Ọwọ́ NDLEA tẹ Baálẹ̀ tó ń gbé igbó ní ìpínlẹ̀ Osun

Aworan Ige Babatunde

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Awọn oṣisẹ ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA ti fi ọwọ ofin mu Baalẹ ọkọ ilu kan to wa lati ipinlẹ Osun to n gbe igbo.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi lede sita fawọn akọroyin pe ọwọ tẹ Baalẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Ige Babatunde pẹlu egboogi ti iwọn rẹ to kilo marun un.

babafemi sọ pe “Ni Osun, olori ilu Akarabata niluu Ile Ife, Ba’ale Ige Babatunde , ẹni aadọta ọdun, ni ọwọ tẹ ni ọjọ karun un, oṣu Keje, ọdun 2024 pẹlu egbogi oloro to jẹ kilo marun un.”

Bakan naa ni Babafemi tun jẹ ko di mimọ pe ọwọ tẹ agunbanirọ, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Yusuf Abdulrahman pẹlu egbogi oloro ‘Loud’ to gbe pamọ ni ile awọn agunbanirọ ni Kano.

“Ni ọjọ kẹta ni ọwọ tẹ agunbanirọ, Yusuf Abdulrahman, ẹni ọdun mẹdọgbọn ni ile awọn agunbanirọ ni Sumaila pẹlu egbogi ‘Loud’”

Babafemi tun jẹ ko di mimọ pe awọn tọkọtaya kan to wọn ni okiki nidi iṣẹ egbogi oloro niluu Eko ni awọn ọmọ ogun NDLEA ya bo ile wọn.

O ni awọn egbogi oloro ti wọn wa ni iṣori A ni awọn ri lọwọ wọn.

Babafemi fikun pe apapọ kilo mẹwaa egbogi oloro ti iwọn rẹ jẹ bilọnu meji naira ni awọn ri gba lọwọ afurasi naa.

“Awọn ọmọ ogun NDLEA yawọ ile tọkọtaya kan ti orukọ n jẹ; Agbakoba John Mmadu ati Agbakoba Ijeoma Chinwe pẹlu amugbalẹgbẹ wọn , Okoye Ifeoma Maryjane, ti wọn ri awọn egbogi olori ti wọn ti pelo kalẹ lati gbe lọ si oke okun.

“Igbesẹ yii waye lẹyin ọpọ iwadii to ti n lọ labẹ lẹ fun ọjọ pipẹ lati mọ bi wọn se n gbe ogun wọle ati jade kuro lorilẹede Naijiria.

“Agbakoba John Mmadu, ẹni ọdun marundinlaadọta ni ọwọ tẹ lọna Ago Palace Okota, ti ọwọ si tẹ Agbakoba Ijeoma Chinwe, ẹni ọdun mọkanlogoji ati Okoye Ifeoma Maryjane, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni agbegbe Amuwo Odofin niluu Eko.”