Wo ìlú kan nílẹ̀ Yorùbá tí wọn kìí fẹ́ obìnrin pupa

Awọn obinrin ẹya Yoruba
  • Author, Afolabi Akinlabi
  • Role, Broadcast Journalist
  • Reporting from Lagos

Awọn eeyan Yoruba jẹ ẹya kan ti kii se ẹlẹyamẹya nidi fifẹ ọkọ ati aya.

Ati ọkunrin tabi obinrin ni kii se awawi nipa awọ ara ẹnikeji wọn, paapaa lasiko ti wọn ba n yan aya atabi ọkọ.

Sugbọn nilẹ Yoruba yii kan naa, ẹya kan wa ni aarin wọn, ti wọn maa n tako fifẹ obinrin to ba ni awọ pupa.

Ilẹ Ugbo ni orukọ ilu naa, to si jẹ ilu nla ni ilẹ Kaarọ ojire, to si wa ni agbegbe ẹsẹ odo nipinlẹ Ondo.

Ọpọ amoye ati onkọtan gbagbọ pe ilu Ile Ife ni awọn Ugbo ti kọkọ bẹrẹ igbe aye wọn, ki wọn to wa ni ibi ti wọn bayii ni ijọba ibilẹ Ilaje ni ipinlẹ Ondo.

Ibeere to si n gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe ki lo de, to se di eewọ fun awọn ọkunrin nilẹ Ugbo lati fẹ obinrin pupa bii aya sile?

Yoruba ni odo kii san, ko ma ni orisun to ti sẹ wa, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu awọn Ugbo yii.

Ko si bi a ṣe fẹ sọrọ nípa ilu Ugbo ati idi to ṣe lodi si fifẹ obinrin pupa, , ti a ko ni sọrọ nípa Moremi Ajasoro ati ilu Ile Ife.

Ajọsepọ wo lo wa laarin Ilu Ugbo ati Ile Ife to fi di pe Ilu Ugbo fofin de awọn ọmọ Ugbo pe wọn ko ni anfani lati fẹ ọmọ pupa gẹgẹ bii iyawo.

Ibeere yii lo mu ki BBC Yoruba kalẹ si aafin Olugbo ti ilu Ugbo, Ọba Obateru Akinruntan lati tan imọlẹ si ọrọ yii.

Bakan naa la tunkan si Ọwọ Ayekere tiluu Ile Ife, Ọba Sunday Oluwagbemileke lati mọ iha ti awọn naa kọ si iṣẹlẹ yii nitori agbọ ẹjọ ẹnikan da, agba osika ni.

Ko tan sibẹ, BBC Yoruba tun fẹ mọ boya lootọ ni eewọ fifẹ obinrin pupa si wa ni ilẹ Ugbo di akoko yii?

"Ajọsepọ to wa laarin Olugbo ati Mọremi lo mu ki ẹya Ugbo mase fẹ awọn obinrin pupa mọ"

Yoruba ni bi ọmọ ko ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan.

Olugbo tilẹ Ugbo, Ọba Frederick Obateru Enitiolorunda Akinruntan salaye fun BBC Yoruba pe ilẹ Ugbo jẹ ara ilẹ Yoruba lapapọ.

Kabiyesi ni akoko kan wa ti ilu Ugbo maa n ko awọn eeyan Ile Ifẹ lẹru, to si nira pupọ fun awọn akọni alagbara ọkunrin ni ilu naa lati gba Ile Ifẹ silẹ lọwọ awọn ọmọ ogun Ugbo, to wa n ko wọn lẹru.

O tẹsiwaju pe Moremi wa lara awọn ẹru ti awọn ọmọ ogun Ugbo ko lasiko ti wọn kọlu ilu Ile Ife ṣugbọn nitori pe o jẹ arẹwa obinrin, o di iyawo Olugbo lasiko naa.

Ọba Akinruntan tẹsiwaju pe "Olugbo ni ọkọ Moremi, to si bi ọmọ kan fun Olugbo.

"Moremi sa kuro ni Ugbo, ọmọ to bí ni wọn si fi rubọ."

Moremi jẹ eeyan to pupa ti pupa rẹ si jẹ eyi ti ko ni abawọn rara, to jẹ pe ko fẹ ẹ si ọkunrin tí ko ni fẹ dẹnu ifẹ kọ Arẹwa naa.

Ni aye atijọ, pupọ awọn obinrin ti wọn ba ko ni ẹru ni wọn maa n fi ṣe aya, tí Moremi naa si di aya Ọba nitori ẹwa rẹ to da yatọ.

Olugbo salaye pe idi ti wọn kii se ẹ ọmọ pupa mọ niluu Ugbo ni nǹkan ṣe pẹ̀lú ajọsepọ to waye laaarin Olugbo igba naa pẹlu Moremi Ajasoro.

"Moremi to dalẹ awa Ugbo jẹ ọmọ pupa, to si tu asiri wa fun Ile Ife, idi ree ti awa Ugbo kii se fẹ obinrin pupa mọ"

Ọba Akinruntan fikun pe "Nnkan ti a kii n fẹ ọmọ pupa niyi, Moremi jẹ Arẹwa obìnrin to lẹwa,

"Kí wọn to mu kuro ni Ifẹ, nnkan to sẹlẹ ni pe ki awọn baba nla wa to kuro ni Ife, ṣe ẹ mọ pe ologun ni wọn, Ife ni wọn ti maa n lọ ko oúnjẹ wa si ilu Ugbo.

"Tí wọn ba dẹ fẹ lọ, gende ọkunrin mẹrindinlogun ni wọn maa ran lọ, ti wọn dẹ ma ko awọn eeyan lẹru ati iyawo ati ọmọ wa si Ugbo

"Ohun tí awọn baba wa n lo lati fi ṣe agbara nigba naa ni wọn ń pe ni Kanako.

"O jẹ ki wọn rìnrinajo to yẹ kí wọn rìn fun oṣu mẹfa ni ọgbọn iṣẹju tabi ogun iṣẹju.

"Ti wọn ba ti lọ, wọn maa ko ẹru ati eeyan bọ. Ife gbiyanju gbogbo agbara wọn lati koju awọn ologun yii sugbọn paabo lo jasi."

Kabiyesi tẹsiwaju pe Moremi wa lara awọn ẹru tí wọn ko wọle si ilu Ugbo, to si di aya fun Olugbo.

O jẹ ko di mimọ pe Moremi lo ọpọlọpọ ọdun niluu naa, to fi di pe o bímọ fun Olugbo lasiko naa.

Nigba ti Moremi di Aya Ọba ní o bẹrẹ si ni ma tọpinpin pe ki lo faa ti awọn ọmọ ogun Ugbo fi lagbara ju tawọn Ile Ife lọ.

"Awọn eeyan wa gba Ife ni amọran pe ki wọn lọ ba Babalawo ni ilu kan to sumọ mọ, pe yoo sọ nnkan ti wọn ma ṣe fun wọn lati gba ara silẹ.

"O wa sọ fun wọn pe ki wọn wa ogunsọ, kí wọn de mọ igi, kí wọn sana si ogunsọ, ohun ni ẹrọ Kanako ti awọn Babanla Ugbo n lo.

Nigba ti awọn babanla n ko ẹru ni wọn ti mu Moremi wa sínu Ugbo, to si bímọ fun wa.

Nigba ti Moremi de ibi, o ri gbogbo nnkan ti wọn n ko sara, to si beere pe ki ni awọn nnkan yii.

"Wọn ni ko dakẹ ẹnu rẹ, ko si wọle lọ."

Moremi Ajasoro pada mọ nípa Kanako to jẹ ohun agbara awọn ọmọ ologun Ugbo to si ni lati sa lọ pada si ile Ife lati lọ jabọ pe oun ti mọ asiri Ugbo.

Lẹyin ti Moremi sọ àṣírí yìí fún àwọn Ile Ife ni Ile Ife bori awọn ọmọ ogun Ugbo.

Eyi lo fa a ti awọn eniyan ilé Ife fi máa ń rí Moremi gẹgẹ bii akikanju obinrin sugbọn ti ilu Ugbo rí gẹgẹ ọdalẹ Obìnrin.

"Nnkan to fa ti a ko ki n fẹ́ obìnrin pupa ree nitori ohun tí Moremi ṣe fun wa.

Ọdale ni Moremi si awọn baba nla wa fi sọ pe a ko gbọdọ fẹ obinrin pupa ojoji gẹgẹ bii iyawo.

Àṣà yii ṣi wa lọwọ bayii niluu Ugbo gẹgẹ bi Kabiyesi Ọba Obateru Akinruntan ṣe salaye.

"Ọmọ pupa pe oríṣi meji, obinrin ti a bi ni alawọ pupa ni ẹya Ugbo kii fẹ, wọn si yatọ si obinrin ti o bora"

Olugbo ti ilu Ugbo, Ọba Obateru Akinruntan jẹ ko di mimọ pe obìnrin pupa pin si ọna meji.

Kabiyesi ni iyatọ wa laarin obinrin ti pupa rẹ ko ni abawọn ati obìnrin to bo ara rẹ.

"Obinrin pupa lai ni abawọn yatọ si awọn obinrin pupa to bo ara wọn

"Pupa ti ko ni abawọn ni a n sọ, kìí ṣe ẹni to bora rara.

"Ọmọ Ugbo le pupa lai ni abawọn, to si le ni ọkọ sugbọn ajoji bi Moremi to pupa ni a n sọ to si jẹ pe awa tí a mọ nípa yii ko ni ba wọn ṣe papọ

"Ọlaju ti de ti ọmọ wa si wa kaakiri ṣugbọn awa ti a wa ni ile, ti a mọ itan yii ko ni fẹ ajoji obinrin to pupa."

Aworan Ere Moremi Ajasoro niluu Ugbo

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba to n salaye fun BBC Yoruba nipa itan aye Moremi Ajasoro, Ọwọ Ayekere tiluu Ile Ife, Ọba Sunday Oluwagbemileke sọ pe ọmọ bibi ilu Ifẹ ni Moremi Ajasoro.

O ni Ile Yekere niluu Ile Ife ni agbegbe Ita Akọgun ni Okerewe, ni agboole Moremi Ajasoro wa.

Bakan naa lo fikun pe Apa kan Ife, apa kan ilu Offa ni Moremi, orukọ baba rẹ si ni Kurunba, ti iya rẹ, Olunbẹ, si jẹ ọmọ bibi ilu Offa.

“Ọdẹ ni baba Moremi ṣe lọ siluu Offa, ni ipinlẹ Kwara lónìí to si pa ọpọ ẹran ninu igbo nibẹ.

"Awọn ara Offa mu pe ki lo de to wa pa ẹran ninu igbo awọn amọ nigba ti wọn ri pe alagbara ẹda ni, wọn ṣe e ni aanu.

"Nigba to n pada sile Ife, wọn fun ni ọmọbinrin kan, Olounbẹ, pe ko fi ṣaya, to si pada bi Moremi Ajasoro.

"Ọmọremi ni apetan orukọ Moremi, Ile Ife ko si le gbagbe rẹ fun iṣẹ takun takun to ṣe.

Ta ni Moremi Ajasoro?

Aworan Ere Moremi Ajasoro niluu Ile Ife

Oríṣun àwòrán, ooniadimulaife/Instagram

Ọrọ nipa itan Moremi jẹ apa meji, bi o ṣe kọju si enikan, lọ kọ ẹyin si ẹlomiran.

Ní ilu ile ife, Moremi Ajasoro jẹ obinrin takuntakun, ti okiki rẹ si kari ile ati oko sugbọn niluu Ugbo, wọn ri Moremi gẹgẹ bii ọdale obinrin to tu asiri ilu naa sọwọ ọta.

Niluu Ile Ife, ọjọ keji ọdun Ọlọjọ ni Ọdun Moremi maa n waye, koda ere Moremi to wa niluu Ile Ife jẹ ọkan to ga ju lorilẹede Naijiria níbi to ti gbe ina dani gẹgẹ akoni obìnrin to gba ilu Ile Ife lọwọ ọta.

Ere Moremi Ajasoro naa wa niluu Ugbo sugbọn eyi yatọ gidi sì eyi to wa niluu Ile Ife.

Ere Moremi to wa ni Aafin Olugbo ti ilu Ugbo lo kunlẹ to si n ra ọwọ ẹbẹ si Olugbo pe ko darin jin oun.

Ni oṣu kẹwaa ọdọọdun ni wọn maa n ṣe ọdun Moremi ni ilu Ugbo àmọ́ niṣe ni wọn maa n na ere rẹ ni ẹgba nitori wọn gbagbọ pe ọdalẹ ni.