Ta ni Sir Keir Starmer, olóòtú ìjọba tuntun ilẹ̀ Gẹẹsi?

Keir Starmer making a speech

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sir Keir Starmer ti di olootu ijọba tuntun fun ilẹ Gẹẹsi lẹyin to jawe olubori ninu idibo gbogbogbo to waye ninu ẹgbẹ oṣelu Labour.

Ọdun mẹrin sẹyin ni alagba Keir gba ipo Jeremy Corbyn gẹgẹ bii adari ẹgbẹ oṣelu Labour, lati igba naa lo si ti bẹrẹ iṣe lati da ẹgbẹ ọhun pada soke tente oṣelu ilẹ Gẹẹsi

Ọdun mẹrinla sẹyin ni ẹgbẹ oṣelu naa ti wa ni ipo agbara kẹyin.

Igbeaye rẹ ṣaaju oṣelu

Lẹyin to le lẹni aadota ọdun ni Sir Keir di ọmọ ile aṣofin, iyẹn lẹyin to ti kọkọ ṣiṣẹ gẹgẹ bii agbẹjọro fun ọpọ ọdun.

Ọdun 1952 ni wọn bi niluu London, to si jẹ ọkan lara awọn ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ bi.

O dagba ni Surrey, nọọsi ni iya rẹ nigba ti baba jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ to n pese nnkan.

Ẹgbẹ oṣelu Labour ni awọn obi rẹ ṣatilẹyin fun lati ibẹrẹ pẹpẹ, awọn obi rẹ naa mọọmọ fun ni orukọ Keir gẹgẹ bii orukọ Keir Hardie, to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu Labour akọkọ ni Scotland.

Ọkunrin naa sọ pe ibẹrẹ aye oun ko rọrun latari bi baba rẹ ko ṣe ni ibarẹpọ to dan mọran pẹlu rẹ.

Arun kan ti wọn n pe ni ‘Still’s disease’ ba iya rẹ finra fun ọpọ ọdun, eyii to pada gba ẹsẹ rẹ mejeji ti ohun rẹ.

Wọn ge ẹsẹ iya rẹ nitori arun naa.

Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni Sir Keir wa to ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour.

Sir Keir as a student
Àkọlé àwòrán, Sir Keir lasiko to wa ni fasiti

Sir Keir ni ẹni akọkọ ninu idile rẹ ti yoo lọ si fasiti, o kẹkọọ nipa imọ ofin ni fasiti Leeds ati Oxford, o si ṣiṣẹ gẹgẹ bii ajafẹtọ ọmọniyan fun ọpọ ọdun.

Lasiko rẹ gẹgẹ bii agbẹjọro, o ja fitafita lati fopin si idajọ iku lawọn agbegbe Caribbean ati ilẹ adulawọ.

Lọdun 2008, Sir Keir di olori gbogbo awọn agbẹjọrọ ni England ati Whales, o si wa ni ipo naa titi di ọdun 2013 ki ijọba ilẹ Gẹẹsi to fi jẹ oye Kight lọdun 2014.

Sir Keir being knighted in 2014

Oríṣun àwòrán, PA Media

Sir Keir gẹgẹ bii adari ẹgbẹ labour

Ọdun 2015 ni Kier di ero ile igbimọ aṣofin gẹgẹ bii aṣoju agbegbe Holborn ati St Pancras niluu London.

Lọdun naa lọhun, ẹgbẹ alatako ni Labour labẹ adari rẹ, Jeremy Corbyn.

Corbyn fi Keir si ipo lati maa ṣe ofintoto iṣẹ ti ijọba igba naa n ṣe.

Sir Keir Starmer and Jeremy Corbyn in 2019

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Sir Keir lo di olori ẹgbẹ Labour ilkẹ Gẹẹsi lẹyin Jeremy Corbyn

Lẹyin ti ijọba UK dibo lati fi ẹgbẹ EU silẹ, Sir Keir di akọwe Brexit.

Lọdun 2019, ẹgbẹ Labour lulẹ ninu eto idibo gbogbogbo ti ijakulẹ naa si jẹ eyii to buru julọ lati ọdun 1935, eyii to mu ki Jeremy Corbyn kọwe fi ipo silẹ ti Kier si bọ sipo rẹ.

Ki ni awọn ohun ti Sir Keir fẹ sẹ?

Aato ilu

O ti ṣeleri pe ohun yoo da gbogbo ileeṣẹ ọkọ oju irin pada sọdọ ijọba labẹ ileesẹ Great British Railways.

Eto ẹkọ

Ṣaaju lo ti kọkọ sọ pe awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ko ni maa san owo ile ẹkọ mọ, ṣugbọn o ti ni ko ni ri bẹẹ mọ bayii latari pe ọwọ ijọba ko ni ka.

Ṣugbọn o ti sọ pe awọn ile ẹkọ aladani yoo bẹrẹ si n san afikun owo ori fun ijọba.

Sir Keir and his wife Victoria wave from a party conference stage

Eto awujọ

Sir Keir ni ijọba yoo na owo ti iye rẹ to £8bn si ẹka eto ohun amuṣagbara labẹ ileeṣẹ GB Energy.

Israel ati Gaza

Keir ṣatilẹyin fun bi ilẹ Gẹẹsi ṣe n gbe lẹyin Gaza amọ o ti ke si igun mejeji ki wọn dawọ ogun duro.

O tun fọwọ si bi ijọba ilẹ Gẹẹsi ṣe n sọ ado oloro si agọ awọn ọmọ ogun Houthi ni Yemen.

Ilẹ Europe

Keir ni ilẹ Gẹẹsi ko ni pada si ajọ EU mọ.