Àwọn darandaran kọlù ikọ̀ Amotekun l'Ondo, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn

Aworan ikọ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun

Awọn ikọ Amotekun ti a ko ti mo iye wọn ni wọn n gba itọju lọwọ ni ile iwosan leyin ti ija bẹ silẹ laarin wọn ati awọn darandaran ni agbagbe Igoba ni opopona Ado-Ekiti n'ilu Akure.

Ohun to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe awọn darandaran yi se ikọlu naa lasiko ti awọn ikọ Amotekun lọ se iṣẹ wọn nipa ofin ti ijọba gbe kalẹ eyi ti ko fi aye gba kiko ẹran jẹ kakiri aarin ilu.

Ofin yi ni Gomina ana, oloogbe Oluwarotimi Akeredolu bọwọ lu lọjọ kọkan-le-logun oṣu kẹjọ ọdun 2021 lati le fopin si aawọ to ma n waye laaarin awọn darandaran ati awọn agbe nipinlẹ Ondo.

Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?

Lasiko to n salaye bi iṣẹlẹ naa se waye, Alukoro ajọ Amotekun l'Ondo Jimoh Adeniken ninu atejade kan to fi lede, o salaye pe ọpọlọpọ awọn ọmọ Amotekun lo farapa kọja ala ti wọn si n gba itọju nile Iwosan.

Ninu ọrọ rẹ Alukoro naa salaye pe "Nitori oniruru ẹsun lati ọwọ awọn agbe to wa lagbegbe Igoba ati ilu Osi lati ọjọ kẹfa osu karun un ọdun yi titi di asiko yi, Ajọ wa lati olu ileeṣẹ wa to wa ni Alagbaka n'ilu Akure bọ soju isẹ lọjọ karun osu kẹfa ni deedee ago mẹrin irọlẹ.

"Lasiko isẹ naa awọn agbe yii saaju awọn ikọ wa lọ oko wọn. Ni kete ti a de bẹ a ba Maalu to le ni ọgọfa ti wọn n jẹ oko awọn agbe naa ti ko si si ẹni to n dari awọn ẹran yi pẹlu wọn.

Aworan ọkan lara ọmọ ogun Amoyekun to farapa

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

"Àwọn ikọ Àmọ̀tẹ́kùn le awọn Maalu yi kuro ninu oko lati se imuṣẹ ofin ijọba to tako ki ko ẹran jẹ laarin ilu. Sugbọn ni kete ti a n gba agbegbe Sango ni Igoba awọn Fulani darandaran pẹlu ihamora se ikọlu si awọn ikọ wa pẹlu okuta, igo, ada, ati ibọn.

"Lẹyin eyi ni a koju wọn ni ibamu pẹlu aṣẹ latoke, sibẹ awọn Fulani yi tẹsiwaju ninu ikọlu wọn ti wọn si lu ọkan ninu awọn ikọ Amotekun titi to fi wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

“O jẹ ohun to ba ni ninu jẹ pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ogun wa farapa ninu ikọlu yii ti wọn si ti n gba itọju.

Alukoro naa sọ di mimọ pe wọn ti da ẹni to ni awọn ẹran naa mọ, ti wọn si ti bẹrẹ iwadi to muna doko lori rẹ.

Adeniken seleri pe Ajọ naa yoo tẹsiwaju lati ma ṣe imuṣẹ awọn ofin ijọba lai gbọjẹgẹ, pẹlu idaniloju pe wọn yoo ma ṣe isẹ wọn ki alaafia le tubọ maa jọba nipinlẹ Ondo.