Wo ìdí tí ṣíṣe nǹkan oṣù ṣe ń nira fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lórílẹ̀èdè Nàìjíríà jú àwọn akẹgbẹ́ wọn lágbáyé

Aworan  obinrin to n gba paadi

Oríṣun àwòrán, MCCRISSAR FOUNDATION

Bi ọwọngogo bi ba ounjẹ jijẹ naa lo tun ti de ba rira owu nnkan oṣu fun awọn obinrin lasiko yii lorilẹede Naijria.

Iwadii fihan pe ọpọ awọn obinrin lo nira fun lasiko yii lati fi owo paadi nnkan oṣu, to si n fa akoba nla fun ilera wọn.

Khairat Badamasi, olugbe ilu Abuja ba BBC sọrọ lori ohun to n dojukọ lori ọrọ paadi lasiko yii.

“Ti mo ba se nnkan oṣu, mo ma n wọ paadi sugbọn pẹlu bi nnkan se ri lasiko yii, n ko ni agbara lati ra paadi.”

Grace Solomon, onisowo niluu Abuja ni oun ni lati ma lo nnkan mi lati di nnkan oṣu oun nitori oun ko ni agbara lati ra paadi.

“Ọpọ igba ti mo n ba se nnkan oṣu, mo joko si ile nitori ẹru n ba mi pe ki oju ma ti mi, ti ẹjẹ ba bẹrẹ si ni jade.”

Iṣoro paadi yii ni ki se pe orilẹede Naijiria nikan lo ti n waye, o jẹ nnkan ti gbogbo agbaye n dojukọ lasiko yii.

Ni ọdun 2021, minisita fun ọrọ obinrin lorilẹede Naijiria, Dame Pauline Tallen sọ pe o le ni milọnu mẹtadinlogoji obinrin lorilẹede Naijiria ti ko ni agbara lati ra paadi nitori ọwọngogo.

Iwadii banki agbaye kan lọdun 2021 fihan pe ai si awọn paadi n fa ọpọ iṣoro fun awọn obinrin, to si n se akoba fun eto ilera wọn.

Dokita Anisa Ambursa sọ pe nnkan ti awọn obinrin ma n se lasiko ti wọn ba se nnkan oṣu ma fa iṣoro fun ilera wọn.

“A ti pese idanilẹkọ fun obinrin ti yoo wulo fun wọn lasiko ti wọn ba se nnkan oṣu. O daara ki wọn lo omi to mọ, ki wọn si ma parọ paadi lorekore.

“Eyikeyi obinrin to ba kuna lati se itọju ara rẹ lasiko nnkan oṣu rẹ ni o ṣeeṣe ko koju awọn aisan to le ṣe akoba nla.

Paadi ọfẹ

Ọpọ igbinyanju lo ti wa lati fopin si iṣoro paadi to sọwọn lorilẹede Naijiria, ti ọpọ ileeṣẹ ati awọn eeyan kan si n gbe igbesẹ lati mu ayipada de ba nnkan to sẹlẹ lọwọ.

Rabi Adamu, oludasilẹ Mcrissar Foundation n pese iranwọ fun awọn obinrin ati ọmọde.

“A ri iṣoro nnkan oṣi gẹgẹ bii eyi to sokunfa iṣoro nal fun ilera awọn obinrin ni ọpọlọpọ ọna.

“Bi ko se si idanilẹkọ ati paadi n se akoba nla fun eto ẹkọ awọn obinrin ni agbegbe wa,:

O ni eyi jẹ idi kan pataki to fi da ileeṣẹ naa silẹ lati pese idanilẹkọ fun awọn obinrin.