Wo ọmọbìnrin tó ń fi òwú híhun ṣe iṣẹ́ ọnà aláràmbarà

Àkọlé fídíò, Kọlade Mayowa Bolade
Wo ọmọbìnrin tó ń fi òwú híhun ṣe iṣẹ́ ọnà aláràmbarà

Kolade Mayowa Bolade jẹ ọdọmọbinrin to fẹran ko maa fi owu hun nnkan ọna alaranbara lati kereke.

Koda, oun ki i lo irin ti wọn fi maa n hun owu naa nigba to bẹrẹ, igbalẹ meji lo ni oun maa n to pọ toun yoo si fi mu iṣẹ ọna to wu oju jade.

Bo tilẹ jẹ pe o ti pe ẹni ọgbọn ọdun bayii, Mayowa fidi ẹ mulẹ pe ọmọkekere loun ṣi wa toun ti n fi owu hun aṣọ, bẹliiti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọmọbinrin yii lọ sileewe yunifasiti bi awọn ẹgbẹ rẹ, o kẹkọọ nipa ile kikọ, ṣugbọn bo ti ṣetan naa lo tun pada si ifẹ rẹ akọkọ ti i ṣe nnkan hihun.

''Bi mo ṣe pada si hun awọn nnkan oriṣiiriṣii bii baagi lawọn eeyan bẹrẹ si i nifẹẹ si i, mo wa n ṣe e ni gbagede .

Awọn ọrẹ, ojulumọ ati ẹbi gbaruku ti mi lati sọ ọ di iṣẹti mo fi n pawo.''

Iyàtọ wà láàrín nǹkan híhun tí a lo irin méjì fun àti ẹlẹ́yọ kan

Ọpọ eeyan ni ko mọ aṣiri to wa ninu awọn baagi, aṣọ tabi bata ti wọn fi ohun hun, ọna meji ni wọn n gba hun awọn iṣẹ ọna yii bi Mayowa ṣe ṣalaye.

Eyi to pe ni Knitting lo ni irin meji ni wọn fi n hun un, nigba ti Crocheting n lo irin kan ṣoṣo

Àrà to wuyi ni mejeeji yoo mu wa bo ṣe wi, bẹẹ lo ṣalaye pe ẹkọ nipa ile kikọ toun kọ ni yunifasiti naa wulo fun iṣẹ ọna yii, pẹlu atilẹyin awọn idanilẹkọọ ori ayelujara Youtube toun tun kọ nipa nnkan hihun .

Mayowa sọ oun ki i le sọ ni gbangba nigba kan pe iṣẹ nnkan hihun (crocheting) loun n ṣe, nitori oun ki i le kọ ọ silẹ bẹẹ ninu fọọmu.

O ni ṣugbọn nigba tiṣẹ naa di nnkan nla tan, oun ki i tiju lati sọ fawọn eeyan pe iṣẹ ọwọ loun n ṣe.

O fi kun un pe boun ba ri awọn akẹgbẹ oun ti wọn n kọ ile gẹgẹ bii ẹkọ tawọn kọ ni fasiti, inu oun maa n dun, nitori oun naa n fi ẹkọ iwe kun iṣẹ ọwọ toun n ṣe yii.

Ọmọbinrin yii wa ni oun o ti i bẹrẹ rara o, o loun ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni, nitori oun fẹẹ gba awọn eeyan mọra lọjọ iwaju, ti wọn yoo maa ṣiṣẹ taara lọdọ oun toun yoo si maa sanwo fun wọn.

To bẹẹ to jẹ bi wọn ba lọ si fasiti paapaa, wọn yoo tun le fi iṣẹ nnkan hihun yanga lawujọ.