'Architecture ni mò kọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga àmọ́ iṣẹ́ aṣọ híhun ni mo yàn láàyò'

Àkọlé fídíò,
'Architecture ni mò kọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga àmọ́ iṣẹ́ aṣọ híhun ni mo yàn láàyò'

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní àtẹ́lẹwọ́ ẹni kìí tanni jẹ.

Èyí ló dífá fún arábìnrin yìí, Bolade Mayowa Kolade tó máa ń hun aṣọ tà.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lóde òní, Bolade lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga níbi tó ti kọ́ nípa ìmọ̀ Architecture àmọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ló yàn láàyò láti máa fi jẹun.

Ó ṣàlàyé pé láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa fi òwú dára láti fi ṣe oríṣiríṣi nǹkan.

Ó ní lẹ́yìn ìgbà tóun dàgbà tí òun parí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ni òun bẹ̀rẹ̀ láti mú iṣẹ́ náà ní òkúnkúndùn.

Ó sọ pé àwọn ará ilé, ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí òun tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà lọ́wọ́ òun nígbà tí òun kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ tó sì ti di iṣẹ́ ńlá tí òun ń fi ṣe iṣẹ́ ṣe.

Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan ni òun máa ń hun bíi báàgì, aṣọ, fìlà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bolade ní òun kìí lè sọ níta pé iṣẹ́ aṣọ híhun ni òun ń ṣe nígbà tí òun kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n nígbà tó yá tí òun ri pé iṣẹ́ náà tó láti jókòó tì ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ní so fún àwọn ènìyàn pé iṣẹ́ tí òun ń ṣe nìyí.