Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àwọn eré bọ́ọ̀lù tó ti wáyé sẹ́yìn láàrin Nàìjíríà àti Benin Republic

Aworan Super Eagles

Oríṣun àwòrán, ng_supereagles/Instagram

Lẹyin ti ikọ Super Eagles Naijiria ta ọmi 1-1 pẹlu South Africa lọsẹ to kọja, Super Eagles yoo tun maa waako pẹlu ikọ agbabọọlu Benin Republic ni irọlẹ oni ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026.

Ọpọ ololufẹ ere bọọlu ni Naijiria lo koro oju si bi ikọ Super Eagles ṣe ta ọmi pẹlu Bafana Bafana South Africa ni papa iṣere Godswill Akpabio niluu Uyo nipinlẹ Akwa Ibom.

Ọpọ lo bu ẹnu ẹtẹ lu akọnimọọgba Super Eagles, Finidi George lori awọn agbabọọlu kan to lo ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ẹwẹ, Gernot Rohr to jẹ olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Benin Republic lo tun jẹ akọnimọọgba Naijiria tẹlẹ ki Jose Peseiro to rọpo rẹ.

Eyi gan an lo jẹ ki ọpọ eeyan maa sọ pe ifẹsẹwọnsẹ naa maa ṣoro fun Naijiria lati jawe olubori ninu rẹ.

Ipo wo ni Naijiria wa lori tabili ati pegede fun Ife Ẹyẹ Agbaye 2026?

Lẹyin ti ikọ Super Eagles Naijiria ta ọmi ninu gbogbo ifẹṣẹwọnsẹ mẹta ti wọn ti gba, ipo karun un ni Naijiria wa ninu ikọ agbabọọlu mẹfa to wa lori tabili idije ati pegede fun ife ẹyẹ agbaye 2026.

Awọn ikọ agbabọọlu Lesotho, Zimbabwe ati South Africa lawọn orilẹede mẹta ti Naijiria ta ọmi pẹlu wọn.

Ami ayo mẹta pere naa si ni Naijiria ni lẹyin ọmi mẹta ti wọn ta.

Benin Republic, ẹwẹ, wa ni ipo kẹta lori tabili pẹlu ami ayo mẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn ti gba.

Benin Republic fidirẹmi nile South Africa pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kọkọ gba, ki wọn to ta ọmi 0-0 pẹlu Lesotho.

Lẹyin naa ni wọn gbo ewuro soju ikọ agbabọọlu Rwanda.

Aworan tabili ere bọọlu

Oríṣun àwòrán, BBC Sports

Bi awọn ifẹsẹwọnsẹ to ti waye laarin Naijiria ati Benin Republic ṣe lọ ree

Ikọ agbabọọlu Naijiria lo jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin to kẹyin ti wọn gba pẹlu Benin Republic.

Igba ti Benin Republic lu Naijiria kẹyin ni ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije Afcon 2017.

Pẹnariti ti Seibou Mama gba sawọn Naijiria nigba ti o ku iṣẹju kan ki ere bọọlu naa pari ni Benin Republic fi fagba han Naijiria.

Ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlogun lo ti waye sẹyin laarin Naijiria ati Benin Republic.

Naijiria jawe olubori ninu mẹtala ninu awọn ere bọọlu ọhun.

Ẹyọkan ṣoṣo ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ yii ni Benin Republic ti jawe olubori, nigba tawọn mejeeji ta ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ meji.

Akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Naijiria ati Benin Republic sọrọ

Gernot Rohr to jẹ olukọni ikọ agbabọọlu Benin Republic sọ pe ikọ Super Eagles naa ni ikọ agbabọọlu to lamilaaka lati jawe olubori laarin ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ninu ifẹsẹwọnsẹ irọlẹ oni.

Rohr sọ pe Benin Republic ko lorukọ bi Naijiria lagbo ere bọọlu, amọ, o ni awọn yoo gbiyanju lati jawe olubori ninu ere bọọlu ọhun.

Rohr fikun ọrọ rẹ pe ere bọọlu yii yoo tun foun lanfani lati ri awọn agbabọọlu Naijiria ti wọn ti wa labẹ oun tẹlẹ ri.

Finidi George to jẹ akọnimọọgba Naijiria naa sọ pe awọn agbabọọlu Naijiria yoo karamọ ere bọọlu naa.

O ni ifẹsẹwọnsẹ pẹlu South Africa ti di afisẹyin ti eegun n fi aṣọ bayii tori awọn ti kọ ẹkọ nibẹ.

Finidi ni awọn agbabọọlu Naijiria fẹ lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026, wọn ṣi ti ṣetan lati lo gbogbo agbara wọn lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Benin Republic ti yoo waye lorilẹede Ivory Coast.