Ọkọ la ikún Òjòlá láti gbé òkú aya rẹ̀ tó di àwátì láìpẹ́ jáde

Àkọlé fídíò, Awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn ninu aginju pẹlu oku ejola naa

Obinrin kan ni wọn ti ba oku rẹ ninu ikun ejola lorileede Indonesia.

Awọn ejo ohun kii saba maa n jẹ eeyan, ṣugbọn sibẹ, eyi ni yoo jẹ iṣẹlẹ keji to ti waye ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin.

Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Siriati, lo di awati lati ọjọ Iṣẹgun, lẹyin ti wọn lo kuro nile rẹ lati lọ ra oogun fun ọmọ rẹ, gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe ṣalaye.

Ọkọ rẹ, Adiansa lo fi to awọn alakoso eleto aabo leti lẹyin to kofiri bata ati aṣọ rẹ ni ẹẹdẹgbẹta kilomita si ile wọn to wa ni abule Siteba, ẹkun Guusu Sulawesi.

Lasiko to n ba BBC sọrọ, alakoso ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa , Idul, sọ pe ọkọ Arabinrin naa lo ri ejola ọhun laaye, to si ge ori rẹ soju ọna.

Lẹyin naa lo sọ pe Adiansa la ikun ejola ọhun lati ri oku iyawo rẹ nibẹ.

Ni aṣẹṣẹbẹrẹ oṣu kẹfa, obinrin kan ni ejola to gun ni iwọn bata ẹsẹ mẹfa, pa jẹ ni ékun miran to wa ni Guusu Sulawesi.

Awọn ọlọpaa ti wa gba awọn agbegbe ọhun lamọran lati maa mu ọbẹ rin, lati le fi doola ẹmi ara wọn nigba ti wọn pade ejola lọna lojiji.

Awọn ara abule pẹlu oku ejola naa

Oríṣun àwòrán, Police handout

Àkọlé àwòrán, Nibi ti wọn ti pa ejola naa ninu igbo

Awọn onimọ nipa ọrọ agbegbe ni South Sulawesi Environmental Institute ni erongba nla nipa ajọsẹpọ to wa laarin igbo gige ati ki iru awọn ẹranko bayii maa ṣe ikọlu si awọn eeyan.

Alakoso rẹ, Muhammad Al Amin, sọ fun BBC pe igbo piparun fun iwakusa ati ọgbin igi ti pọ si: "Atubọtan rẹ ni pe nigba ti awọn ẹranko wọnyi ba sare jade lati wa ounjẹ, awọno agbegbe ti eeyan n gbe ni wọn yoo ti wa ounjẹ, ati pe eeyan ni wọn yoo ṣọdẹ lati pa jẹ.

Ọga ọlọpaa, Idul sọ pe awọn olugbe agbegbe naa fura pe ejola ọhun maa n farapamọ nitori awọn ẹranko buruburu to maa n bu ramuramu, eyi ti ejola yii n dọdẹ wọn.

Ṣugbọn sibẹ, awọn ẹranko buruku yii kii sabaa si ninu igbo mọ.

Idul wa rọ awọn eeyan lati ma ṣe maa da rin mọ bi wọn ba n rin irin-ajo lagbegbe naa.

Ejola kan ree to n dọdẹ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ejola le tobi to iwọn mita mẹwaa.

Bawo ni ejo ṣe n jẹ eeyan?

Awọn ejola to n pa awọn eeyan jẹ ni Indonesia ni wọn maa n dọdẹ pẹlu ọgbọn alumọkọrọyi.

Wọn maa n gun kọja mita mẹwaa (32ft), bẹẹ si ni wọn lagbara gidi.

Wọn maa ṣe ikọlu lẹyin ti wọn ba farapamọ lati dọdẹ ounjẹ wọn, wọn yoo si raga bo ọunjẹ wọn, ti wọn yoo si fun un titi ẹmi yoo fi bọ lara ounjẹ wọn naa.

Ounjẹ wọn naa yoo pofolo ku laarin iṣẹju aaya.

Ejola maa n gbe gbogbo ounjẹ wọn min tan lẹẹkan ṣoṣo ni. Ẹnu wọn fẹlẹ debi wi pe o le fẹ lati gbe ounjẹ wọn min lai nii ṣe pẹlu bi ounjẹ naa ṣe tobi to.

Nigba to ba di ibi pe o fẹẹ jẹ eeyan, "ibi ejika mọ apa ẹni naa ni yoo fun mọ lati kan an danu" Mary-Ruth Low, oniṣẹ iwadii nipa ẹranko ni Wildlife Reserves Singapore, to tun mọ nipa bi ejola lo sọ fun BBC nibi ifọrọwerọ.

"Awọn ẹranko to n rin ni ejola maa n saba pa jẹ," Low sọ eyi, bo tilẹ jẹ pe wọn kii saba jẹ awọn ẹranko to n fi aya fa, to fi mọ aleegba tabi ọọni.

Ṣibẹsibẹ, wọn tun maa n jẹ eku ati awọn ẹranko kekere miran, " ṣugbọn to ba ti di pe ikun wọn tobi de ipele kan, wọn kii ronu nipa awọn ẹran eku mọ nitori ohun to n gbe ounjẹ yoo ti tobi.

"Ati pe awọn naa le tobi, bi ounjẹ ti wọn ba gbe ba ṣe to ni yoo sọ bi awọn naa yoo ṣe tobi to."

Bakan naa ni wọn le gbe awọn ẹranko bii ẹlẹdẹ, ati paapaa maalu min.