Ọmọbìnrin ààrẹ Cameroon fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí àṣepọ̀ abo-sí-abo

Aworan Brenda Biya ati Layyons Valenca ti wọn n fẹnu konu

Oríṣun àwòrán, Brenda Biya/Instagram

Àkọlé àwòrán, Brenda Biya, ọmọ aarẹ Cameroon n fi ẹnu ko Layyons Valenca, arinrinoge ilẹ Brazil lẹnu yii.

Ọmọbinrin aarẹ orilẹede Cameroon, Brenda Biya, ti fi aworan kan sori ayelujara, nibi to ti n fi ẹnu ko obinrin bii tiẹ, Layyons Valenca, lẹnu.

Aworan yii ti mu ki ọpọ eeyan maa fi ero ọkan wọn han nipa iru eeyan ti ọmọ aarẹ Cameroon yii jẹ.

Arinrin oge (model) lorilẹede Brazil ni Layyons Valenca, ti Brenda Biya n fi ẹnu ko lẹnu ninu aworan naa.

Koda, ọmọbinrin aarẹ Cameroon naa tun fi akọle kan soju opo Instagram rẹ to fi fọto ọhun si, ohun to kọ si i ree, '' mi o fi ọ ṣere rara, mo si fẹ ki gbogbo aye mọ bẹẹ''.

Ami ifẹ ni Brenda Biya fi siwaju ọrọ naa bo ti kọ ọ tan.

Baba rẹ, Paul Biya, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrun-un (91,) lo ti n ṣe aarẹ Cameroon lati ọdun 1982, o si jẹ ọkan lara awọn aarẹ to pẹ ju lori oye nilẹ Adulawọ.

Ohun to tubọ fa ariwo lori ọrọ ọmọbinrin aarẹ yii ni pe eewọ ni ibalopọ akọ-si-akọ, tabi abo-si-abo lorilẹede Cameroon.

Bo si tilẹ jẹ pe oke okun ni Brenda Biya n gbe ju, sibẹ, awọn araalu baba rẹ n kọminu nipa ohun ti ọmọ olori wọn ṣe.

Ṣe èyí túmọ̀ sí pe ọmọbinrin ààrẹ n dán nǹkan èèwọ̀ wo ni?

Olorin ni Brenda Biya, 'King Nasty' lorukọ tawọn eeyan mọ ọn si lagbo ariya.

Ṣugbọn bo ti gbe aworan to di ariwo yii sita to, ko fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe oun n lọwọ si ibalopọ obinrin-si-obinrin.

Ko sọ ero ọkan rẹ nipa ibalopọ bẹẹ bo ti gbe fọto yii jade to.

Ni Aarin-gbungbun ilẹ Adulawọ, ẹwọn ọdun marun-un ni awọn tọwọ ba tẹ pe wọn lọwọ si ibalopọ ẹda eeyan kan naa maa n ṣe gẹgẹ bi ijiya.

Ṣugbọn lẹyin asiko diẹ to fi aworan naa sori ayelujara, Brenda Biya gbe iroyin kan jade lati inu iwe iroyin Le Monde, nibi ti wọn ti fi ede Faranse kọ ọ pe o ti kede ''iru eeyan to jẹ.''

O tun fi ọrọ ti awọn ti wọn lawọn wa lẹyin rẹ sọ sita sita pẹlu.

Ọkan ninu awọn to fi idunnu wọn han si ọmọ aarẹ Cameroon yii ni obinrin kan , Shakiro, toun naa nifẹẹ si ibalopọ abo-si-abo to si maa n kede rẹ lai fi bo rara ni Cameroon, ko too raye sa lọ si oke okun.

Shakiro sọ pe Brenda ti n lo ara rẹ bii agbẹnusọ fawọn eeyan ti ko lagbara lati sọrọ lorilẹede ti wọn o mọ ju ki wọn maa pariwo eewọ lọ.

Orilẹde Belgium ni Shakiro n gbe bayii, lẹyin ti wọn mu un pe o jẹbi ẹsun ibalopọ obinrin si obinrin ni Cameroon.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan n gboriyin fun Brenda, ọpọ eeyan lo n sọrọ buruku si i lori ayelujara. Wọn ni obinrin bii tiẹ lo n ba lo pọ.

Aṣoju to gboya ni Brenda Biya, o n fi ifẹ ranṣẹ si gbogbo aye ni - Alice Nkom

Bakan naa lawọn mi-in sọ pe Brenda gbe aworan naa sibẹ lati pe ero soju opo ayelujara rẹ ni, awọn mi-in si n beere pe ṣe nitori ọmọ ọla to jẹ lo ṣe n huwa ta a ni yoo mu mi.

“ Mo nifẹẹ si eyi fun ọmọ aarẹ Cameroon'' . Bandy Kiki, ajafẹtọọ awọn LGBT (Lesbian, Gay, Bisexual and Transgender) lo kọ eyi soju opo Facebook rẹ.

Ilu oyinbo ni Brenda Biya n gbe, ṣugbọn labẹ ofin, wọn le mu un to ba ni ibalopọ abo-si-abo nigba to ba wa si Cameroon to si ru ofin to de ibalopọ .

Awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ti n lodi si ofin orilẹede Cameroon yii, wọn ni o le ju fun awọn LGBT.

Ni 2020, ajọ Human Rights Watch rọ Cameroon lati yi ofin to de awọn eeyan yii pada, wọn ni ki wọn jẹ ki kaluku ni ominira nipa ẹni to ba fẹẹ ba ṣe.

Amofin Alice Nkom, lọọya to gbajumọ ni Cameroon to si tun n ja fẹtọọ ọmọniyan, sọ pe aṣoju to gboya ni Brenda Biya, o ni o n fi ifẹ ranṣẹ si gbogbo aye ni.

Ọpọlọpọ ileeṣẹ iroyin ni ko gbe iroyin fọto ifẹnukonu ọmọ aarẹ wọn yii, ajọ to n ri si iṣẹ wọn le fiya jẹ ẹni to ba polongo ibaṣepọ to lodi labẹ ofin wọn.

Ijọba orilẹede Cameroon ati Aarẹ Biya funra rẹ ko ti i sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ ọmọ aarẹ yii.

Ẹka iroyin BBC kan si Brenda Biya funra rẹ, ṣugbọn ko ti i fesi titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii.