Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé lórí ẹ́jọ́ tó ń tako yíyọ Soun Ogbomoso lóyè

Aworan Ọba Ghandi ati ile ẹjọ

Ile ẹjọ kọtẹmilọrun to n bẹ ni agbegbe Adeọyọ niluu Ibadan, ti sun igbẹjọ to yẹ ko waye lonii laarin Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Ghandi Loye ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde siwaju.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro to ṣoju igun mẹtẹẹta ni adajọ ile ẹjọ naa, Arabinrin Y.B Nimpar kede pe, ile ẹjọ ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkọkanla, oṣu kọkanla ọdun yii.

Agbẹjọrọ agba to ṣoju Ọba Ghandi nile ẹjọ naa, Mallam Yusuf Ali, SAN, ṣe alaye fun akọroyin BBC Yoruba pe igbaradi saaju idajọ ti yoo waye l'opin ọdun yii, ni awọn wa ṣe lonii.

Igbiyanju lati ṣe afọmọ gbogbo eri ti wọn ko wa, lo si mu ki wọn tun fi ara han nile ẹjọ naa.

Ile-ejo kotemilorun n'Ibadan

Ọpọlọpọ awuyewuye lo rọ mọ iyansipo Ṣọun Ogbomọṣọ ki o to di pe Ọba alade naa gun ori aleefa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, awọn igun kan ninu idilẹ Laoye lo kọkọ pe ẹjọ tako Ọba Ghandi Laoye, pẹlu ẹsun wi pe kii ṣe ojulowo ọmọ oye.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ nipasẹ Gomina ��eyi Makinde naa pe ẹjọ tako idile Laoye lori ẹsun ti wọn fi kan Ṣoun Ogbomọṣọ.

Bakan naa ni Ọba Ghandi pe ẹjo kotẹmilọrun tako awọn ẹsun ti mọlẹbi kan an. Eyii lo mu ki awọn ẹjọ kotẹmilọrun naa pe meji ọtọọtọ.

Ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii ni a o mọ ibi ti ọrọ naa yoo yọri si.

Àkọlé fídíò, Wo báàgì tó ń lo ìtànṣán oòrùn, ó tún ní páàdì nǹkan oṣù fáwọn ọmọdébìnrin

Ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ tó rọ Soun Ogbomoso lóyè, bẹ̀rẹ̀ lónìí

Aworan Soun Ogbomoṣo

Oríṣun àwòrán, OLALEYE OLAWUYI PETER/FACEBOOK

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba ipinlẹ Oyo pe tako idajọ ile ẹjọ to rọ Soun ilu Ogbomosho, Oba Ghandi Afolabi Olaoye, ni yoo bẹrẹ lonii ọjọ kẹrin oṣu Keje nile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Ibadan.

Yatọ si ẹjọ kọtẹmilọrun yii, ijọba tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ maṣe gba ki wọn yọ ori ade ọhun loye titi ti yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn pe.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Kabir Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.

Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan nipinlẹ lori idajọ to gba ade Ọba lori Soun tuntun.

Ipẹjọ yii ni agbẹjọro ijọba ti fa koko mẹfa yọ ninu eyii to ti tako idajọ ile ẹjọ akọkọ.

O ni awọn ẹri to wa nilẹ tako idajọ to waye pe Ghandi ko yẹ loye Soun ilu Ogomosho.

Lara awọn ti ijọba pe lẹjọ kotẹmilọrun yii ni agbẹjọro Oladapo Atanda, ijọba ibilẹ ariwa Ogbomosho ati igbimọ afọbajẹ Ariwa Ogbomosho.

Awọn to ku ni agbẹjọro S.A. Mohammed, ileeṣẹ Mohammed & Mohammed & Co., Mobolaji Chambers, Kola Fatoye, Oloye Samuel Otolorin, Oloye Salawu Ajadi, Oloye Tijani Abioye, Oloye David Adeniran Ojo, atawọn mii.

Ki lo de ti adajọ fi wọgile iyansipo Soun Ọba Ghandi Olaoye?

Ọmọọba Kabir Olaoye to pe ẹjọ tako iyansipo Ghandi salaye pe aise-deede wa ninu ilana ti wọn fi yan an.

O wa n rọ ile ẹjọ naa lati wọgile iyansipo kabiyesi Olaoye, ko si pasẹ fun awọn afọbajẹ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye miran.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adedokun to n gbọ ẹjọ naa kede pe iyansipo ọba Laoye ko ba ofin mu.

Bakan naa lo pasẹ pe ki awọn afọbajẹ lọ bẹrẹ ilana ọtun lati yan Soun tuntun

Saaju ni Adajọ Adedokun ti wọgile ẹbẹ mẹta ti ọkan ninu awọn olupẹjọ, Ọmọọba Adeyemi Taofiq Akorede Laoye gbe siwaju rẹ.

Awọn ẹbẹ naa loun naa fi n pe iyansipo oriade tuntun naa nija.

Bi ile ẹjọ ṣe rọ mi loye ko tọna - Soun

Oba Ghandi Olaoye náà korò ojú sí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga tó rọ̀ ọ́ lóy��.

Ó ní òun kò faramọ́ ìdájọ́ tí Adájọ́ Adedokun dá láti gba ẹ̀sùn tí ọmọọba Kabir Olaoye fi kan òun wọlé.

Ó ṣàlàyé pé Adájọ́ Adedokun kò da ẹjọ́ náà dáadáa bó ṣe kéde pé ìyànsípò kò bá ìlànà jíjẹ Soun Ogbomoso mú.

Aworan Soun Ogbomoṣo

Ààfin Ogbomoso ti rọ àwọn ènìyàn ìlú náà láti fi ọkàn balẹ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga.

Ẹnìkan ní ààfin tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ òun ní àwọn máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti tako bí ilé ẹjọ́ ṣe yọ Ọba Ghandi Olaoye nípò Soun Ogbomoso.

Ó ní ṣáájú ni ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ pé ìlànà tí wọ́n fi yan Ọba Ghandi tọ̀nà nígbà tí ọmọba kọ́kọ́ pé ẹjọ́ àti pé ejò lọ́wọ́ nínú tí ilé ẹjọ́ náà bá tún yí ohùn padà.

Ó fi kun pé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ló máa bá àwọn tán ìmọ́lẹ̀ sí gbogbo àwọn nǹkan tó tá kókó lórí ẹjọ́ náà.

Ó wa pàrọwà sí àwọn ènìyàn láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀ àti pé dídùn ni ọsàn máa so fún àwọn ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

Aworan iwe ipẹjọ

Oríṣun àwòrán, Others

Aworan iwe ipẹjọ

Oríṣun àwòrán, Others