Èsì ìbò jáde ní France, ẹgbẹ́ òṣèlú Ààrẹ Macron fìdírẹmi, kò s’ẹ́gbẹ́ tó lè dá ìjọba ṣe, Báwo ni ọ̀rọ̀ àkóso ìṣèjọba ṣe fẹ́ rí báyìí?

Jean-Luc Mélenchon, ọkan lara awọn olori oṣelu ni France

Oríṣun àwòrán, ANDRE PAIN/EPA-EFE/REX/Shutterstock

Ẹgbẹ oṣelu New Popular Front ti gbẹyẹ nibi idibo sile aṣofin apapọ lorilẹede France nibi ti wọn ti bori ibo ijoko aṣofin to pọ julọ.

Ninu esi idibo ti wọn kede lọjọ Aiku, ẹgbẹ oṣelu New Popular Alliance ni ijoko mejilelọgọsan, ẹgbẹ oṣelu Ensemble Alliance ni ijoko mejidinlaadọsan, National Rally + Allies ni ijoko mẹtalelogoje.

Republican right ni ọgọta ijoko ti awọn ẹgbẹ yooku si ko ijoko mẹrinlelogun to ku.

Amọṣa, bi esi idibo naa ṣe ri bayii, ko si eyikeyi ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta yii to ni iye ijoko to to lati le e da ijọba gbe kalẹ lai fara ti ẹgbẹkẹgbẹ.

Ni ipele akọkọ idibo naa to waye ni ọsẹ to kọja, ọpọ lo n woye pe ẹgbẹ oṣelu ti aarẹ orilẹede naa, Macron wa ni yoo moke, amọṣa ọrọ ko ri bẹẹ mọ lẹyin idibo naa bayii.

Ipo kẹta ni akojọpọ ẹgbẹ oṣelu ti Aarẹ Macron wa gbe ninu idibo naa pẹlu ida mọkanlelogun din diẹ ninu ọgọrun ti akojọpọ ẹgbẹ oṣelu New New Popular Front ko ida mejidinlọgbọn ninu ọgọrun.

Esi ibo yii fihan pe ko si eyikeyi ninu ẹgbẹ oṣelu yii to le da duro ṣe ijọba funrarẹ lai fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu miran.

Bawo ni agbekalẹ eto oṣelu France ṣe ri bayii?

Olotu ijọba France, Gabriel Attal

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lẹyin ikede esi idibo yii, iruju wa lori bi agbekalẹ ilana iṣejọba yoo ṣe duro lorilẹede France pẹlu bi ko ṣe si eyikeyi ninu akojọpọ ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta lorilẹede naa ṣe lee da ijọba ṣe pẹlu iye ibo ti wọn ni.

Nibayi, aarẹ orilẹede naa, Emmanuel Macron ti rọ olootu ijọba, Gabriel Attal pe ko ṣi ni suuru naa, ko si maṣe kọwe fi ipo rẹ silẹ niotir ati mu ki eto iṣejọba duro deede lẹyin esi idibo naa.

Lalẹ ọjọ Aiku ni olotu ijọba France, Gabriel Attal kede pe oun fẹ kọwe fi ipo silẹ ki aarẹ Macron to da igbesẹ naa nu bi omi iṣanwọ.

Labẹ ofin ilẹ naa, aarẹ ni yoo kede ẹni ti yoo jẹ olotu ijọba orilẹede naa lati ara akojọpọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ni ile aṣofin orilẹede naa. Ohun ti ẹgbẹ oṣelu National Popular Front n sọ bayii ni pe awọn fẹ fi orukọ eeyan ti awọn fẹ ni ipo olotu ranṣẹ sii titi di opin ọsẹ yii.