"Kò yẹ kí àwọn èèyàn máa sanwó gege láti mí afẹ́fẹ́, ẹ mú àdínkù bá owó ‘Inhaler’"

Àkọlé fídíò, High Cost Of Drugs: Aláìsàn ikọ́ sémìí-sémìí ní láìsí Inhaler, òun kò le gbé ayé
"Kò yẹ kí àwọn èèyàn máa sanwó gege láti mí afẹ́fẹ́, ẹ mú àdínkù bá owó ‘Inhaler’"

Owo gbogbo eroja lo l soke ni orilẹede Naijiria paapaa oogun oyinbo ta awọn eeyan n lo fun ilera wọn.

Owo awọn oogun naa lo lọ soke fiofio, eyi to nira fun ọpọ eeyan lati ri owo ra.

Pabambari rẹ ni ti owo ẹrọ ti awọn eeyan to ni aisan semi-semi (ASTHMA) fi maa n mi afẹfẹ, ti ọpọ eeyan mọ si Inhaler, eyi to fo kọja agbara awọn eeyan to ni aisan naa.

Eyi si lo mu ki awọn eeyan kan maa fi apa janu pe owo ti wọn n ta Inhaler naa ti pọju, o si yẹ ko jẹ ọfẹ ni.

BBC wa se iwadii nipa idojukọ ti awọn alaisan semisemi n la kọja lasiko ti owo Inhaler lọ soke yii.

Obinrin to n mi Inhaler

"Ventolin ni mo maa n lo tẹlẹ amọ nigba ti oogun naa ti di ẹgbẹrun mẹsan Naira, agbara mi ko lee gbe mọ"

Ọkan ninu awọn alaisan semisemi to ba BBC sọrọ ni ọmọ ọdun mẹẹdogun ni oun wa nigba ti asisan naa bẹrẹ.

O ni alase ni oun, to maa n lọ lati se ounjẹ nibi ariyaoun maa n mi fun wakati meji pẹlu ẹrọ Inhaler yii.

Bakan naa lo salaye pe oun tun maa n gba bọọlu amọ oun pa bọọlu gbigba ti nitori aisan semisemi naa.

"Ventolin ni mo maa n lo tẹlẹ amọ nigba ti oogun naa ti di ẹgbẹrun mẹsan Naira, agbara mi ko lee gbe mọ.

Idi ree ti mo se n lo Inhaler amọ agbara mi ko ka owo Inhaler naa mọ nitori pe o ti wọn ju."

O wa n gbarata pe ko tii ye oun nipa ọna ti oun yoo gba gbe ile aye pẹlu bi owo Inhaler se n lọ soke fiofio yii.

"Lai si Inhaler, n ko le gbe ile aye"

Ọmọde to n mi Inhaler ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"A ti n ko owo jọ lati se iranwọ fun ipese Inhaler fun awọn alaisan semisemi"

Bakan naa, awọn eeyan mii to tun ba BBC sọrọ salaye pe o yẹ ki ijọba maa pin ẹrọ Inhaler ni ọfẹ ni, fun awọn eeyan to ni aisan semisemi.

"Ko yẹ ki awọn eeyan maa san owo lati mi afẹfẹ, o yẹ ki ijọba maa pin Inhaler fun wọn ni ọfẹ ni.

Amọ ni bayii, a ti n ko owo jọ, ti a si tun n beere atilẹyin owo lọdọ awọn ileesẹ nlanla ati ẹnikọọkan.

Owo yii ni yoo se iranwọ lati pese Inhaler fun awọn alsian semisemi.

A tun n fẹ ki ijọba se iranwọ nidi lila awọn eeyan to wa ni abule ati ẹsẹkuku lọyẹ nipa aisan semisemi.