Iléeṣẹ̀ ilẹ̀ òkèrè 71 ló jẹ gbèsè kúrò ní Nàìjíríà nítorí jìbìtì orí ayélujára – EFCC

Aworan awọn afurasi onijibiti ori ayelujara ti EFCC mu

Oríṣun àwòrán, EFCC@X

Ko din ni ileeṣẹ ilẹ okeere mọkanlelaadọrin ti wọn ti fi orilẹ ede Naijiria silẹ bayii latari jibiti ori ayelujara ti wọn lu wọn, eyi to ko wọn si gbese.

Ọga agba ajọ to n ri si ajẹbanu ni Naijiria (EFCC),Ola Olukoyede to sọrọ yii, ṣalaye pe lọdun 2022, ki i ṣe pe awọn ileeṣẹ naa kuro ni Naijiria nikan, owo to tun le ni ẹẹdẹgbẹta milọnu dọla( $500 m) ni orilẹede yii funra rẹ padanu sọwọ awọn ọmọ Yahoo.

O fi kun un pe aburu ti jibiti ori ayelujara ti ṣe fun ọrọ aje Naijiria ko kere rara, o si ti ba nnkan jẹ gidi lẹka naa.

Ninu atẹjade kan ti olori ẹka iroyin EFCC, Dele Oyewale fi sita, ọga agba EFCC, tun ṣalaye pe Yahoo tawọn eeyan n ṣe ni Naijiria ti sọ ilu yii di alabuku lẹyin odi.

Olukoyede sọ nipa bi ọmọ Naijiria ko ṣe ni anfaani lati ra ọja pẹlu adehun lati sanwo lọjọ iwaju, eyi ti a mọ si Credit card.

O ni nibi to buru de,ẹni to ba fẹẹ ra ohunkohun lọdọ oyinbo ni lati lowo ninu apo ikowosi rẹ ni, ti wọn yoo yọwọ naa lẹsẹkẹsẹ ninu akanti rẹ (Debit card).

Nipa idi ti eyi fi ri bẹẹ, ọga EFCC ṣalaye pe iwa jibiti to gbokun nilẹ wa lo fa a. O ni awọn eeyan ko nigbagbọ ninu jijẹ ọmọluabi ẹni to ba ti jẹ ọmọ Naijiria.

Yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ ni wọ́n n yẹ ọmọ Nàìjíríà wò níbi tí wọn kò ti dààmú àwọn ọmọ ìlú míràn rárá

Aworan ọga EFCC,Ola Olukoyed ati atọka ileeṣẹ EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC@X

Nibi ti iwa jibiti ti ko abuku ba Naijiria de, Olukoyede ṣalaye pe awọn ileeṣẹ ilẹ okeere kan wa ti wọn ki i gba keeyan lo kaadi Naijiria lọdọ wọn rara.

‘’Iwọ fi paali alawọ ewe rẹ han wọn pe ọmọ Naijiria ni ọ, ki o waa wo o boya wọn ko ni i mu ọ jade ti wọn yoo yẹ gbogbo ara rẹ wo yẹbẹyẹbẹ’’

Ọga EFCC ṣalaye pe ibi ti awọn ọmọ orilẹede ibo mi-in yoo wọ nirọrun, iwa jibiti ti wọn mọ nipa Naijiria ko ni i jẹ ki wọn gba ọmọ orilẹede yii laaye kia lati wọle.

O ni o ṣe pataki ki Naijiria gbogun ti jibiti kaakiri ẹka, nitori o ti sọ awọn eeyan ibẹ di alabuku kaakiri.

‘’A maa bẹrẹ atunṣe yii lati ibi pẹlẹbẹ ni, a si maa gbe e de oke pẹlu.

‘’Awọn mi-in ninu awọn to n jale nipo giga yii bẹrẹ lati ijọba ibilẹ. Wọn bẹrẹ gẹgẹ bii olori ẹgbẹ nileewe, wọn n ji owo,ẹnikẹni ko si ṣe ohunkohun si i titi to fi mọ wọn lara.

Olukoyede lo sọ bẹẹ.

Aworan ọrọ ti Alaga EFCC sọ loju opo X ajọ naa

Oríṣun àwòrán, EFCC@X

N30bn la bá ní báńkì méjì tó jẹ́ ti Mompha, owó yìí ló rí látinú ìwà jìbìtì wíwọ́ ike - EFCC

Aworan Mompha

Oríṣun àwòrán, Mompha @Instagram

Ajọ to n ri si ajẹbanu lorilẹede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti tako ọkunrin jayejaye to gbajumọ lori ayelujara nni, Ismaila Mustapha tawọn eeyan mọ si Mompha, lori owo rẹpẹtẹ ti wọn tọpinpin de apo ikowopamọ si rẹ ni banki.

Atọpinpin kan to jẹ oṣiṣẹ lọdọ ajọ EFCC, Idi Musa, jẹri tako Mompha ni kootu lọjọ Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje ọdun 2024 yii, nigba to ni oun tọpinpin biliọnu lọna ọgbọn si akanti ọmọ jayejaye ọhun.

Mompha, ẹni ti wọn ṣi n wa titi di asiko yii ni wọn lo ni ileeṣẹ kan torukọ rẹ n jẹ Ismalob Global Investment Ltd.

Mompha ati ileeṣẹ rẹ ni EFCC pe lẹjọ, lori ẹsun ṣiṣe okoowo to lodi sofin, ṣugbọn ti wọn n fi nnkan mi-in boju bii iṣẹ gidi ti wọn n ṣe lati ri owo. (Money laundering).

EFCC ni oun ti ri owo nla to wa ninu asunwọn Mompha ni banki Fidelity ati Zenith to n lo.

Ẹlẹrii EFCC to tako Mompha, ṣalaye pe ninu itọpinpin loun ti ri aṣiri Mompha ati ileeṣẹ rẹ .

Idi Musa tẹsiwaju ninu atako naa pe ni 2019, ẹka ijọba apapọ to n wadii (FBI), ta EFCC lolobo nipa jibiti ori ayelujara ti Mompha ati ileeṣẹ rẹ lu awọn eeyan lorilẹde Amẹrika.

O fi kun un pe laarin Naijiria ati awọn orilẹede oke okun ni Mompha ati ileeṣẹ rẹ ti n ‘wọ́ke’, ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara.

Báwo ni EFCC ṣe ṣàwárí 30b lákàńtì Mompha?

Aworan Mompha

Oríṣun àwòrán, Mompha @Instagram

Iwadii fi han pe Mompha ko gbe ni Naijiria, gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati mu un ko si yọri si rere bayii

Gẹgẹ bi Idi Musa to jẹ ẹlẹrii kẹfa lori ẹsun yii ṣe ṣalaye, o ni, ‘’laaarin kan lasiko iwadii, a kọ lẹta si banki Zenith, nibi ti a ti beere fun alakalẹ owo to wọ akanti ileeṣẹ Mompha (Statement of account).

‘’A tun kọwe si banki Fidelity ati awọn mi-in ti olujẹjọ n lo, a si yanna-yanna rẹ delẹdelẹ.

‘’Nigba ti a n yẹ awọn esi banki yii wo, a ri ọgbọ̀n biliọnu (30b) to wọle si akanti Mompha, olujẹjọ akọkọ, iyẹn ninu akanti Fidelity rẹ, a si ri biliọnu marun-un mi-in to wọle si apo ileeṣẹ rẹ, olujẹjọ keji, iyẹn jẹ ti Zenith banki.‘’

Ẹlẹrii EFCC yii sọ pe awọn kọwe si FBI ati ẹka to n ri si jibiti to yatọ nileeṣẹ EFCC (Special Fraud Unit).

O ni awọn kọwe naa lati jẹ ki wọn mọ ohun to n ṣẹlẹ, nitori Mompha ti sọ fun wọn pe iṣẹ abanipaarọ owo (Bureau De Change) loun n ṣe.

O fi kun un pe awọn fi ẹda iwe naa ranṣẹ si banki apapọ ilẹ wa, CBN pẹlu awọn ẹka mi-in to tun yẹ ko gbọ.

Iwadii fi han pe olujẹjọ yii ko gbe ni Naijiria, gbogbo igbiyanju awọn agbofinro lati mu un ko si yọri si rere bayii.

“ Ni 2019, lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa, a kọ lẹta si ẹka to n ri si iwọle-jade awọn arinrinajo ni Naijiria, pe ki wọn ba wa mu Mompha nigbakigba to ba wọ Naijiria.

“ Nigba to di ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa ọdun 2019 yẹn, Mompha gbọ pe EFCC n wa oun nigba to wa ni Naijiria, o sare gba papakọ ofurufu lọ lati tete maa sa lọ.

“ Awọn to fẹẹ mu olujẹjọ naa debẹ wọn si ri i pe o ti pari eto lati maa rin irinajo rẹ, wọn mu un pẹlu awọn ẹru to ko dani, wọn si fa a le ajọ EFCC lọwọ.’’

Bẹẹ ni Idi Musa, ẹlẹrii EFCC sọ.

Ṣe lóòótọ́ ni Mompha jẹ́ abánipààrọ̀ owo?

Aworan Mompha

Oríṣun àwòrán, Mompha @Instagram

Idi Musa sọ fun kootu pe Mompha ki i ṣe abanipaarọ owo (Bureau de Change). O ni irọ gbuu leyi ati pe olujẹjọ to ti sa lọ naa ko sọ otitọ nipa iṣẹ to n ṣe.

O ni iwadii awọn lorii Mompha da lori ṣiṣe okoowo ti ko ba ofin mu, ṣiṣi ibudo abanipaarọ owo lai gba iwe aṣẹ. Ẹsun mejeeji yii lo ni olujẹjọ ṣi n jẹjọ rẹ nile ẹjọ giga to wa ni Ikoyi, niluu Eko.

“ Itọpinpin awọn FBI ati ti iwadii kan fi han pe wọn lo foonu iPhone Mompha lati fi beere nọmba aṣiri banki kan ni United Arab Emirates.

“ Nigba ti a mu olujẹjọ yii, gbogbo ẹru ti a gba lọwọ rẹ la ko kalẹ bi ẹri, a si tọju wọn si ọfiisi EFCC. Pupọ awọn ẹru naa la da a pada fun un pẹlu adehun ati ajọsọ, afi iPhone 8 rẹ nikan to ṣi wa pẹlu ajọ EFCC.

“Gbogbo awọn nnkan to ko jọ yii naa, eru lo fi ko wọn jọ, nitori nigba ti a fun un ni fọọmu lati kọ awọn ohun to ni, Mompha ko kọ awọn nnkan naa silẹ’’

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii ni Adajọ Mojisola Dada, sun igbẹjọ si fun itẹsiwaju.