Ẹ fura o lórí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá! Ìpínlẹ́ 21 yóò kojú ẹ̀kún omi, àrùn Kọ́lẹ́rà sì lè pọ si - Ìjọba àpapọ̀

Aworan agbara ojo ni titi

Yatọ si awọn ipinlẹ mẹwaa ti akọsilẹ ti wa pe wọn ti koju omiyale ati iku ojiji latari ojo arọọda, ijọba apapọ Naijiria ti sọ pe ipinlẹ mọkanlelogun mi-in lo tun ṣee ṣe ki wọn koju iṣoro yii.

Bakan naa ni wọn ni aisan Kọlẹra to ti tan ka Naijiria le tun burẹkẹ si i pẹlu ojo to n rọ lọpọ igba naa.

Minisita fun ọrọ omi ati imọtoto, Ọjọgbọn Joseph Utsev, lo sọ eyi di mimọ niluu Abuja, l’Ọjọbọ, ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun 2024 yii.

Ọjọgbọn Utsev ṣalaye pe ajọ ‘Nigeria Hydrological Services Agency’, ti woye iṣoro yii tẹlẹ, wọn si ti fi atẹjade ikilọ sita loṣu kẹrin ọdun 2024 yii.

Ninu iwoye wọn ni wọn ti kede pe ipinlẹ mọkanlelọgbọn (31), ati ijọba ibilẹ mejidinlaaadọjọ (148) ni yoo koju iṣoro ẹ̀kun omi ju.

Awọn ipinlẹ naa ni Adamawa, Akwa Ibom, Anambra,Bauchi,Bayelsa, Benue, Borno, Cross River, Delta, Ebonyi, Edo, Imo, Jigawa, Kaduna, Kano, Katsina ati Kebbi.

Awọn mi-in ni Kogi, Kwara, Eko, Nasarawa, Niger, Ogun, Ondo, Ọsun, Ọyọ, Plateau, Rivers, Sokoto, Taraba ati Yobe.

Ẹ o ranti pe ile alaja meji lo dawo ni Mushin, ipinlẹ Eko lẹyin ojo nla to rọ l’Ọjọruu, ọjọ kẹta oṣu keje 2024.

Bakan naa ni agbara ojo ṣe gbe akẹkọọ kan lọ ni Ketu, l’Ekoo, ti idaamu ọlọkan-o-jọkan si ba awọn eeyan nigba ti omi gba gbogbo ọna, to ya wọle, ya wọ ṣọọbu to si ba ọpọ nnkan jẹ.

Àìsàn Kọ́lẹ́rà lè pọ̀ sí i

Aworan ile to wo latari arọọda ojo

Nigba to n kilọ lori aisan Kọlẹra, Minisita to n ri si ọrọ omi ati imọtoto naa sọ pe agbara ojo to n pọ yii le mu ki aisan Kọlẹra pọ si i lorilẹ-ede yii.

Bakan naa lo ni akunfaya awọn odo yoo bẹrẹ loṣu keje yii, yoo si kan awọn ipinlẹ bii Ondo, Kaduna, Anambra, Benue, Adamawa ati awọn ipinlẹ mejila mi-in.

Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Utsev ṣe wi, ninu ipinlẹ mọkanlelogun ti ẹkun omi yoo ti waye, o ti ṣẹlẹ ni mẹwaa ninu wọn bayii.

‘’ O ṣe pataki lati mọ pe ọwọ ojo yii n le si i, o si n rọ ju ti tẹlẹ lọ.

‘’Eyi yoo mu ki agbara ojo pọ, ki omi si maa yale. Bi eyi ba ti n ṣẹlẹ, aisan Kọlẹra to wa nita le maa lagbara si i’’ Bayii ni Ọjọgbọn Utsev wi.

Diẹ lara awọn agbegbe to ti koju omiyale ọhun bo ṣe sọ ni Kuje, Gwagwalada, Bwari ati Kwali ti wọn wa l’Abuja.

Awọn mi-in ni Anambra (Onitsha North); Edo (Benin); Benue (Makurdi); Kwara (Oke-Ero, Moro); Eko (Agege, Alimosho, Ikorodu, Erekusu Eko, Ikẹja, Eti-Osa); Ogun (Ijebu-Ode); Osun (Oriade); Nasarawa (Doma); Taraba (Takum, Sarduna); ati ipinlẹ Yobe.

Adágún odò Kainji

Adagun odo Kainji ati ti Jebba ti wọn wa nipinlẹ Niger ko ti i maa da omi sita bi aṣoju ijọba apapọ naa ṣe sọ.

Bakan naa lo ni adagun odo Shiroro to wa ni Kaduna pẹlu ṣi n da omi sinu akoto to maa n tọju omi si ni lasiko yii.

“ Nibi to de duro yii, o ṣe pataki lati mọ pe awọn odo naa maa kun jade, bẹrẹ lati ibẹrẹ oṣu keje ọdun 2024.

‘’Awọn ipinlẹ to ṣee ṣe ko kan ni Akwa Ibom, Anambra, Adamawa, Benue, Bayelsa,CrossRiver,Delta,Edo,Jigawa,Kogi, Kebbi, Kaduna, Niger,Nasarawa, Ondo, Ogun, Rivers, Taraba ati Abuja”

Utsev lo sọ bẹẹ.

Ninu gbogbo eyi ṣaa, igbọran san ju ẹbọ riru lọ lo fi pari alaye rẹ.