Wo ààfin àti ọjà tí obìnrin kò gbọdọ̀ ṣí orí wọ̀ nílẹ̀ Yoruba

Àkọlé fídíò,
Wo ààfin àti ọjà tí obìnrin kò gbọdọ̀ ṣí orí wọ̀ nílẹ̀ Yoruba

Ni ipinlẹ Ondo, lara awọn ibi ti nnkan iṣembaye wa julọ ni ilu Owo.

Ti a ba n sọrọ nipa ilu Owo, lara awọn nnkan iṣẹmbaye, to tun jẹ agbaayanu ilu naa ni aafin Olowo jẹ.

Awọn iroyin kan sọ pe aafin naa ni aafin ọba to tobi julọ nilẹ adulawọ.

Eyi lo gbe ikọ ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba lọ siluu Owo, lati wo ẹwa ati bi aafin naa ṣe tobi to.

Ninu irinajo wa, a ba Olowo ti ilu Owo, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye Kẹta, to si ṣalaye pe ko si irọ ninu awọn iroyin naa.

A tun ṣalabapade agbẹnusọ Olowo, Ọgbẹni Samuel Adewale, to mu ikọ wa kaakiri aafin naa atawọn itan to wa nidi aafin ọhun.

Lara awọn gbagede ti a de ni oju ọna ti awọn Iloro, to ba Olowo wa lati Ile Ife maa n gba lasiko ọdun Igogo, Ako, nibi ti Olowo ti maa n sinmi lasiko ti ko ba fẹ ri alejo kankan.

A tun fi ẹsẹ kan Ugha Ẹyin Ode, eyi to jẹ gbagede nla ti Olowo ti maa n ba awọn araalu sọrọ lasiko apejọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Obinrin kii ṣi ori wọ aafin Olowo ati ọja Ọba

Lara awọn eewo to rọ mọ aafin Olowo ni pe, o ni awọn agbegbe kan ti awọn alejo kii de, paapaa lasiko ti wọn ba n ṣe oro ilu tabi lasiko ọdun Igogo.

Bẹẹ ni a tun gbọ pe obinrin kii ṣi ori wọ aafin Olowo, obinrin to ba fẹ wọ aafin gbọdọ we gele tabi ko lo eyikeyi ibori ko to wọ aafin naa.

Yatọ si aafin Olowo ti obinrin kii ṣi ori wọ, obinrin ko tun gbọdọ ṣi ori wọ Ọja Ọba.

Bo tilẹ jẹ pe ẹyin odi aafin Olowo ni ọja naa wa, wọn sọ fun wa pe ori ilẹ aafin Olowo ni wọn gbe Ọja Ọba naa kalẹ si.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti a ba bọ lati aafin Olowo ti ilu Owo.