Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko pa ajínigbé mẹ́sàn án, gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró

Lagos

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣekupa awọn afurasi ajinigbe mẹsan an nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Benjamin Hundeyin fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Ẹti lo ti sọ bẹẹ.

O ni latari ọfintoto awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, awọn ti bẹgi dina erongba awọn ajinigbe ọhun lati ji eeyan pataki kan gbe lagbegbe Ladipo.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu Keje yii ni awọn da awọn ajinigbe naa lọna, nibi ti wọn ti ṣina ibọn funra wọn, ti iro ibọn si n dun lakọlakọ.

Lagos

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Hundeyin ni ṣaaju ni kọmiṣọna ọlọpaa, Adegoke Fayoade, ti kọkọ paṣẹ iṣẹ ọhun lẹyin ti wọn gbọ pe awọn ajinigbe naa yoo ṣọṣẹ.

Eyii lo mu ki wọn maa ṣọ ikọ ajinigbe ọhun lojulẹsẹ lọna ati dena wọn lasiko ti wọn ba lọ ṣọṣẹ.

Lasiko ti awọn ọlọpaa atawọn ajinigbe naa kọju ija sira wọn, ọlọpaa pa mẹsan an ninu wọn, nigba ti meji ninu wọn moribọ, bo tilẹ jẹ pe wọn fara gbọta ibọn.

Lara awọn ohun ti ọlọpaa gba lọwọ awọn ajinigbe naa ni ọpọlọpọ ohun ija oloro, ninu eyi ti AK47 atawọn ibọn ilewọ mii wa, to fi mọ erọ POS, ọta ibọn, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota 4Runner dudu ati ọkọ Lexus RX350 alawọ buluu.

Hundeyin ni o ti to oṣu mẹjọ ti awọn ti n wa awọn afurasi naa lẹyin ti wọn ṣọṣẹ lawọn agbegbe bii Okota, Ejigbo ati Ladipo.

Alukoro ọlọpaa ọhun sọ siwaju si pe, iṣẹ awọn ajinigbe naa ti dopin bayii ti awọn ti rẹyin wọn.

O pari ọrọ rẹ pe ọpọ aṣeyọri ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti ṣe lẹnu lọlọ yii lati daabo bo araalu.