Ìyàlẹ́nu ló ṣì n jẹ́ fún mi bí Nàíjíríà ṣì ṣe dúró pẹ̀lú adúrú owó tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ti jí gbé – Alága EFCC

Aworan Ola Olukayode, Alaga EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Alaga ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ lorileede Naijiria, EFCC, Ọla Olukayọde, ti sọ pe iyalẹnu nla lo maa n jẹ fun oun nigba ti oun ba n ri iye owo tawọn eeyan ti ko jẹ lati ipasẹ iwa ajẹbanu, ti orileede Naijiria tun ṣi ṣe duro bo ti duro yii.

Olukayọde ni bi awọn araalu ba ri awọn iwe ẹsun owo to nii ṣe pẹlu owo kikojẹ, omije yo jabọ loju wọn.

Alaga EFCC lo sọrọ yii lasiko to n gba igbimọ iṣakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ pinpin owo ilu ati ina nina lorileede yii, RMAFC ti Mohammed Shehu jẹ alaga wọn lalejo laipẹ yii.

Nibẹ lo ti sọ pe iwa ajẹbanu nipa owo ijọba kikojẹ lo jẹ eyi to ga julọ ninu ohun to fa iwa jibiti lorileede Naijiria ati pe bi wọn ba yọ owo ijọba kikojẹ kuro, orileede yii yoo dara sii.

Nigba to n sọrọ, o ni “Nigba ti mo ba n wo awọn iwe ẹsun, ti mo si n ri iye owo nla-nla ti awọn eeyan n jigbe, o maa n ya mi lẹnu bi a ṣe n duro gẹgẹ bi orileede.

Bi ẹ ba ri awọn iwe ẹsun kan, ẹ maa sunkun.

Olukayode tẹsiwaju pe “Bi ẹ ba ri bi wọn ṣe n dari awọn owo ipinfunni ranṣẹ sinu apo aṣuwọn aladani lawọn ile ifowopamọ kan laarin oru, lẹyin ipade eto iṣuna, o maa ya yin lẹnu nipa ẹmi to n dari wa gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.

“Bi ki eeyan di ipo oṣelu mu fun ọpọ ọdun, ki ẹ si pe e wi pe ko wa ṣe akọsilẹ bo ṣe na awọn owo kan, ti iru ẹni bẹẹ si maa sọ rara, oun ko ni wa ṣe kọsilẹ kankan, eyi ko le jẹ itẹwọgba.”

Siwaju sii ni Olukayọde sọ pe niṣe lo yẹ ka ni inu ati ọkan mimọ pẹlu iwa ọmọluabi ninu eto oṣelu ati ẹka aladani bi a ba n fẹ itẹsiwaju ati idagbasoke orileede.

Olukayọde ni iwa ajẹbanu di ipo nla mu ninu awọn adojukọ to n ba orilede yii finra, pẹlu ileri wi pe didena awọn ọna ti awọn alakoso n gba kowo jẹ ni ileeṣẹ wọn yoo bojuto lati rii pe awọn araalu n lọ si ipo oṣelu lati ṣe ojuṣe wọn lọna to tọ.

“Agbekalẹ ọna lati gbogun ti iwa jibiti yoo mu ipa rere wa. Fun idi eyi, EFCC ti wa ni ẹka kan ti a pe ni Department of Fraud Risk and Assessment and Control, eyi ti yoo maa tọpinpin iwa jibiti.

“Ẹ jẹ ka wo ilana eto ipawo-wọle wa. Ilana naa jẹ eyi to mẹhẹ to si faaye silẹ fun nina owo ninakuna. Bi a ko ba wo ilana yii daadaa, ojiji lasan la kan ma maa le.

“Kii ṣe pe a kan maa ṣewadi, ka si gba pada nikan, ohun ti a pinnu lati ṣe nileeṣe wa ni pe lati ṣagbeyẹwo ilana. Bi a la le di awọn ibi ti owo ti n jo danu yii, ka si ni ida aadọta ninu owo ti a fi n gbe iṣẹ jade ni Naijiria, orileede yii yoo dara.”