Halal àbí Haram? Wọ́n ti ibùdó ìtọ́jú omi ọyàn pa lẹ́yìn ẹ̀hónú àwọn ẹlẹ́sìn Islam

Oṣiṣẹ kan mu ike ti omi ọyan wa ninu rẹ jade lati inu ẹrọ amu nnkan tutu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan ọwọ òṣiṣẹ kan to gbe omi ọyan jade lati inu ẹrọ amunnkan tutu

Igbiyanju awọn eeyan kan ni Pakistan lati da ibudo ti wọn yoo maa ṣe omi ọyan obinrin lọjọ si lo ti foriṣanpọn bayii, lẹyin ti ijọ ẹlẹsin Islam kan lati Karachi lodi si i.

Ṣaaju ni awọn alfa kan ti kọkọ faramọ aba naa pẹlu awọn ofin kan, ṣugbọn nigba to ku ọjọ diẹ ti wọn yoo ṣi ibudo naa, wọn lawọn ko gba mọ.

Orilẹede Pakistan lo wa nipo karun-un ninu awọn ilu ti eeyan ibẹ pọ ju lagbaaye. Ṣugbọn gẹgẹ bi ajọ UNICEF si ṣe wi, ibẹ ni awọn ọmọde ti n ku ju ni Guusu Asia.

Awọn ibudo to n ṣetọju omi ọyan bi eyi ko ba ko ipa ribiribi laarin iku ati iye lorilẹde naa, nitori o jẹ ibi ti wọn ti le ri omi ọyan fun awọn ọmọ ti wọn bi lai pe oṣu mẹsan-an, ati awọn mii ti wọn ko ri ọyan iya to bi wọn mu.

Rahim ati Bashira iyawo rẹ, pẹlu ọmọ wọn obinrin to ni alaafia daadaa.

Oríṣun àwòrán, Rahim Shah

Àkọlé àwòrán, Rahim ati Bashira iyawo rẹ, pẹlu ọmọ wọn obinrin to ni alaafia daadaa.

Ìgbìyànju làti gbélé ayé

Obinrin kan, Bashira, padanu ọmọkunrin rẹ bo ṣe bimọ naa tan.

Eyi waye ni abule t'oun ati ọkọ rẹ n gbe ki wọn too ko wa si Karachi.

Nigba ti Bashira ati ọkọ rẹ, Rahim Shah, bimọ wọn keji to jẹ obinrin ni Karachi, niṣe lẹru n ba wọn pe ki ọmọ naa ma tun ku bii ti akọkọ.

Bashira ṣalaye fun BBC pe, "oṣu to yẹ ki n bimọ mi ko ti i pe ti mo fi bi i, awọn dokita si gba wa nimọran lati maa fun un lọmu.

"Ṣugbọn ọyan mi ko sẹ to." Eyi mu ki gbogbo ipa tọkọtaya to ṣẹṣẹ bimọ obinrin nigba naa pin.

" Inu ẹrọ ti wọn maa n gbe ọmọ ti oṣu rẹ ko ba pe si ni wọn gbe ọmọbinrin mi si ni yara itọju to lagbara.''

Oṣu meje ni oyun naa wa ti iya rẹ fi bi i, ọmu iya rẹ ko sẹ, bẹẹ ni wọn ko le fun un lounjẹ oniyẹfun inu agolo tawọn ọmọde maa n jẹ.

Rahim, ọkọ Bashira sọ pe, ''mo gbiyanju gbogbo agbara mi lati ri i pe ọmọ mi ye, obinrin kan toun naa n ṣofọ lọwọ ran wa lọwọ.

“ A n lọ lati ileewosan kan sikeji, nibẹ lati pade obinrin kan ti oun naa padanu ọmọ rẹ lẹyin to bimọ naa tan. A bẹ ẹ pe ko maa ba wa fun ọmọ mi lọyan, o si gba tayọtayọ'' Bashira lo ranti ọjọ to si ṣalaye bẹẹ.

Bi ko ba si ti obinrin to ba wa fun ọmọ mi lọyan ni, ọmọ naa ko ba ma ye, nitori o nilo omi ọyan lati fi ni agbara lati ṣẹgun àìsàn - Bẹẹ ni Rahim naa ṣalaye.

Ibùdó tí wọ́n ń tọ́ju omi ọyàn si

Aworan ti BBC fi ṣalaye ilana ipese omi ọyan

Ni ti Bashira, eeyan lo ba a fun ọmọ rẹ lọmu. Ṣugbọn ni ti eyi ti wọn n ṣe lọjọ sibudo itọju omi ọmu yii, eroja kan ti wọn gba lara eeyan ni wọn maa n ṣiṣẹ le lori, ilana itọju iṣegun oyinbo ni wọn maa n lo lẹyin ti wọn ba ti ṣayẹwo omi ọyan naa tan ti wọn si ti gbe e sinu ẹrọ amunnkan tutu.

Lẹyin naa ni wọn yoo maa fun awọn ọmọ ti wọn nilo omi ọyan ẹda eeyan mu.

Awọn orilẹede kan to jẹ musulumi lo pọju nibẹ, titi kan Malaysia ati Iran naa ni ibudo ti wọn n ṣe omi ọyan lọjọ si yii.

Ṣugbọn awọn olori ẹsin kan sọ pe igbesẹ naa lodi si ohun ti ẹsin Islam sọ nipa fifun ọmọ lọyan.

Ninu ẹsin Islam, igbagbọ wọn ni pe bi obinrin ti i ki i ṣe oun lo bimọ ba n fun ọmọ naa lọyan mu, yoo jẹ ko da bii pe ẹbi ni wọn, awọn ọmọ mii ti obinrin naa si fun lọmu yoo maa jẹ tẹgbọn-taburo pẹlu ọmọ ọlọmọ to fun lọmu naa ni.

Gbogbo ohun to ba wa ni ibamu pẹlu ẹsin Islam ni wọn n pe ni 'Halal', eyi to ba ta ko o ni wọn si n pe ni 'Haram'.

Ni Pakistan,awọn alfa kan ka ṣiṣe omi ọyan lọjọ sibi kan kun Haram, wọn ni ẹsin Islam ko faaye gba a.

Ṣugbọn awọn alaṣẹ ti ṣe ibudo naa lọna to ba ofin ẹsin Islam mu.

Minisita eto ilera lagbegbe kan niluu naa, Dokita Azra Pechuho, sọ fun BBC pe oun ti kọwe ranṣẹ si ajọ to n ri si awọn irori lọna ẹsin Islam lati fi da wọn loju pe obinrin le fun ọmọ lọyan lọna ti ẹsin Islam la kalẹ.

" Akọsilẹ yoo maa wa fun awọn obinrin to fi omi ọyan silẹ, eyi ti a maa pin laarin awọn obi awọn ọmọ wọnyi, ti yoo sọ iye ti kaluku fi silẹ. Dokita Pechuho lo sọ eyi di mimọ.

Afojusun rẹ ni lati yanju ọrọ naa, to bẹẹ ti iya to ba bi ọkunrin yoo maa fi omi ọyan silẹ fun ọmọkunrin nikan, awọn to ba si bi obinrin yoo fi tiwọn silẹ fun awọn ọmọbinrin nikan.

Eyi farapẹ ilana kan ti awọn onimọ ẹsin Islam kan gbe kalẹ ni Turkey lọdun 2012.

Aworan ọsibitu ti wọn ti n tọju awọn ọmọ ti wọn ba bi lai ti i pe oṣu mẹsan-an

Oríṣun àwòrán, Sindh Institute Of Child Health and Neonatology

Àkọlé àwòrán, Ibi yii ni wọn ti n tọju awọn ọmọ ti wọn bi lai ti pe oṣu mẹsan-an.

Ìdájọ́

Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 ni awọn ajọ ẹlẹsin Islam to lorukọ ni Karachi kọkọ faramọ idasilẹ ibudo omi ọyan naa, bo tilẹ jẹ pe pẹlu awọn ofin kan ni.

Lara awọn ofin naa ni pe wọn gbọdọ fi orukọ awọn to fẹẹ fi omi ọyan ọhun silẹ fawọn ti wọn yoo gba a fun ọmọ wọn.

Wọn tun ṣofin pe wọn ko gbọdọ fun ọmọ ti ki i ṣe musulumi lomi ọyan obinrin to ba jẹ musulumi mu.

Wọn ko gbọdọ gbowo. Awọn ọmọ ti wọn ba bi ki oṣu mẹjọ too pe ni wọn lẹtọọ lati gba omi ọyan yii, bi iya wọn ko ba si le fun wọn lọyan nikan ni.

Ofin Pakistan ni pe ofin Sharia jẹ dandan fun awọn ofin yooku ati ẹka gbogbo lati tẹlẹ.

Nigba ti awọn alaṣẹ ibudo omi ọyan naa ti gba pe awọn yoo tẹle ofin wọnyi, ẹka ẹsin kan ni Karachi ni ko da awọn loju pe yoo ri bẹẹ.

Idajọ ti wọn gbe kalẹ lọjọ kẹrindinlogun,oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii sọ pe yoo ṣoro ki awọn alaṣẹ ibudo omi ọyan yii too le tẹle ilana ofin ẹsin Islam.

Eyi lo mu ajọ 'Sindh Institute of Child Health and Neonatology'(SICHN) sọ pe ko si ọna miran mọ ju kawọn jawọ ninu eto naa, lẹyin tawọn ti gba idajọ lati ọdọ Darul Uloom Karachi, ajọ ẹlẹsin Islam kan.

“Lati asiko yii lọ, a o maa beere itọsọna lori ọrọ yii lọwọ Darul Uloom Karachi ati ajọ Council of Islamic Ideology,” Bẹẹ ni ile itọju olomi ọmu naa wi.

Wọn fi kun un pe ilana itọju oyinbo nikan kọ lawọn gba fun, awọn gbọdọ fi ti ẹsin Islam naa ṣe gidididi.

Aworan obinrin Pakistan kan to n fun ọmọ rẹ lọyan niwaju ile onibiriki kan

Oríṣun àwòrán, Unicef

Àkọlé àwòrán, Omi ọyan aa maa mu ọmọ dagba daadaa

Omi ọyàn

Gẹgẹ bi ajọ UNICEF ṣe wi, ọmọ ikoko mẹrinlelaaadọta (54) ninu ẹgbẹrun kan (1,000) lo maa n ku ni Pakistan.

Orilẹede naa si n gbiyanju lati mu onka naa walẹ si mejila nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030.

Omi ọyan maa n fun ọmọde lagbara lati koju aisan, o si tun maa n fun wọn lokun, bẹẹ lo n mu wọn dagba.

Ajọ ilera agbaye, WHO, sọ pe awọn ọmọde to ju 820, 000, ti wọn ko ti i to odun marun-un le yè bi wọn ba ri ọyan mu daadaa laarin oṣu akọkọ si ọdun keji wọn.

Ṣaa, UNICEF to ṣagbatẹru eto yii ko sọ nnkan kan le e lori.

Ni 2018, Ajọ Ilera Agbaye, WHO ati UNICEF, sọ pe bi awọn ọmọ ko ba ri ọyan iya tiwọn mu, ko ṣaa jẹ pe ọyan eeyan mi-in ni wọn n mu.

Bakan naa ni awọn ẹka ilera lorilẹedde Amẹrika ati Europe naa dabaa pe awọn abani-fun-ọmọ lọyan daa lati ni.

Kò sófin tó de ọ̀rọ̀ omi ọyàn

Ajọ WHO sọ pe o ju orilẹede ọgọta lọ ti wọn ni ibudo itọju omi ọyan. Ṣugbọn atako awọn ẹlẹsin lori rẹ ko yingin, wọn ko gba.

Ni 2019, wọn da ibudo itọju omi ọyan kan silẹ ni Bangladesh, laarin oṣu kan pere ni wọn ti i pa pada nigba ti awọn ẹlẹsin tako o .

Iwadii kan ti wọn ṣe ni ''American Academy of Paediatrics, fi han pe awọn idile ẹlẹsin Islam maa n lọra lati fun ọmọ wọn lomi ọyan bi eyi mu, nitori wọn ko mọ awọn to ni i.

Titi dasiko yii ni ko ti i si alakalẹ kan lori ọna ti wọn yoo fi maa gbe ibudo omi ọyan kalẹ. Ajọ WHO ṣẹṣẹ bẹrẹ si i ṣiṣẹ lori rẹ ni.

Ni ti Pakistan yii naa, ohun ti yoo ṣẹlẹ si i ko ti i ye ẹnikẹni.

Ṣugbọn bi a ba pada si Karachi, lọdọ Bashira ati ọmọ rẹ, ọmọ naa ti n rin daadaa bayii, o si ni alaafia to peye. Ọpẹlọpẹ ọna ti wọn gbe tiwọn gba, eyi ti ileewosan to bawọn wa oluranlọwọ jẹ ko ṣee ṣe.

Bashira paapaa n foju sọna de ọjọ toun naa yoo le ran awọn iya mi-in lọwọ.

" Titi aye ni n o maa dupẹ fun ẹni to ba mi fun ọmọ mi lọmu, to ba si di lọjọ iwaju, temi naa ba ni anfaani lati san oore yii pada lati gba ẹmi ọmọ yoowu la, emi naa yoo ṣe bẹẹ fun un''

Bayii ni Bashira wi.