Ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ ní Nàíjíríà, JAMB rí 3000 ayédèrú akékọ̀ọ́ fásitì - Oloyede

Awọn akẹkọọ to n se idanwo JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Ajọ to n ri si igbaniwọle awọn akẹkọọ sileewe giga ni Naijiria, Joint Admissions and Matriculations Board (JAMB), ti sọ pe o le ni ẹgbẹrun mẹta ayederu akẹkọọgboye tawọn ṣawari rẹ bayii.

Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, ọga to n ri si igbaniwọle ni JAMB, sọ pe awọn eeyan naa ko de yunifasiti ri, debi ti wọn yoo tilẹ kẹkọọ yege.

Nibi ipade kan ti Oloyede ṣe pẹlu awọn olori yunifasiti lawọn ipinlẹ Naijiria, Committee of Pro-Chancellors of State Universities (COPSUN), lo ti ṣiṣọ loju ọrọ naa laipẹ yii.

O ni bawọn ti ko mọ nnkan kan ṣe n pe ara wọn ni akẹkọọ gboye, ti wọn si pọ to bayii ko ṣẹyin iwa ibajẹ to ti gbilẹ lawọn ẹka kaakiri orilẹede yii.

Ọga agba ajọ JAMB naa sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori aṣiri to di mimọ naa, bẹẹ ni igbesẹ ti bẹrẹ lori ati dẹkun igbani wọ ileewe giga lọna aitọ.

Ọjọgbọn Oloyede ṣapejuwe aṣiri to tu yii bii ohun to ti ni loju ju ole lọ, to si le ṣe orilẹede yii ni ṣùtá.

Ohun ti eyi n tọka si ni pe akiyesi ati amojuto gbọdọ wa lẹka eto ẹkọ Naijiria, ki otitọ ati iwa ọmọluabi le jẹyọ lara awọn ti wọn ba n kẹkọọ gboye nileewe giga wa.