Ẹ fura o! Ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye yóò ��e ètò kan lónìí káàkiri Nàìjíríà tó lè m'éwu dání f'áráàlú - ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá

Aworan awon omo egbe okunkun

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti kilọ fawọn araalu lati wa lojufo latari eto kan ti wọn ni ẹgbẹ okunkun Aiye fẹ ṣe lonii ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Keje ọdun 2024 yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe-Koko lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta.

SP Iringe-Koko ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbọ labẹlẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye yoo ṣe ayajọ oludasilẹ wọn lọjọ keje oṣu Keje ọdun 2024 yii.

O ni ayẹyẹ ayajọ yii ti wọn pe orukọ rẹ ni 7/7 yoo waye ni gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria papaa julọ l'awọn ile ẹkọ giga.

SP Iringe-Koko ṣalaye ninu atẹjade to fi sita naa pe "ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣai mọ bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ṣe maa n fi ẹmi awọn ṣ'ofo to fi mọ ṣiṣe ikọlu s'awọn ẹgbẹ okunkun mii l'awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria.

"Ẹgbẹ okunkun Aiye le lo ayẹyẹ 7/7 lati fipa mawọn eeyan wọ ẹgbẹ wọn"

Ileeṣẹ ọlọpaa woye pe ayẹyẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye fẹ ṣe yii yoo waye ni ibuba wọn lawọn ọgbà ile ẹkọ.

Eto naa si tun le ṣokunfa ikọlu s'awọn ẹlẹgbẹ okunkun mii.

Bakan naa, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye tun le lo eto yii lati fi ipa mu awọn eeyan wọ ẹgbẹ wọn, ati pe wọn tun le lo eto naa lati fipa b'awọn obinrin lopọ ati lati jale.

Ni bayii, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Rivers, CP Olatunji Disu ti paṣẹ pe káwọn ọlọpaa ṣawari ibi gbogbo t'awọn ẹlẹgbẹ okunkun Aiye ba ti ko ara wọn jọ, ki wọn ṣi fọwọ ofin mu wọn.

CP Disu tun paṣẹ fawọn ọlọpaa wi pe ki wọn ri pe ayẹyẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye fẹ ṣe ọhun ko waye.

Ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga lati pese abo to peye fawọn akẹkọọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn obi ati alagbatọ pe ki wọn mojuto awọn ọmọ wọn papaa julọ lasiko yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn adari ẹsin lati ma dẹkun sisọ ewu to wa ninu didarapọ mọ ẹgbẹ okunkun fawọn olujọsin.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ko ni beṣu bẹgba lati ri pe oun daabo bo araalu ati dukia wọn."