Spain júwe ilé fún Germany, Portugal ko àgbákò lọ́wọ́ France

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ija di ija alagbara nla meji lana nigba ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Spain pẹlu Germany ati France pẹlu Portugal wọ iya ija fun wakati meji gbako ninu ifẹsẹwọnsẹ ipinle ikọ orilẹede mejọ nibi idije Euro 2024 to waye lọwọ ni orilẹede Germany.

France ati Portugal naa natan bi owo, bo ti lẹ jẹ pe France pada bo ẹgba sidi Portugal ni paapa iṣere to waye ni Hamburg.

Ọpọ awọn ololufẹ Christiano Ronaldo to jẹ agbabọọlu fun Portugal ni wọn ri ijakulẹ lẹyin ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede France ti Kylian Mbappe n gba bọọlu fun jawe olubori lẹyin Pẹnariti.

Ronaldo gba pẹnariti rẹ wọle sugbọn Joao Felix, agbabọọlu alayalo fun Barcelona kọ lati gba bọọlu rẹ wọle.

Saaju ki ifẹsẹwọnsẹ France ati Portugal to bẹrẹ ni ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ti ya sọtọ, ti awọn kan si wa lẹyin , atamatase agbabọọlu Portugal, Cristiano Ronaldo ati Kylian Mbappe to jẹ gbajumọ fun ẹgbẹ agbabọọlu France.

Ifẹsẹwọnsẹ naa wọ pẹnariti, ri France si moke lẹyin ti Joao Felix kọ lati gba pẹnariti rẹ wọle.

Idije yii ni idije kẹyin Euro ti Ronaldo, ẹni ọdun mọkandinlogoji yoo kopa ninu.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ Spain ati Germany, Mikel Merino lo gbo ewuro soju orilẹede to gba alejo idije naa, Germany.

Germany ro pe ifẹsẹwọnsẹ naa yoo wọ pẹnariti sugbọn Merino gba ẹyin gba ẹbọ jẹ fun Germany, to si fọwọ osi juwe ile fun wọn.

Eyi tumọ si pe ikọ orilẹede France ati Spain ni yoo wọ iyaja ni ipele Semi- Final idije Euro 2024.