Ayàwòrán tó dáná sun fọ́to Ààrẹ gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méji

Shadrack Chaula

Oríṣun àwòrán, Mwananchi

Ọkunrin ayaworan kan, Shadrack Chaula, ni kootu ti ran lẹwọn ọdun meji bayii pẹlu bi fidio ibi to ti bu aarẹ orilẹede rẹ, to si tun n dana sun fọto aarẹ ọhun ṣe kari ayelujara.

Orilẹede Tanzania ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, Aarẹ Samia Suluhu Hassan si ni ẹni naa ti Shadrack tori ẹ ri ẹwọn he.

Ọjọbọ, ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2024 yii ni Adajọ Shamla Shehagilo, paṣẹ ẹwọn ọdun meji fun olujẹjọ naa.

Ayaworan ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) yii ko jiyan ni kootu, o loun huwa naa loootọ, ko si sọ awijare kankan lati gba ara rẹ silẹ nigba ti wọn ni ko rojọ.

Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ fi aaye owo itanran silẹ fun un, eyi ti i ṣe ẹgbẹrun meji dọla bi ko ba fẹẹ lọ si ẹwọn, ṣugbọn ẹwọn ni ayaworan naa balẹ si.

Ohun to ṣẹlẹ yii ti mu kawọn eeyan kan maa lodi si aṣẹ kootu lorilẹede naa, wọn ni jijo fọto aarẹ nina ki i ṣe iwa ọdaran rara.

Bakan naa ni awọn eeyan kan loju opo ayelujara ti bẹrẹ si i dawo lati gba a kuro lẹwọn.

Lọdun 2018 ni Tanzania ṣe ofin kan to n gbogun ti gbigbe iroyin ofege jade, ṣugbọn awọn kan sọ pe wọn ṣe bẹẹ lati pa ẹnu araalu mọ ni.

Awijare awọn ọlọpaa lorii ti Shadrack yii ni pe o sọ awọn ọrọ to lagbara tako Aarẹ Samia Suluhu Hassan.

Wọn ni o lo ẹka ayelujara TikTok lati gbe ọrọ atako naa jade ni ọgbọnjọ, oṣu kẹfa ọdun 2024, ni Abule Ntokele, Guusu Iwọ oorun Mbeya, lorilẹede Tanzania.

Kò sí nínú àṣà wa láti máa bú àwọn olórí wa

Aarẹ Samia Suluhu Hassan

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Samia Suluhu Hassan

Ọlọpaa ibilẹ kan, Benjamin Kuzaga, sọ fun awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun pe, "ki i ṣe aṣa awa eeyan Mbeya lati maa bu awọn olori wa’’

O ni ẹṣẹ ti ayaworan naa ṣẹ ni pe o sọrọ abuku si aarẹ, o tun waa n pin in ka lori ayelujara.

Ṣugbọn amofin kan,Philip Mwakilima, sọ fun iwe iroyin ibilẹ, Mwananchi , pe ko sẹni to le fidi ẹ mulẹ pe iwa ọdaran ni lati jo fọto nina.

‘’Ṣe ayaworan tijọba n sanwo fun lo ya fọto naa ni? Ẹ jẹ ki wọn jade waa sọ ipa wọn lori awujọ ati orilẹede.’’

Bẹẹ ni lọọya to tako igbesẹ kootu naa wi.

Ọdun 2021 ni Aarẹ Samia Suluhu Hassan gori aleefa ni Tanzania, o ṣe awọn ofin kan lẹka oṣelu ati awujọ.

Ṣugbọn awọn alatako lodi si eyi, wọn ni ofin adanipada-sẹyin ni iya naa n ṣe kiri.