Kí ló dé táwọn òbí ṣe ń ti ara wọn mọ́ ẹ̀wọ̀n nítorí ọmọ?

Ọmọkùnrin tó jókòó da ojú délẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Author, Hyojung Kim
  • Role, BBC Korean

Nǹkan ẹyọ̀ kan tó ń so àwọn ènìyàn tó wà ní iléeṣẹ́ tó ń pèsè ìdùnnú papọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó wà lóde ní orílẹ̀ èdè South Korea, ni ojú ihò tí wọ́n fi ń fún wọn ní oúnjẹ nínú yàrá tí wọ́n wà.

Kò sí ààyè láti lo fóònù tàbí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà nínú yàrá kótópó bíi ẹ̀wọ̀n tí wọ́n wà, tó sì jẹ́ pé ògiri ni wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́ níbẹ̀.

Àwọn olùgbé ibẹ̀ le wọ aṣọ péńpé olómi aro tí wọ́n bá fẹ́ àmọ́ wọn kìí ṣe ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n kàn wà níbẹ̀ láti ní ìrírí àti mọ̀ bí ó ṣe máa ń rí tí èèyàn bá ń dá wà.

Gbogbo àwọn tó fẹ́ ní ìrírí ni wọ́n ní nǹkan tó jọ ara wọn – wọ́n ní ọmọ tó máa ń dá wà ní gbogbo ìgbà láì dá sí ẹnikẹ́ni.

Ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń fi ara wọn sí

Báwọn èèyàn ṣe ń dá wà yìí ni wọ́n ń pè ní “hikikomori” ní èdè Japan, ní ọdún 1990 ni wọ́n ṣe àtòjọ orúkọ yìí láti júwe bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń yọ ara wọn láàárín àwùjọ.

Láti inú oṣù Kẹrin ọdún yìí ni àwọn òbí ti ń kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́tàlá èyí tí àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba, Korea Youth Foundation àti Blue Whale Recovery Centre ń ṣe agbátẹrù rẹ̀.

Èròńgbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ni láti kọ́ àwọn òbi nípa bí wọ́n yóò ṣe máa bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ dáadáa.

Dídáwà nínú yàrá kan tó jọ ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹ́ta ní Hongcheon, ẹkùn Gangwon wà lára ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún.

Ìrètí ni pé dídáwà náà yóò jẹ́ kí àwọn òbí ní ìmọ̀ kíkún nípa àwọn ọmọ wọn.

Ẹ̀wọ̀n ẹ̀mí

Ọmọkùnrin Jin Young-hae ti ń dá wà nínú yàrá rẹ̀ láti bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn báyìí.

Àmọ́ láti ìgbà tí Jin(kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) fúnra rẹ̀ ti wà ní àhámọ́, ló ti ní ìmọ̀ kíkún lórí ipò tí ọmọ rẹ̀, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún wà dáadáa.

“Mo ti ń rò ó pé kí ni mo ṣe láì da tó fi rí báyìí, ó sì le láti máa rò ó,” ìyá ẹni àádọ́ta ọdún náà sọ.

“Àmọ́ nígbà tí mò ń rò ó báyìí, ó ti ń yé mi díẹ̀ díẹ̀.”

Kọ̀ láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀

Jin ṣàlàyé pé ọmọ òun jẹ́ ẹni tó jáfáfá, tí òun àti bàbá rẹ̀ sì ní ìrètí tó ga nínú rẹ̀.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ ẹ́, ní ìṣòro láti yan ọ̀rẹ́ kan, tí kìí jẹun dédé, tó di di pé ó ṣòro fún láti máa lọ sílé ẹ̀kọ́.

Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, ó ń ṣe dada ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan ló pinnu pé òun kò lọ sílé ẹ̀kọ́ mọ́.

Ó ní ó máa ń jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún òun nígbà tí òun bá ri tó ti ara rẹ̀ mọ́ inú yàrá láì dá sí ẹnikẹ́ni àti pé kìí tọ́jú ara rẹ̀ mọ́.

Ó wòye pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ìṣòro tó ń ní pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́, àti pé wọn kò gbà á sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tó fẹ́ gan ló fa ìwà tó ń wù àmọ́ síbẹ̀ ó kọ̀ láti bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń ṣe é ní pàtó.

Àwọn òbí tó ti ara wọn mọ́ inú túbú

Oríṣun àwòrán, Korea Youth Foundation

Nígbà tí Jin dé iléeṣẹ́ Happiness Factory, ó ka ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ọ̀dọ́ tó ń ya ara wọn sọ́tọ̀ kọ.

“Nítorí ọmọ mi kò bá mi sọ̀rọ̀ bí alárà, mi ò mọ̀ nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ̀.”

“Kíka àwọn nǹkan jẹ́ kí n máa rò ó pé ó ń fi dídákẹ́ rẹ̀ dá ààbò bo ara rẹ̀ ni.”

Park Han-sil (kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) náà lọ sí Happiness Centre nítorí ọmọ rẹ̀, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, tí kìí dá sí ẹnikẹ́ni láti ọdún méje sẹ́yìn.

Lẹ́yìn tó máa ń sá nílé fún ìgbà kan tẹ́lẹ̀, ní báyìí kìí sábà jáde kúrò nínú yàrá rẹ̀.

Park ní òun mu lọ rí àwọn dókítà àtàwọn tó máa ń gba èèyàn nímọ̀ràn àmọ́ ọmọ òun kọ̀ láti lo àwọn oògùn tí wọ́n fun, géèmù ló máa ń fi ojoojúmọ̀ ta.

Ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn

Nígbà tí Park ń gbìyànjú láti bá ọmọ rẹ�� sọ̀rọ̀ ló pinnu láti mọ̀ nípa nǹkan tó ń kojú nípa ètò dídáwà tó ṣe.

“Mo ti ri báyìí pé ó dára láti gba ọmọ mi bó ṣe rí láì fi tipátipá mu láti rí bákan bí mo ṣe fẹ́,” ó sọ.

Iléeṣẹ́ ètò ìlera àti ìgbáyégbádùn nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe lọ́dún 2023 ní ìdá márùn-ún nínú àwọn ènìyàn 15,000 tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kàndínlógún sí mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni wọ́n máa ń dá wà láì dá sí ẹnikẹ́ni.

Tí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé South Korea, ó túmọ̀ sí pé èèyàn 540,000 ló ń kojú ìṣòro yìí.

Ìwádìí náà ní àwọn ohun tó ń fà á ni:

  • Àìrí iṣẹ́ (24.1%)
  • Ìṣòro pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ènìyàn (23.5%)
  • Ìṣòro ẹbí (12.4%)
  • Àìlera (12.4%)
Obìnrin tó ń dáná

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní Japan, bí àwọn ènìyàn ṣe ń ya ara sọ́tọ̀ kúrò ní àwùjọ tó bẹ̀rẹ̀ ní 1990 jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ máa gbọ́kànlé àwọn òbí wọn.

Èyí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ òbí tí wọ́n ti darúgbó, tó jẹ́ pé owó ìfẹ̀yìntì ni wọ́n ń ná di tálákà paraku.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Jeong Go-woon ti ẹ̀ka sociology ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Kyung Hee ní bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn àṣeyọrí ọmọ ni wọ́n fi ń ṣe òdiwọ̀n bí òbí ṣe ṣàṣeyọrí sí ń dá kún bí àwọn òbí ṣe ń dá wà.

Ó ní ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń rí ara wọn bíi ẹni tó kùnà nínú ojúṣe rẹ̀ nígbà tí ọmọ wọn bá ń ní ìpèníjà kan tàbí òmíràn.

“Ní Korea, àwọn òbí máa ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ nípa nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe dípò ọ̀rọ̀ ẹnu lásán.”

Obinrin tó ń ronú nílẹ̀ tó jókòó sí

Oríṣun àwòrán, Korea Youth Foundation

Àkọlé àwòrán, Àwọn òbí kan ní àwọn ti ń mọ̀ nípa àwọn ọmọ àwọn si

Adarí Blue Whale Recovery Centre, Kim Ok-ran ní wíwòye pé àwọn ọ̀dọ́ tó máa ń dá wà jẹ́ ìṣòro mọ̀lẹ́bí túmọ̀ sí pé àwọn òbí náà máa ta àwọn tó súnmọ́ wọn dànù.

Ó ní àwọn míì tún máa ń bẹ̀rù débi wí pé wọn kìí lè bá àwọn tó súnmọ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tí wọ́n ń kojú.

“Nígbà mìíràn wọn kò ní lọ síbi ìpéjọ ẹbí pàápàá lásìkò ayẹyẹ.”

Ṣíṣe àmójútó

Àwọn òbí tó ti lọ sí Happiness Factory fún ìrànlọ́wọ́ ṣì ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí àwọn ọmọ wọn máa padà sípò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀.

Nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ Jin ohun tó máa bèèrè lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀ nígbà tó bá jáde síta láti inú yàrá tó wà, omi lé ròrò lójú rẹ̀.

Pẹ̀lú ohùn gbígbọ̀n ló fi dáhùn pé òun máa sọ fún pé òun mọ̀ pé ó ti la ọ̀pọ̀ nǹkan kọjá.

“Ó le púpọ̀.”

“Mà á ri dájú pé mò ń mójútó ẹ dada.”

Tí o bá ní ìṣòro tó jọ mọ́ èyí tí ó wà nínú iṣẹ́ yìí, gbìyànjú láti kàn sí àwọn onímọ̀ ìlera tó péye ní agbègbè fún àmójútó tó yẹ.