Hijrah: Kí ni pàtàkì ọdún tuntun yìí fún àwọn mùsùlùmí

Aworan awọn musulumi to n gba adura

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun Hijrah jẹ ọdun kan to ṣe pataki pupọ fun awọn musulumi jakejado agbaye.

Awọn ipinlẹ kan loriẹede Naijiria ti kede isinmi lẹnu iṣẹ lati fun awọn Musulumi lanfani lati ṣe ajọyọ ajọ naa de gongo.

Hijirah ọdun yii jẹ wiwọ ọdun 1446 fun awọn Musulumi.

Iyatọ to wa laarin ọdun musulumi ati ọdun yooku ni pe wọn ko kii ṣe e papọ pẹlu awọn yooku ati pe orukọ wọn yatọ.

Bakan naa ni awọn Gomina ti kesi awọn araalu lati lo asiko ajọyọ fi gba adura fun ifọwọsowọpọ ati igbagbe alaafia fun orilẹede Naijiria.

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ninu atẹjade kan ti olubadamọran rẹ, Sulaiman Olarenwaju rẹ buwọlu fun awọn akọroyin rọ gbogbo musulumi lati ma gba adura fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Ki ni a n pe ni Ọdun Musulumi ati pe ki ni pataki rẹ.

Ọdun Hijirah ti wa ṣaaju ki wọn to Anọbi Muhammad (SAW) ṣugbọn wọn ko lo awọn oṣu lasiko naa.

Lilo awọn oṣu ninu ọdun musulumi bẹrẹ lẹyin ti Anọbi gbera kuro lati ilu Mecca lọ Medina lorilẹede Saudi Arabia.

Idi ree ti wọn fi pe ọdun to pari 1445 AH (AH tumọ si ọdun 1445 lẹyin ti Anọbi rin irinajo).

Oṣupa wiwo ni ẹṣin Islam fi n wo asiko, ko si nkankan ninu awọn oṣu musulumi ti ọjọ rẹ pe bii ti ọdun Gregorian.

Awọn musulumi maa n ṣe ajọyọ irinajo Anọbi Muhammad (PBUH) lati Makkah lọ Medina.

O ṣe koko fun awọn musulumi nitori o n jẹ ki wọn ní oye sii nípa Ibẹrẹ ẹṣin Islam ati bi o ṣe di ọkan gboogi.

Lọjọ kini oṣu Muharram, awọn ko ni ọjọ kan fun ijọsin ṣugbọn o duro gẹgẹ asiko lati ranti irinajo Anọbi ati ilakọja rẹ.

Gbogbo Musulumi ni wọn ma n rọ lati gba awẹ ati adura lọjọ kini ọdun.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa oṣu Muharram

Oṣu Muharram ni oṣu akọkọ, ti wọn si tun ma pe ni oṣu Al Hijiri

Iye ọjọ to wa ninu oṣu yii maa n yi si ara wọn. Nigba miran o le jẹ Ọjọ mọkandinlọgbọn, o si tun le jẹ ọgbọn ọjọ ni yoo wa ninu oṣu yii.

Awọn Musulumi gbọdọ gba awẹ lọjọ kẹsan an ati ikẹwaa oṣu yii ti wọn n pe ni Tashua ati Ashurah.

Oṣu yii kọ awọn Musulumi ni igboya ati jija fun idajọ òdodo.

Oṣu Ewọ ni oṣu Al Muharram ti awọn musulumi yoo si yago fun ayẹyẹ lati le ṣe apọnle fun Imam Hussain.