Wo bí o ṣe lè fi ojú òpó Facebook rẹ gba owó

Aworan owo dola ati Facebook

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ileeṣẹ Meta to ni oju opo Facebook, Instagram ati Whatsapp,ti kede pe awọn to n ṣe fiimu ni Naijiria ati Ghana yoo ni anfaani lati maa lo iṣẹ wọn loju opo ayelujra wọnyi, wọn yoo si maa ri owo gba.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Mọnde, ọjọ kin-in-ni oṣu keje ọdun 2024 yii Moon Baz, to n dari awọn iṣẹ wọnyi nilẹ Africa, Turkey ati Middle East ti sọ pe igbesẹ yii yoo ran awọn onifiimu lati Naijiria pẹlu Ghana lọwọ lati ri owo.

O ni yoo tun fun wọn lanfaani lati mu idagbasoke ba ẹka iṣẹ wọn kaakiri agbaye.

Ọjọ kẹta ti ọga to n ri si ọrọ ilẹ okeere nileeṣẹ Meta, iyẹn Nick Clegg, de si Naijiria ni ikede yii waye.

Clegg to ti ba Aarẹ Bọla Tinubu ṣepade, ṣeleri nibi ipade naa pe awọn ọmọ Naijiria yoo pin ninu ere tawọn jẹ lori awọn fidio to wa loju opo Facebook loṣu kẹfa ọdun 2024 yii.

Ṣugbọn ki ni awọn eeyan naa yoo ṣe ki wọn too le maa ri owo yii gba?

Ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe láti rí owó gbà

Gẹgẹ bi ileeṣẹ Meta ṣe wi, akọkọ ni pe:

O kere ju, o gbọdọ ti pe ẹni ọdun mejidinlogun (18).

*O gbọdọ maa gbe lorilẹ-ede ti wọn ti mọ ọ pẹlu iṣẹ ti o n ṣe.

*O kere tan, o gbọdọ ni olutẹle (followers) ẹgbẹrun marun-un loju opo naa.

*Eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọta (60,000 viewers), o kere tan gbọdọ wo fiimu rẹ laarin ọgọta ọjọ.

Awọn ti wọn ṣe fiimu yii ati awọn ti wọn sanwo fun ipolowo rẹ ko si ninu eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọta yii o, ileeṣẹ Meta ko ni i ka wọn mọ ọn.

*O kere tan, oju opo rẹ gbọdọ ni aworan marun-un tawọn eeyan le ri.

* Ki i ṣe gbogbo aworan lo kunju oṣuwọn, awọn mi-in le ma tẹ Meta lọrun, wọn ko si ni i pawo.

Òfin tó de yíya àwọn àwòrán àti ìpolówó ọjà.

Fun awọn aworan to n ṣafihan iṣẹlẹ bo ṣe waye, o kere tan, o gbọdọ ni ẹgbẹrun mẹwaa olutẹle.

*Wọn ti gbọdọ wo fidio naa fun iṣẹju ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (600,000 minutes) laarin ọgọta oru, (60 nights).

* O kere tan, aworan marun-un ti iwọ funra rẹ ṣe mẹta ninu rẹ gbọdọ wa niwaju fawọn eeyan lati ri.

* O lodi sofin lati lo ere to ni i ṣe pẹlu iku, ibalopọ, eke ṣiṣe, iroyin ofege ti ki i ṣe otitọ abi iroyin nipa ilera to jẹ irọ gbuu ni.

Ayélujára ti sọ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ di ojú tó pawó, pèsè iṣẹ́ fún wọn

Aworan awọn alawada meji

Oríṣun àwòrán, Sabinus/ Women @Instagram

Bi oju opo ayelujara ti a mọ si Social media ṣe n gunke si i lo n ṣina fun ọpọlọpọ ọdọ to n lo o fun iṣẹ ọpọlọ ti wọn n ṣe ti wọn si fi n pawo pẹlu.

Awọn eeyan tẹnikan ko mọ tẹlẹ ni wọn ti tipasẹ awọn oju opo yii di gbajumọ ati oju to pawo.

Awọn ileeṣẹ nla nla n lo wọn fun ipolowo ọja, wọn si n sanwo gidi fun wọn.

Awọn fidio ẹfẹ, ọrọ iṣiti ati awọn nnkan mi-in bẹẹ ni wọn n gbe soju opo bayii to si ti di ohun ti awọn eeyan ko le ma wo, bẹẹ lo n pawo fawọn eeyan naa.

Apẹẹrẹ iru awọn to n fi oju opo ayelujara pawo ni ọkurin kan, Emmanuel Ejekwu tawọn eeyan mọ si ‘Oga Sabinus’.

Awọn fidio awada lo fi bẹrẹ loju opo Facebook ati Instagam, to fi ṣe bẹẹ di ẹni to n relu oyinbo bayii lati kopa ni gbagede.

Bakan naa ni ọmọ Ghana kan, Akwasi Boadi tawọn eeyan mọ si 'Akrobeto', ko ṣe iṣẹ meji ju awọn fidio ẹfẹ to maa n gbe soju opo YouTube ati Instgram rẹ lọ.

Nibẹ to ti maa n ka iroyin ere idaraya.

Oun naa ti gbabẹ di ilu mọ ọn ka bayii, o si ti n pawo to daa lori ayelujara.