Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ, fi oyún 27 gún ọṣẹ

Shina Rambo

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Yoruba ni bi ọmọ ko ba jọ sokoto, yoo jọ kijipa, ẹni to ba bi ni laa jọ.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu itan igbe aye arakunrin kan ti ọpọ eeyan mọ si Shina Rambo.

Shina jẹ ẹda to ga, o to iwọn ẹsẹ bata mẹfa ati aabọ, to si tun ni omi lara, o si dudu lawọ.

Ogboju adigunjale laarin ọdun 1990 si 2000 nii ṣe, ki ọwọ agbofinro to ba a, o lọ ṣe ẹwọn, nibẹ lo si ti ba Ọlọrun pade, o di ajihinrere fun Oluwa.

Bi irinajo aye Apamọlẹkun jaye ẹda naa si ṣe lọ ree, gẹgẹ bi oju opo Wikipedia atawọn ifọrọwanilẹnuwo ti Shina Rambo se.

Bi Shina Rambo ṣe bẹrẹ aye rẹ de idi ole jija

Ọdun 1958 ni wọn bi Shina sile aye, ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni baba rẹ nigba ti iya rẹ jẹ ọmọ ilu Sabongida-Ora nipinlẹ Edo.

Baba rẹ jẹ oṣiṣẹ ologun taa mọ si Sọja, to si ni iyawo to le ni mejidinlogun nitori ọpọ ibi ti iṣẹ gbe lọ, lo ti n fun obinrin loyun.

Gẹgẹ bi Shina Rambo ti salaye, baba oun maa n lo aṣọ ati irinsẹ ologun lati ja awọn eeyan lole, to si maa n ko owo pupọ wa sile.

Lati ọmọ kekere si ni Shina ti n laju ri owo tuulu bayii lọwọ baba rẹ, eyi to maa n wọ ọ loju.

Ni ọjọ kan, nigba ti Shina wa ni ọmọ ọdun meje, baba rẹ gbe apo nla kan to kun fun owo pupọ wa sile.

Awọn owo yii jẹ owo beba ilẹ okeere, ti ẹjẹ si kun ara owo naa, wọn n lo gele obìnrin kan lati nu ẹjẹ kuro lara owo naa.

Shina ni asiko yii ni oun wa bi baba oun pe "Ṣe ẹjẹ eeyan niyi ni abi ẹjẹ ẹranko?".

Ṣugbọn o ni baba oun ko dahun, gbogbo wọn kan n mu ọti ati siga lọ ni, wọn ti wọn si n ṣe faaji pẹrẹu.

Inu Baba mi bajẹ tori mo to ibọn, to si fẹ fi ada ge mi lori tori

Bakan naa, adigunjale yii ni ọpọ igba ni baba oun yoo tu ìbọn Sọja rẹ kalẹ loju oun, ti yoo si tun to o pada, bẹẹ ni oun n fi oju si oun to n ṣe.

Amọ ni ọjọ kan, Shina ni oun wọ yara baba oun lasiko to lọ ṣe igbọnsẹ, oun ri ìbọn rẹ to tu kalẹ, ti oun si joko lati to ìbọn naa pada, eyi ti oun ṣe lai si wahala kankan.

Baba rẹ wọle ba nibẹ pẹlu ìbọn to ṣẹṣẹ to tan, o ni inu baba oun bajẹ, to si fẹ pa oun, o yin ìbọn mọ oun nitootọ amọ ori ko oun yọ, ti oun si sa jade.

Shina ni "Baba mi duro de mi ni alẹ, o yọ kẹlẹ wọ yara mi, to si fẹ fi ada ge mi lori, mo tiraka lati sa mọ lọwọ sugbọn ada naa ba mi ni ẹsẹ osi, ti apa rẹ si wa lara mi di oni olonii."

Shina fikun pe ọjọ yii gan ni oun gba pe oun ti gba iyọnda lẹnu isẹ, ohun to ku ni ki oun gbe ìbọn, bi oun si ṣe bẹrẹ iṣẹ adigunjale ree.

Mo se ahọn ọgọrun eeyan jẹ

Shina Rambo gba pe idi isẹ ẹni laa ti mọ ni ni ọlẹ, to si tiraka lati lu aluyọ nidii isẹ adigunjale.

Niwọn igba to jẹ pe ẹni ti yoo ba jẹun gbọin-gbọin, gbọdọ ti ilẹkun gbọin-gbọin, Shina wa agbara kun agbara, o n ṣe oogun abẹnu gọngọ, ko si si ibi ti ko ṣe oogun de.

Wọn ni ẹni ti yoo ba ba esu jẹun, sibi rẹ yoo gun, Shina ro ara rẹ lagbara ninu oogun debi pe o fi ọmọ odo gun ọlẹ̀ inu alaboyun mẹtadinlọgbọn lati fi ṣe oogun ìṣọ́ra.

Bakan naa, Shina tun ge ahọn ọgọrun eeyan, ó ṣe e jẹ, to si tun gbe ninu igi iroko fun ọpọlọpọ ọjọ, bakan naa lo n sun ni itẹ oku lati sọ ara rẹ di ọkùnrin.

Ko tan sibẹ o, Shina tun wa agbara lọ silu Ogoja nipinlẹ Cross Rivers, to si setan lati di ilumọọka ogbontagi adigunjale to n dẹru ba araye.

Itẹ oku si ni wọn ti fun ni obìnrin kan bíi aya to maa n tẹle lọ digunjale ti gbogbo aye mọ si Alhaja, awọn eeyan ro pe eeyan ni amọ alujannu ni.

Alhaja maa n bo ori ni, kii si oju silẹ kí asiri rẹ ma ba a tete tu pe abara meji ni, ko si si ẹni to maa n ri oju rẹ rara.

Shina Rambo ni Alhaja yii ni awakọ oun, to si le sare asapajude pẹlu mọto laisi ewu, laarin iṣẹju diẹ, yoo si wa ọkọ lati Naijiria de Cotonou.

Shina, lasiko to n sọ irinajo rẹ fawọn akọroyin lẹyin ti ọwọ ba a tan, salaye pe "ọpọ etutu ni mo ti ṣe, ti n ko si le e ka tán."

Mo lo to ọdun kan ninu igi Iroko

"Mo di alagbara pupọ, mo lọ sinu igi iroko, to fẹ to odidi ilu kan, ọpọ ile to rẹwa lo wa nibẹ ninu igi Iroko, koda, mo nile temi nibẹ nibi ti ọpọ oloselu atawọn ọlọrọ maa n wa."

Shina Rambo fikùn pe, oun le e gbe orisirisi àwọ̀ eeyan wọ nigba kuugba to ba wu oun, eyi to mu ko nira fawọn ọlọpaa ri oun mu.

Shina ni: " Wọn n pa awọn eeyan miran ti ko mọwọ-mẹsẹ ninu iwa idigunjale, wọn ro pe Shina Rambo ni awọn n pa, koda, babalawo mẹsan to ṣe oogun naa fun mi, ọwọ ara mi ni mo fi pa wọn, ki wọn ma baa tu asiri mi."

Shina ni oun ge ori ọgọrun eeyan, ti oun gbe fun awọn Babalawo naa, wọn si ṣe oogun afẹẹri fun oun, ko si si iru ọta ibọn ti wọn yin mọ oun, bii igba ti wọn sọ ọra omi lu oun ni, ko si si oun ti oun ko le ṣe lati wa agbara.

Bakan naa ni Shina Rambo ni eyi to ba oun ninu jẹ julọ ni pe oun ba iya oun lopọ ri, igbakuugba ti oun ba si foju kan iya arugbo naa, ni ibanujẹ maa n gba ọkan oun.

Bi Shina Rambo ṣe di ẹru jẹjẹ si ilu lọrun

Lẹyin to gba ọpọ agbara yii, Shina Rambo di ẹru jẹjẹ, ogbontagi adigunjale ati apamọlẹkun jaye, to n ja ilu lole laisi ẹni to to wo o loju.

Lọpọ igba gan lo ti wọ agọ ọlọpaa lọ, ti yoo si pa gbogbo awọn ọlọpaa to ba wa nibẹ lọsan gangan, to si buru ju alujannu oloju kan lọ.

Bo ṣe n na orilẹede Naijiria, lo n pada si ilu Cotonou ni Republic of Benin, ti yoo si fi tipa gba ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ bíi ogoji ni ọjọ kan ṣoṣo, bẹẹ lo di olowo ati ọlọrọ rẹpẹtẹ.

Shina Rambo ni iyawo ati ọmọ mẹta sugbọn gbogbo rẹ lo padanu ni ọjọ kan naa lasiko tàwọn ọlọpaa bẹ ile rẹ wo nigba to ti jade lọ ṣíṣẹ idigunjale, ṣe atakoro wọ inú Ado, ko le mu ọmọ rẹ wọ ọ.

Nigba to n sọrọ nipa iyawo rẹ, Rambo ni "Igi lẹyin ọgba ni iyawo mi jẹ fun mi, mo si maa n pada sile lọ sun ti, lẹyin ti mo ba jale tan."

"O mọ iru isẹ ti mo n ṣe, idi ree ti ọwọ ọlọpaa ko fi tete tẹ mi. Emi kii sun sita ni alẹ, mo maa n pada sile lẹyin ti mo ba jale tan ni ọ̀san gangan."

O tẹsiwaju pe, "Mo lowo, mo lọla, mo si n na owo to to aadọta miliọnu loojọ."

"Ọjọ kan tiẹ wa, ti ewe oogun mi fẹ sunko, ọwọ awọn ọlọpaa ati ologun fẹ tẹ mi, a yaa bọ sagbo awọn eeyan to n ṣe inawo, a fọn owo soju agbo, ọpọ eeyan àtàwọn ọlọpaa gan n sa owo, la ṣe ri ọna sa lọ."

Bi ọwọ agbofinro ṣe tẹ Shina Rambo, ijiya ẹṣẹ rẹ ati bo ṣe di ajihinrere

Lẹyin ti aya, ọmọ ati ohun gbogbo ti Shina Rambo ṣiṣẹ fun tan, ti gbogbo rẹ poora loju aye rẹ, lo ba lọ fi ara rẹ silẹ fawọn ọlọpaa.

Wọn gbe lọ sile ẹjọ, ti adajọ si sọ si ẹwọn ọdun mọkanla ni ọgba ẹwọn Agodi nilu Ibadan.

Asiko to si wa ninu ọgba ẹwọn naa lo ṣe alabapade oloogbe Wolii T.O Obadare lasiko to wa waasu nibẹ.

Shina Rambo fi aye rẹ jin Ọlọrun, Obadare gbadura fun, to si yi orúkọ rẹ pada si Oluwafemi, asiko ti Oloye Olusegun Obasanjo n dari orile-ede Naijiria si lo fun Shina Rambo ni idande kuro lọgba ẹwọn.

Lati igba naa wa ni Shina Rambo ti n waasu ihinrere Ọlọrun, to si dagbere fun iwa idigunjale.

Ẹkọ ti itan igbe aye Shina Rambo kọ wa

Ẹkọ akọkọ ni pe ki obi mase huwa ibajẹ loju awọn ọmọ wọn nítorí obi ni awokose fawọn ọmọ wọn.

Ẹkọ keji ni pe ko yẹ ki awọn òṣìṣẹ́ ti ilu ba gbe ara le ja ilu kulẹ gẹgẹ bi baba Shina Rambo ti ṣe.

Ẹkọ kẹta ni pe o yẹ ka mọ pe bo pẹ, bo ya ewe yoo sunko nitori oogun lo ni ọjọ kan ipọnju, ori ẹni lo ni ọjọ gbogbo.

Bakan naa lo yẹ ka kọgbọn pe ko si ohun gbogbo taa fi ọna eru ko jọ, ti yoo ba ni kalẹ nitori ibukun Oluwa nii mu ni la, laifi laalaa kun.

O tun yẹ ko ye wa pe ko si ẹni ti Ọlọrun ko le mu, asegbe kankan ko si si, asepamọ nikan lo wa.

Lakotan, itan Shina Rambo kọ wa pe ko si ẹda ti Ọlọrun ko le lo fun itankalẹ isẹ rẹ, lai naani bi igbe aye onitọun ti buru to ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ.