Àwọn wo ni ìdádúró owó orí kàn àti àǹfààní tó wà nínú rẹ̀?

Ọja

Ijọba orileede Naijiria si sọ ọ di mimọ pe ohun ti dawọ sisan owo ori duro fun awọn olokoowo keekeeke ti ere ti wọn n jẹ ko to nnkan ati fun awọn agbẹ.

Alaga igbimọ aarẹ to n ri sọrọ bi ijọba ṣe n na owo ati atunto owo ori (Fiscal Policy and Tax Reforms), Taiwo Oyedele lo sọ eyi di mimọ lori ikanni ‘X’ rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bi Oyedele ṣe ṣalaye, o ni igbesẹ yi lo waye lori eto to n lọ lọwọ nipa agbeyẹwo adojukọ lori eto owo ori ati owo nina ọlọjọ pipẹ to ti n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Ki ni idaduro owo ori?

Idaduro owo ori jẹ eyi ti ijọba apapọ yoo maa yọ lati apo iṣuna awọn to n san owo ori bii awọn agbaṣẹṣe, awọn to n ṣe ohun lilo jade, awọn lanlọọdu ati bẹẹbẹẹlọ. Inu apo iṣuna ijọba ni owo ọhun yoo maa lọ nigba ti wọn ba san an lorukọ awọn ti ọrọ kan.

Ọdun 1977 ni wọn ti kọkọ gbe eto yii kalẹ sinu agbekalẹ eto ipawo-wọle ijọba, eyi si ni lati ma ṣe jẹ ki awọn eeyan maa sa fun sisan owo ori.

Ida marun si mẹwaa ni iye idaduro owo ori sisan to wa ni Naijiria lọwọlọwọ, to si nii ṣe pẹlu awọn owo sisan bii ile gbigbe, owo ileewe, ele lori owo, owo iṣẹ ṣiṣe, ipin idokowo ati bẹẹbẹẹlọ.

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ki lo de ti ijọba fi n yọ owo ori naa kuro?

Ijọba Naijiria sọ pe pẹlu eto to n lọ lọwọ lori agbeyẹwo owo nina ati owo ori sisan, awọn ti ri awọn abuda kan, eyi to n jẹ ki awọn eeyan ma le san owo ori, ti wọn si gbọdọ wa iyanju si.

Wọn tun ni idaduro owo ori ni wọn n ko papọ mọ owo ori ọtọ, eyi to n jẹ ki awọn eeyan maa san owo ori rẹpẹtẹ, to si n jẹ ki okoowo ṣiṣe maa le koko lorileede yii.

Ijọba nigbagbọ pe bi wọn ba fopin si idaduro owo ori sisan yii lati ọdọ awọn agbẹ, awọn ileeṣẹ to n gbe nnkan lilo jade, eyi yoo mu adinku ba owo ounjẹ ati ohun lilo.

Awọn wo lo n jẹ anfaani, ati pe ki lo tumọ si fun wọn?

Ni Naijiria, awọn okoowo keekeeke ni awọn ti owo ti wọn n pa lọdun ko to miliọnu marundinlọgbọn naira, ti wọn ko si tun ni to aadọta oṣiṣẹ.

Orileede to gbajumọ julọ nile Afrika lo ni adojukọ lori eto ọrọ aje wọn, pẹlu ida mẹtalelọgbọn lori ẹkunwo awọn ohun ti wọn n lo, to si jẹ ki owo ounjẹ ohun elo miran gbowo lori.

Awọn eroja ounjẹ bii Tomato, Ata, ẹyin, ẹfọ, ororo ni wọn ti gbowo lori kọja sisọ laarin ọdun kan sẹyin, eyi to jẹyọ lati ara owo epo to lọ soke ati owo naira ti ko lagbara kankan mọ.

Labẹ ilana tuntun yii, awọn olokoowo keekeeke ni wọn ti yọ kuro ninu owo ori sisan.

Bo tilẹ jẹ pe orileede yii yoo maa padanu owo to n wọle lati ọdọ awọn olokoowo keekeeke wọnyi, ṣugbọn Ọmọwe Olusegun Vincent to jẹ onimọ nipa owo ori ni fasiti Pan Atlantic nipinlẹ Eko nigbagbọ pe ilana tuntun yii yoo ni ipa ọjọ pipẹ lagboole okoowo ṣiṣe.

“Ijọba ti n da owo pada si apo awọn okoowo keekeeke. Wọn maa maa ri owo lati mu okoowo wọn tẹsiwaju, ki wọn si gba awọn oṣiṣẹ siṣẹ, ati lati mu idagbasoke ba ohun ti wọn n ṣe jade, eyi ti yoo mu eto ọrọ aje to n ṣaisan dide duro.” O sọ fun BBC.

Lọdun 2020, ileeṣẹ Price Water Coopers (PwC) ṣakọsile ida mẹrindinlọgọrun awọn olokoowo keekeeke ti Nigeria’s Micro Small and Medium scale Enterprises lorileede yii; wọn si gba ida mẹrinlelọgọrin ṣiṣẹ, eyi ti wọn tun ko iupa mọkandinlaadọta ninu eto ipawo-wọle orileede yii

“Niṣe lo dabi ida oloju meji. Ijọba wa ọna lati pawo wọle, ṣugbọn o tun ṣe pataki lati jẹ ki awọn olokoowo da duro, nitori pe yoo fuin awọn ileeṣẹ lanfaani ni agbara, ati pe ko nii ṣe bi wọn ṣe kere to, o maa ni ipa rere to n ko ninu adinku lori owo ounjẹ, ati eto ọrọ aje to n lọ soke.” Ọmọwe Vincent fi kun ọrọ rẹ.

Titi di asiko yii ni awọn alakoso ko tii sọ pato ọjọ ti ilana yii yoo bẹrẹ iṣẹ, ṣugbọn ti idaniloju ti n wa pe awọn olokoowo keekeeke ati awọn agbẹ yoo ni ifọkanbalẹ niwọn igba ti ilana yii ba di ofin.