Wo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ti fí orúkọ sílẹ̀ fún ẹ̀yáwò tí ìjọba gbé kalẹ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́

Aworan ẹnu ọna abawole fasiti ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹka ijọba orilẹede Naijiria to n risi ẹyawo fun eto ẹkọ Nelfund ti kede sita pe ile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba ipinlẹ mẹrindinlogoji lo ti fọrukọ silẹ fun ẹyawo ti ijọba apapọ gbe kalẹ fun awọn akẹkọọ.

Ninu atẹjade kan ti Nelfund fi sọwọ sori ayelujara ni ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu keje sọ pe awọn akẹkọọ ti ni anfani bayii lati bẹrẹ si ni forukọ fun ẹyawo naa.

Nelfund ni inu awọn dun lati gbe ikede naa sita fun awọn akẹkọọ lati jẹ anfani.

“Inu wa dun lati kede sita pe awọn ile ẹkọ giga ile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba ipinlẹ mẹrindinlogoji, ti awọn akẹkọọ si ti ni anfani lati bẹrẹ si ni forukọ silẹ bẹrẹ lati ọjọ keje oṣu keje ọdun 2024.

“Awọn ile ẹkọ yii ti fi orukọ awọn akẹkọọ silẹ. A n rọ awọn ile ẹkọ giga yooku lati wa forukọ silẹ lati le fun awọn akẹkọọ ni anfani lati jẹ anfani ẹyawo naa.”

Awọn ile ẹkọ giga to forukọ silẹ

1. Adamawa State University, Mubi

2. Ramat Polytechnic, Maiduguri

3. Borno State University

4. Mohammet Lawan college of Agriculture, Borno State

5. Edo State University, Uzairue

6. Ekiti State University, Ado-Ekiti

7. Gombe State University

8. Kingsley Ozumba Mbadiwe University, Imo State

9. Imo State University of Agriculture and Environmental Sciences Umuagwo

10. Nuhu Bamalli Polytechnic, Zaria

11. Yusuf Maitama Sule University, Kano

12. Umaru Musa Yar’adua University, Katsina

13. Katsina State Institute of Technology and Management

14. Kebbi State University of Science and Technology, Aliero

15. Confluence University of Science and Technology, Kogi state

16. Lagos state university of education

17. Lagos State University

18. Nasarawa State University, Keffi

19. Tai Solarin University of Education, Ogun state

20. University of Medical Sciences, Ondo

21. Osun State University

22. UNIVERSITY OF ILESA, OSUN STATE

23. GTC, ARA Osun State

24. GTC, GBONGAN Osun State

25. GTC, IJEBU-JESA Osun State

26. GTC, ILE-IFE Osun State

27. GTC, INISA Osun State

28. GTC, IWO Osun State

29. GTC,OSU Osun State

30. GTC, OTAN AYEGBAJU Osun State

31. OSUN STATE COLLEGE OF EDUCATION, ILA-ORANGUN

32. GOVERNMENT TECHNICAL COLLEGE ILE-IFE

33. OSUN STATE COLLEGE OF TECHNOLOGY

34. Taraba State University, Jalingo

35. Umar Suleiman College of Education, Gashua, Yobe State

36. Zamfara State University, Talata Mafara