakoso eto ikansira-ẹni tẹlẹ fun Harris, Jamal Simmons lo sọ eyi.

“Awọn alẹnulọrọ ti yoo ṣe ipinnu ẹni ti wọn yoo fa kalẹ ni awọn ti wọn n fi atilẹyin wọn han. Ipo rẹ si ni lati jẹ olubaṣiṣẹpọ tootọ sii.”

Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ apapọ fun ẹgbẹ oṣelu Democratic (DNC) ni wọn n gba niyanju lati dibo fun Aarẹ Biden, ko le jẹ oludije fun ẹgbẹ naa nibi ipade gbogboogbo ti yoo waye ninu oṣu kẹjọ, ti wọn si fẹ ko wa ninu iwe idibo kaakiri orileede naa.

Ọmọ ẹgbẹ kan to ti ba awọn ọmọ igbimọ yooku sọrọ sọ fun BBC pe awọn fẹ ki wọn fa igbakeji Aarẹ Harris kalẹ bi Biden ba loun ko ṣe mọ.

“Bi a ba ṣiṣọ loju ipade gbogboogbo ọhun, rukerudo nla ti yoo pa wa lara ninu oṣu kọkanla ni yoo da silẹ,” wọn sọ eyi.

Iroyin kan ti ileeṣẹ Washington Post gbe jade, sọ wi pe Ọgbẹni Biden gbọdọ jẹwọ ara rẹ lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe oun tọ si ipo naa bo ba ṣe n jade.

O rawọ ẹbẹ yii nibi ayẹyẹ ‘Medal of Honor’ to waye l’Ọjọru, to si loun ti ṣagbekalẹ irin ajo lọ si Wisconsin ati Philadelphia ki ọsẹ yii too pari.