Wo ìdí tí àwọn agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀èdè tó bá kópa ní ìdíje Afcon lọ́dún 2025 kò fi ní ṣe kérésimesì àti ọdún tuntun pẹ̀lú ẹbí wọn

Aworan ife ẹyẹ AFCON

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ CAF to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Afirika ti kede ọjọ ti idije ere bọọlu AFCON 2025 yoo bẹrẹ.

Aarẹ ajọ CAF, Patrice Motsepe ti kede wi pe ọjọ kọkanlelogun oṣu Kejila ọdun 2025 to n bọ ni idije naa yoo bẹrẹ lorilẹede Morocco.

Motsepe ni idije ere bọọlu naa yoo pari lọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun 2026.

Motsepe fi ọrọ yii lede loju opo itakun ayelujara CAF ati loju opo X ati Facebook ajọ naa pẹlu.

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ajọ CAF ni ‘’o dami loju pe idije AFCON 2025 yoo yọri si rere, ati wi pe ohun ni yoo jẹ idije AFCON to dara julọ ninu itan idije naa.’’

Ṣaaju ni igbimọ alaṣẹ CAF ṣe ipade wọn ni olu ileeṣẹ ajọ naa to wa niluu Cairo lorilẹede Egypt ki Motsepe to kede ọjọ ti idije naa yoo bẹrẹ.

Oṣu Kẹfa si Ikeje ọdun 2025 ni CAF ti kọkọ sọ tẹlẹ pe idije naa yoo waye tẹlẹ ki wọn to sun un ṣiwaju.

Asiko yii ni ajọ CAF woye pe idije naa ko ba tako idije UEFA Champions League tori ọpọ agbabọọlu ọmọ ilẹ Afirika ni yoo maa ṣoju awọn ẹgbẹ agbabọọlu wọn ni Yuroopu nigba naa.

Amọ, ọpọ lo gbagbọ wi pe idije AFCON 2025 ti yoo waye loṣu Kejila ọdun 2025 si oṣu Kinni ọdun 2026 yoo ṣe ipalara fun ọpọ awọn ikọ agbabọọlu Premier League.

Awọn ileeṣẹ iroyin kan nilẹ Gẹẹsi ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ẹgbẹ agbabọọlu ma fawọn agbabọọlu ilẹ Afirika to n gba bọọlu fun wọn laye lati lọ fun idije naa.

Idi ni pe idije ere bọọlu kan ni ajọ FIFA to n ṣakoso ere bọọlu lagbaaye fọwọ si pe kawọn ẹgbẹ agbabọọlu maa fawọn agbabọọlu laye lati kopa ninu rẹ laarin ọdun kan.

Ọdun 2026 yii kan naa ni idije ife ẹyẹ ere bọọlu lagbaaye yoo waye.

Amọ, ajọ CAF le sọ pe idije AFCON 2025 ni idije naa, bo tilẹ jẹ pe lọdun 2026 ni ọpọ ere bọọlu idije naa yoo waye.

Ajọ CAF ti sun idije ere bọọlu awọn obinrin WAFCON 2024 naa si 2025

Ẹwẹ, ajọ CAF ti sun idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Afirika naa WAFCON 2024 si ọdun 2025.

Idije WAFCON 2024 yoo bẹrẹ lọjọ karun un oṣu Keje ọdun 2025 lorilẹede Morocco bakan naa.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje yii kan naa ni idije ọhun yoo pari ni Morocco.

Ni bayii, ajọ CAF tun ni lati kede ọjọ tuntun ti idije ere bọọlu CHAN yoo bẹrẹ.

Orilẹede Kenya, Tanzania ati Uganda ni CAF ti kọkọ kede pe wọn a gbalejo idije naa tẹlẹ.