‘Kò sí nǹkan tí Tinubu fẹ́ jẹ lérè lórí ìdàrúdàpọ̀ oyè Emir ìlú Kano, ààrín òun àti Emir Muhammadu Sanusi II gún régé’

Emir Sanusi, Aarẹ Tinubu ati Emir Aminu Kano

Oríṣun àwòrán, IG/Sanusilamido Sanusi/others

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ti fi esi si ọrọ ti aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu NNPP, Ọmọwe Hashim Dungurawa sọ pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu lọwọ si rukerudo to n waye lori ọrọ oye Emir ilu Kano to n ja ranyinranyin lati bi oṣu melokan bayii laarin Aminu Ado Bayero ati Muhammadu Sanusi keji.

Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun aarẹ Tinubu, Abdu’aziz Abdu’aziz to fesi si ọrọ naa ṣalaye pe igun mejeeji ti ọrọ naa kan ni Aarẹ Tinubu ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu, “paapaajulọ Muhammadu Sanusi II”.

Ọgbẹni Abdu’aziz Abdu’aziz ni ẹsun ti aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu NNPP naa fi kan aarẹ lasiko to ba BBC Hausa sọrọ ninu ifọrọwerọ kan “ko lẹsẹ nlẹ rara”.

“ohun ti ẹni to sọrọ naa ko mọ tabi to mọọmọ maa fẹ sọ nitori abosi oṣelu ni pe ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin aarẹ ati igun mejeeji to n ja ti itẹ Emir yii”.

O ni lati igba ti Sanusi Lamido Sanusi II ti kọkọ du ipo naa lọdun 2014 ni oun ati aarẹ ti jumọ jọ n ni ajọṣepọ to dan mọran bọ. O fi kun un pe ko si igba kan ti Emir ti ijọba ipinlẹ Kano yọ nipo, Aminu Ado Bayero wa ba aarẹ ni ile Aarẹ Naijiria lati igba to ti de ipo.

“Ṣugbọn Emir Sanusi II ti wa ju ẹẹkan lọ lati ri aarẹ. Eyi fi irufẹ ajọṣepọ to wa laarin wọn han. O jẹ ohun to ku diẹ kaato pe eeyan kan yoo wa jade sita lati sọ nnkan ti ko ni ẹri to daju nipa rẹ.”

Laipẹ yii itahunsiraẹni waye laarin ileeṣẹ aarẹBọla Tinubu ati oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu NNPP, to ti figbakanri jẹ gomina ipinlẹ Kano, Sẹnetọ rabiu Kwankwaso lori ẹsun ti Kwankwaso fi kan ijọba Aarẹ Tinubu pe o n gbe igbesẹ lati da ijọba pajawiri silẹ ni ipinlẹ Kano.

Lasiko ifinijoye rẹ to waye, Kwankwaso sọ pe “awọn eeyan kan n lẹdi apo pọ mọ awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC lati pamọ si abẹ wahala ọrọ oye Emir to n waye naa lati da wahala silẹ” ni ipinlẹ Kano.

Amọṣa ileeṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu awọn ẹsun ti Kwankwaso fi kan an naa, leyi ti wọn tọka si gẹgẹbi ọrọ alufansa ti ko lẹsẹ nlẹ rara

Ṣé lóòtọ́ ni pé Tinubu lọ́wọ́ nínú wàhálà oyè Emir nílùú Kano nítorí ìyà Ado Bayero?
 Konkwaso

Oríṣun àwòrán, others

Alaga ẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Kano, Hashimu Dungurawa, ti fẹsun kan Aarẹ Bola Tinubu pe oun lo n da wahala silẹ laarin Muhammadu Sanusi Keji ati Aminu Ado Bayero nipinlẹ Kano.

Ọjọgbọn Hashimu lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC, nibi to ti sọ pe oun ni ẹri maa jẹ mi rinṣo lati kin ọrọ oun lẹyin.

O ni “O han gbagba pe Aarẹ lọwọ ninu ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ.

“Tinubu, latari ibaṣepọ rẹ pẹlu iya to bi Emir ana, iyẹn Aminu Ado Bayero, sọ pe oun ko ni gba ayafi ti wọn ba da pada sipo to wa tẹlẹ.

“Wọn ko awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun wa siluu Kano lasiko naa ti Naijiria n koju iṣoro eto abo, eyii ko si ṣẹyin erongba rẹ lati gbogun ti awọn ti ko ṣatilẹyin fun.”

Nigba ti BBC bere lọwọ adari ẹgbẹ NNPP naa boya o ni ẹri lati kin ọrọ rẹ lẹyin, o ni “Ta ni Aarẹ Naijiria lọwọ yii? Ṣe ki n ṣe Tinubu ni? Njẹ o ṣeeṣe ki wọn ko ọlọpaa ati ọmọ ogun lọ si agbegbe kan fun ọpọlọpọ oṣu ki Aarẹ ma mọ nipa rẹ? To ba sọ pe oun ko mọ, a jẹ pe wahala wa nigbayẹn.”

Ki ni ọọfisi Aarẹ sọ?

BBC kan si ọọfisi Aarẹ lori ẹsun ti alaga NNPP fi kan an, ọkan lara awọn agbẹnusọ Aarẹ, Malam Abdu'aziz Abdul'aziz, kọ lati da si ọrọ ọhun.

Ti ẹ ko ba bagbe, ẹnu ọjọ mẹta yii ni ọọfisi Aarẹ ati oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NNPP tẹlẹ, to tun ti fi akoko igba kan jẹ gomina ipinlẹ Kano ri, Rabi'u Musa Konkwaso, n sọko ọrọ si ara wọn lori ohun to n ṣẹlẹ ni Kano.

Kwankwaso sọ pe awọn kan n ṣisẹ papọ pẹlu awọn adari APC lati da wahala silẹ ni Kano.

Amọ ṣa ọọfisi Aarẹ ti dahun pe ọrọ ti Kwankwaso sọ naa ko lẹsẹ nilẹ ati pe ko si sootọ kankan ninu rẹ.