Wo ìlú tí àwọn kan ti ń pa ìrọ́ mọ́ àwọn arúgbó pé àjẹ́ ni wọ́n láti dọ́gbọ́n gba ilẹ̀ wọn

Àkọlé fídíò, Wo ìlú tí àwọn kan ti ń pa ìrọ́ mọ́ àwọn arúgbó pé àjẹ́ ni wọ́n láti dọ́gbọ́n gba ilẹ̀ wọn
  • Author, Njeri Mwangi in Kilifi county & Tamasin Ford in London
  • Role, BBC Africa Eye

Ikọ oluwadii BBC Africa Eye ti ṣe iwadii lori iṣẹlẹ awọn agbalagba kan tawọn eeyan n fẹsun kan pe wọn ni ajẹ lagbegbe odo Kilifi lorilẹede Kenya.

Africa Eye ṣawari ohun to fa a ti wọn fi n ṣeku pa awọn eeyan yii.

Ẹni ọdun merinlelaadọrin ni Tambala Jefwa i ṣe.

Oju kan loku ti Jefwa fi n riran.

Sidi to jẹ iyawo rẹ ṣalaye pe wọn gun un lọbẹ, bakan naa tun ni iyawo rẹ tun na ika si apa to wa lara Jefwa.

Sidi ni wọn ni lati ran ori Jefwa ni leyin tawọn kan ṣe ikọlu si i.

Wọn fẹsun kan Jefwa pe o lajẹẹ, emeji ọtọtọ ni wọn ṣi ṣe ikọlu si i.

O padanu oju rẹ kan nibi ikọlu akọkọ, o ṣi fẹẹ ba ikọlu ẹlẹẹkeji lọ.

Awọn tọkọtaya yii ni oko agbado to pọ, bakan naa ni wọn tun ni adiẹ.

Ija ti wa laarin wọn at'awọn ẹbi wọn lori ọrọ ilẹ aala.

Wọn gbagbọ pe eyi gan an nidi ti wọn fi fẹ ẹ pa a, kii ṣe pe o ni ajẹ.

"Wọn fi mí silẹ ki n le baa ki, ọpọ ẹjẹ mi lo ṣofo.

Mi o mọ idi ti wọn fi lu mi, amọ, mo mọ pe ko le ju ọrọ ilẹ lọ," Jefwa lo sọ bẹẹ.

Sidi Jefwa ṣafihan apa lara ọkọ rẹ lẹyin ti wọn lu u.
Àkọlé àwòrán, Sidi Jefwa ṣafihan apa lara ọkọ rẹ lẹyin ti wọn lu u.

Ọpọ eeyan l'awọn orilẹede kan lo gbagbọ wi pe ajẹ wa.

Koda, l'awọn apa kan lorilẹede Kenya, Malawi, Tanzania ati South Africa, wọn maa n lo eyi lati ṣeku pa awọn agbalagba ti wọn yoo si gba ilẹ wọn.

Iroyin kan ti ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, Haki Yetu gbe sita sọ pe ọsọọsẹ l'awọn eeyan kan n ṣeku pa agbalagba kan lẹba odo Kilifi lẹyin ti wọn ba fẹsun kan wọn pe wọn ni ajẹ.

Julius Wanyama toun naa n ṣiṣẹ pẹlu ajọ to ajafẹtọọ ọmọniyan sọ pe ọkan lara awọn ẹbi lo maa n paṣẹ pe ki wọn pa iru ẹni bẹẹ.

Ọpọ awọn eeyan yii ni kii ṣe iwe ipin ogun silẹ ki wọn to ku.

Ẹnu ni wọn maa fi saba fi ilẹ wọn silẹ ti wọn ba ti fẹ ku.

Wanyama ni meje ninu mẹwaa awọn eeyan ti wọn n pa yii lo jẹ agbalagba tori ọpọ ninu wọn lo ni ilẹ ati dukia.

Wanyama sọ pe "o iwa iṣekupani yii wọpọ ni Kilifi lorilẹede Kenya.

Wọn ko ni iwe kankan fun ile wọn.

Idi niyi ti wọn n ṣeku pa awọn agbalagba ki wọn ba le gba ilẹ wọn."

Jefwas gbagbọ pe awọn ẹbi oun lo se ikọlu si oun
Àkọlé àwòrán, Jefwas gbagbọ pe awọn ẹbi oun lo se ikọlu si oun

Ibudo kan ti ẹgbẹ alaanu kan , Malindi District Association gbe kalẹ fun idoola awọn agbalagba ko ju irin-ajo wakati kan pẹlu ọkọ lọ sile Jefwa.

O to ọgbọn awọn agbalagba ti wọn ti ṣe ikọlu si ti wọn ko si le pada si ori ilẹ wọn mọ to wa nibẹ.

Katana Chara, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, ti wa ni ibudo naa fun ọdun kan.

Chara dero ibudo yii lẹyin ti wọn ṣa a lada ni yara ibusun rẹ loṣu Kẹrin ọdun 2023.

Wọn ge ọwọ rẹ mejeeji, ko si le ṣíṣẹ́ kankan mọ.

Koda, o nilo iranwọ lati jẹun ati lati mura gan an.

Chara ni oun mọ ẹni to ge ọwọ oun, amọ, o ni oun ko tii ri soju ri.

Wọn fẹsun kan an pe ajẹ ni, wi pe oun lo pa ọmọ ẹnikan.

Chara ni oun gbagbọ pe tori ilẹ oun ni wọn fi ṣe ikọlu soun

"Mo ni nkan ṣe pẹlu awọn ajẹ.

Amọ, mo ni ilẹ to tobi gan an lẹba odo," Chara ṣalaye.

Aworan okunrin ti wọn ge ọwọ rẹ mejeeji
Àkọlé àwòrán, Ninu aba kan ni Katana Chara n gbe bayii

Wọn ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn ẹbi Chara, amọ, ko si ẹni to foju ba ile ẹjọ ninu wọn.

Ajafẹtọọ Wanyama lo n gbiyanju lati ja fun un.

Awọn eeyan diẹ lo ti foju ba ile ẹjọ lori ẹsun isekupa awọn agbalagba.

BBC Africa Eye ṣawari ọkunrin kan to ni oun ti ṣeku pa ogun eeyan.

O ṣalaye pe $400 loun gba fun iṣekupani ẹnikọọkan toun pa.

O ni "ti iṣekupani kan ba waye, mo fẹ ki ẹ mọ pe ẹbi ẹni ti wọn pa lo sanwo ẹmi rẹ.

Wọn gbe iṣẹ fun mi ni, mo ṣi ṣiṣẹ naa.

Emi kọ ni mo payan bi ko ṣe ẹni to ran mi niṣẹ."

Ajọ to n ri si ọrọ ẹtọ ọmọniyan ni Kenya ṣe agbekalẹ iwe apilẹkọ kan loṣu Keji ọdun 2023 wi pe didana sun ajẹ, iṣekupani ati ikọlu s'awọn eeyan wọpọ l'awọn ẹkun bii Kisii lapa iwo-oorun Kenya ati ẹkun Kilifi ni Kenya.

Iwe naa sọ pe awọn ẹbi maa n fẹ gba ilẹ ni wọn fi seku pa awọn agbalagba.

Wanyama ni iṣẹlẹ iṣekupani to n waye pẹlu b'awọn eeyan ṣe n pe awọn agbalagba ni ajẹ lati gba ilẹ wọn ti di adanu to ṣẹlẹ kaakiri Kenya.

Nilẹ Afirika, awọn eeyan maa n bọwọ fun àwon agbalagba tori wọn maa n ni ọgbọn ati imọ.

Ni ẹkun Kilifi, awọn agbalagba maa n kun irun won lati le dabi ọmọde tori ẹru n b'awọn ki wọn maa ba ṣeku pa wọn.

O nira ki ẹni ti wọn ba fẹsun kan pe o ni ajẹ ni ẹkun yii lati le ru u la.

Nigba ti Chara n gbe ni ibudo ti ẹgbẹ alaanu pese fawon agbalagba, ẹru si n ba awọn okunrin bii Jefwa pe awọn to fẹ pa wọn le pada wa.