Mbappe gbá góòlù méjì sáwọn lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ ìbòjú gbá bọ́ọ̀lù

Aworan Kylian Mbappe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹlẹsẹ ayo agbabọọlu orilẹede France, Kylian Mbappe gba goolu meji sawọn ninu ere bọọlu igbaradi ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede rẹ lẹyin to fi imu ṣeṣe.

Mbappe fi imu ṣeṣe ninu ere bọọlu akọkọ ti France kọkọ gba pẹlu Austria ninu idije Euro 2024 to n lọ lọwọ.

Mbappe wọ iboju gba bọọlu fun wakati kan ninu ere bọọlu igbaradi ẹgbẹ agbabọọlu France pẹlu ikọ agbabọọlu Germany, Paderborn ti ọjọ ori awọn agbabọọlu wọn ko ju ọdun mọkanlelogun lọ.

Mbappe to jẹ balogun ẹgbẹ agbabọọlu France ko le kopa kankan ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ikọ agbabọọlu Les Blues ati Netherlands ninu eyi ti wọn ti ta ọmi 0-0.

Ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu afẹsẹgba lo sọ pe Mbappe ko ba mi awọn titi ti o ba ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ France ati Netherlands ti wọn ti ta ọmi odo sodo ni.

Amọ, lọjọ Abamẹta ni Mbappe kopa ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ pẹlu Paderborn ninu eyi to ti fakọyọ gba goolu meji sawọn.

O ṣeeṣe ki Mbappe wọ iboju rẹ lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Iṣẹgun ti yoo waye laarin France ati Poland.

Ṣaaju idije Euro 2024 ni Mbappe fi ẹgbẹ agbabọọlu PSG silẹ lọ darapọ mọ ikọ Real Madrid lorilẹede Spain.