Mọ̀ si nípa àìsàn ‘Dementia’, máṣe pe arúgbó rẹ ní àjẹ́ tàbí wèrè torí làákàyè rẹ̀ tó ń ṣíṣẹ kíṣẹ́ lọ́jọ́ ogbó

Àkọlé fídíò, Dementia: Máṣe pe arúgbó rẹ ní àjẹ́ tàbí wèrè torí pé làákàyè rẹ̀ ń ṣíṣẹ kíṣẹ́ lọ́jọ́ ogbó
Mọ̀ si nípa àìsàn ‘Dementia’, máṣe pe arúgbó rẹ ní àjẹ́ tàbí wèrè torí làákàyè rẹ̀ tó ń ṣíṣẹ kíṣẹ́ lọ́jọ́ ogbó

Lorilẹ Afirika, ọpọ idẹyẹsi lawọn ọdọ maa n se sawọn arugbo wọn to ba ni arun to nii se pẹlu ọjọ ogbo eyi to n mu ki ọpọlọ wọn se isẹkisẹ, taa mọ si Dementia.

Ọpọ wọn lo n pe awọn arugbo to n tọ sara, gbagbe nkan, tabi ki ọrọ wọn ma ba taye mu, ni were ati ajẹ, eyi ti ko dara.

Ninu fidio to n lanilọyẹ yii, awọn olutọju arugbo kọ wa ni awọn ohun to yẹ ka se lati setọju awọn arugbo yii, ki ọjọ alẹ wọn lee rọrun fun wa.

Ibudo itọju arugbo

"Bi ọpọlọ arugbo ko ba sisẹ bo se yẹ, ni iya yoo ri ọmọ rẹ, ti ko si ni da a mọ mọ"

Nigba ti a de ile ti wọn ti n tọju arugbo kan, a se alabapade awọn arugbo ti wọn gbe wa sibẹ, ti isesi wọn ko dape to, ti oludari ibudo naa si salaye ohun to n fa ihuwasi naa.

O ni aisan kan ti wọn n pe ni Dementia lo n ba wọn fin ra, kii kuku se pe Ajẹ ni wọn tabi pe wọn ya were.

Amọ dipo ki awọn obi mii ri itọju to peye gba lasiko ti aisan Dementia yii n ba wọn finra, se ni awọn ọmọ ati ẹbi wọn yoo pa wọn ti.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Mama Laetricia tii se olutọju awọn arugbo ni igba ti ọpọlọ arugbo ko ba sisẹ bo se yẹ, ni iya yoo ri ọmọ rẹ, ti ko si ni da a mọ mọ.

“Kii se pe awọn arugbo to ni aisan Dementia yii jẹ eeyan buruku ni ko se da aya, ọkọ ọmọ tabi ẹbi rẹ mọ, amọ inu ọpọlọ rẹ ni arun naa wa.

Oyinbo ni bi igba ti alantakun ba ti mu ẹgbẹ ibi kan, to ta owu si ninu ọpọlọ, ti ko si lee sisẹ deedee, ni aisan Dementia ri.”

Ibudo itọju arugbo

Kii se pe awọn arugbo to n se werewere ni ajẹ tabi pe were ni wọn, amọ ẹ gbe wọn wa lati se itọju wọn.”

Bakan naa ni olutọju arugbo miran, Kiki Edwards salaye pe awọn arugbo miran maa n rin ihoho bọ sita lẹyin ti wọn ba ti ile igbọsẹ de lai da asọ bora pada nitori pe wọn ti gbagbe lati se bẹẹ.

“Nigba miran, ẹlomiran yoo mura pe oun n lọ sibi isẹ amọ ti yoo duro si oju kan lai ranti ohun to fẹ se mọ.

Kii se pe wọn ni ajẹ tabi pe were ni wọn, amọ ẹ gbe wọn wa lati se itọju wọn.

Nigba miran wọn yoo maa se aran tabi tọ si ara.”