‘Èèwọ̀ ni, nkò gbọdọ̀ f’ojú kan ìyá mi láàyè tàbí okú’

Àkọlé fídíò, ‘Èèwọ̀ ni, nkò gbọdọ̀ f’ojú kan ìyá mi láàyè tàbí okú’
‘Èèwọ̀ ni, nkò gbọdọ̀ f’ojú kan ìyá mi láàyè tàbí okú’

Nilẹ yoruba, gbogbo ilu kọọkan lo ni eewọ awọn nnkan ti wọn ko gbọdọ ṣe, paapaa fun awọn ọba.

Lara awọn ilu to wa nilẹ Yoruba ni Odo Owa, ilu kan ni ijọba ibilẹ Oke Ero, nipinlẹ Kwara.

Fun ọba alaye to ba jẹ niluu Odo Owa ti a n sọ yii, eewọ ni fun un lati fi oju ri iya to bi, yala ti iya naa ba wa laye, tabi nigba to ba ku.

Yatọ si eyi, eewọ tun ni fun ọba naa lati ri ọmọ tuntun ti iyawo rẹ ba bi, titi ọmọ naa yoo fi pe oṣu mẹfa.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Oloota ti ilu Odo Owa, Ọba Joshua Adegbuyi Adeyemi, Aniyeloye II, o sọ pe oun ni ọba keji to jẹ lori itẹ ilu naa, to ni iya laye nigba to jọba.

“Ni kete ti Oloota ba ti gun ori itẹ, eewọ ni ko gbọdọ fi oju kan iya rẹ laaye tabi to ba ku.”

O ni lati ọjọ ti awọn Iwarefa ti mu oun laarin oru, ti wọn si gba ọ̀já ti iya oun fi pọn oun lọwọ iya naa, ni awọn ti fi oju rira gbẹhin titi iya naa fi ku lọdun 2023.

Awọn eewọ to rọ mọ itẹ Oloota ko mọ bayii, Kabiesi Adeyemi tun sọ pe oriṣiriṣi ounjẹ ni oun ko le jẹ.

Bakan naa ni ko gbọdọ fi ọwọ kan ọkọ́.

“Botilẹ jẹ pe iṣẹ agbẹ la n ṣe niluu wa, nko gbọdọ fi ọwọ kan ọkọ. Ti mo ba ṣe bẹẹ, iṣẹ ati oṣi ni yoo ba awọn eeyan mi.

Ọba Aniyeloye II sọ pe ti oun ba ni agbara lati yi ohunkohun pada, oun yoo fi opin si ki ọba o ma maa ri iya rẹ.

“Idi ni pe, imọran obi ko le dabi ti ẹlomii.”