Ẹni tó bá ti ṣíwọ́ ọmọbíbí, yóò máa gba owó lọ́wọ́ ìjọba ní ìlú yìí

Awọn eeyan ni Japan

Ofin kan ti waye lorilẹede Japan bayii, eyi to kede pe wọn yoo maa sanwo fun awọn eeyan ti wọn ti da ọmọ bibi duro.

Kootu to ga julọ ni Japan lo ṣofin ọhun fun eeyan ti iye wọn to ẹgbẹrun mẹrindinlogun (16,000) ti wọn ko le bimọ mọ.

Eyi waye latari bo ṣe jẹ ijọba ilu naa lo gbe igbesẹ ai ni i bimọ mọ fawọn eeyan ilu yii lati ọdun pipẹ.

Masayo Fururi, ẹni ti wọn ti fipa mu lati ma bimọ mọ, fi idunnu rẹ han lori ofin tuntun yii

Ki i ṣe pe awọn ti wọn jẹ nipa naa fẹ bẹẹ, ṣugbọn ijọba lo agbara lorii wọn.

Igbesẹ ti wọn pe ni ‘involuntary sterilzation’ naa ni wọn fipa ṣe fun wọn, titi de ori awọn eeyan ti aisan ọpọlọ n da laamu.

Ṣugbọn ni bayii, ile-ẹjọ to ga julọ lorilẹede naa sọ pe awọn eeyan ti ọrọ naa kan ti ni anfaani lati beere owo lori ohun ti wọn ṣe fun wọn.

Iya agbalagba ẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71) Masayo Fururi, ẹni ti wọn ti fipa mu lati ma le bimọ mọ, fi idunnu rẹ han lori ofin tuntun yii.

O ni, ‘’Inu mi dun si eyi, aadọta ọdun sẹyin ree ti mo ti n ja fun ẹtọ mi to wa lọwọ ijọba lori ohun ti wọn ṣe fun mi. Igba yii nijọba ṣetan lati bẹbẹ fun aforiji.’’

Ṣaa, omi tuntun ti ru bayii, awọn ẹni ti wọn jẹ nipa yoo maa gba ẹtọ to tọ si wọn.