Ọmọ ogun 25 gba ìdájọ́ ikú torí wọ́n jẹ́ ojo tó sá lójú ogun

DR Congo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọmọ ogun marundinlọgbọn ti gba idajọ iku ni Democratic Republic of Congo latari bi wọn ṣe sa loju ogun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn M23.

Wọn tun fẹsun ole jija kan awọn ologun naa lẹyin ti wọn ji ọja ninu awọn ṣọọbu kan lasiko ti wọn fi ipo wọn silẹ loju ogun.

Ile ẹjọ ọhun da iyawo mẹrin ninu awọn afurasi naa silẹ lori ẹsun pe wọn gba ọja ti ọkọ wọn ji ninu ṣọọbu oniṣọọbu.

Agbẹjọro awọn ologun naa, ti meji ninu wọn jẹ ọgagun ti sọ pe, oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun.

Yatọ si awọn marundinlọgbọn to gba idajọ iku, ẹnikan ninu wọn ri ẹwọn ọdun mẹwaa he, nigba ti ile ẹjọ naa ni ki ẹnikan maa lọ sile rẹ layọ ati alafia.

"Nnkan ija oloro tawọn ọmọ ogun M23 dara ju ti ọmọ ogun ijọba lọ"

Ninu oṣu Karun un ọdun yii ni ile ẹjọ kan niluu Goma, lorilẹede yii kan naa, ṣedajọ iku fun ọmọ ogun mẹjọ lori ẹsun pe wọn sa kuro loju ogun ati pe wọn jẹ ojo.

Awọn ologun mẹjọ naa ti pe ẹjọ kotẹmilọrun.

Wayi o, awọn ọmọ ogun M23 to n da DR Congo laamu ti gba awọn ilu nla to ṣe koko bii Kanyabayonga.

Ẹwẹ, ijọba ilẹ naa ti fẹsun kan orilẹede Rwanda, to jẹ alamuleti rẹ pe o n ṣatilẹyin fun M23 ọhun.

Laarin ọsẹ diẹ sẹyin, ko din ni nnkan bii 150,000 araalu to sa fi ile wọn silẹ latari ija to n waye laarin ọmọ ogun ijọba atawọn ọmọ ogun M23.

Ajọ UN atawọn orilẹede kan nilẹ adulawọ ti fi ọmọ ogun sọwọ si DR Congo lati koju M23.

Ṣugbọn iroyin ni nnkan ija oloro ọwọ awọn ọmọ ogun M23 naa dara ju ti ọmọ ogun ijọba ilẹ naa lọ.