Ìjálá, Ògèdè àti Ọfọ̀ ni a fi ń rọ́nà fún ooni, kí ẹ̀mí burúkú lè yàgò fún wa lọ́nà - Oníjàálá Ooni

Àkọlé fídíò, Onijala: Ooni kìí sùn bíí àwa èèyàn lásán, àágùn ara mi ni mo fi mọ̀ pé ó ti paradà
Ìjálá, Ògèdè àti Ọfọ̀ ni a fi ń rọ́nà fún ooni, kí ẹ̀mí burúkú lè yàgò fún wa lọ́nà - Oníjàálá Ooni

Awọn Onilu, Onirara, Akewi ati Onijala jẹ awọn eeyan ti alejo yoo kọkọ fi oju kan lawọn aafin to wa nilẹ Yoruba.

Ipa ti awọn eeyan yii si n ko ninu aafin naa ati agbelarugẹ asa Yoruba ko se e fi oju tẹmbẹlu rara.

Lara wọn si ni ọkunrin to maa n sun Ijala fun Ooni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi ati awọn babanla rẹ to ti jẹ saaju wa.

Ki wa ni ojuse Onijala yii ni aafin Adimula tilẹ Yoruba? Awọn ọna wo lo n gba gbe asa ati ise ilẹ Yoruba larugẹ?

Ki lo de ti Onijala naa fi maa n tẹle Ooni kaakiri ilu tabi orilẹede to ba n lọ, ki si ni pataki Ijala to n sun yii se jẹ ninu igbe aye Ooni ati isesi rẹ ni ojoojumọ?

Ọna lati wa idahun si awọn ibeere wọnyii, lo mu ki BBC Yoruba morile ilu Ile Ife lati ba Oloye Omisore Lateef Oyewale, tii se Onijala Ooni Adimula sọrọ.

Onijala Ooni n kunlẹ ki Ooni

“Oogun gbọdọ jade lara mi ti mo ba n ki Ooni, eyi ni yoo sọ fun mi pe Kabiyesi ti parada lori ibusun”

Nigba to n gbalejo BBC Yoruba, Oloye Omisore ni ki oye to la, ni owurọ kutukutu, ka to ri atẹlẹwọ ni idaji, ni oun yoo ti gbera kuro nile oun, lati maa lọ si aafin, lọ fi Ijala ji Ooni.

“Lati ile mi ni maa ti maa ki Ooni bọ, oogun si gbọdọ jade lati ara mi ti mo ba n ki Kabiyesi, eyi si ni yoo jẹ ki n mọ pe Ooni ti parada lori ibusun rẹ.

Bẹrẹ lati aago mẹfa owurọ, ni maa ti maa fi Ijala pe Ooni, maa maa pe wọn kikankikan, mo si gbọdọ lo, o kere tan, wakati kan lati ki wọn.”

Onijala Ooni

“Ooni kii sun bi awa eeyan lasan se n sun, fifi ori le ibusun wọn yatọ”

Bakan naa ni Onijala Ooni tẹsiwaju pe fifi ori le ibusun Ooni yatọ nitori pe Ooni kii sun, bi awa eeyan lasan se n sun.

“Nitori pe Ooni kii sun bi awa eeyan lasan se n sun, orisirisi ohun ni a maa n fi pe Oonirisa, ko to dide nilẹ.

Nigba to n darukọ awọn Oonirisa to ti sun Ijala fun, ki wọn to waja, Oloye Omisore ni oun ni oun maa n sun Ijala fun Ooni Okuade Sijuade, Onibuse Keji.

“Mo tun ti bẹrẹ pẹlu Ooni Enitan Adeyeye Ogunwusi bayii, o ti pe ọdun mẹjọ bayii, ti mo ti bẹrẹ pẹlu wọn.

Ibi ti a ba yọju si bayii, awọn eeyan yoo ti mọ pe Ooni de, tori Ooni kọja yanmọ-yanmọ, Kayeefi, Olodumare Ọba ni.

Awa gan kii sun mọ Ọba pupọ pupọ tori Mo sun mọ Ọba niwọn egbeje, mo ri mọ Ọba niwọn ẹgbẹfa, arọbafin ni Ọba n pa.

Ooni tile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi

“Eeyan kii kọ Ijala nitori bi eeyan ba kọ Ijala, yoo kan jọ ni, ko le dabi atilẹbọlẹ”

Oloye Omisore, lasiko to n dahun si ibeere pe bawo lo se kọ Ijala sisun, ni eeyan kii kọ Ijala nitori pe yoo kan jọ ni amọ ko le dabi ti adayeba.

Ajogunba ni nitori ọdẹ gidi, ọdẹ Aperin, ọdẹ Apẹfọn ni awọn baba to bi mi lọmọ.

Koda, emi gan maa n dẹgbẹ, ti mo si ti pa ẹrin daadaa.

Mo si wa laarin ọmọ ọdun mẹfa si mejila ki n to mọ Ijala ke.

Èmi ni aago tó ń jí Ooni ní ìdáji, máà sì ki oríkì rẹ̀ di òru gànjọ́”

Onijala Ooni n kunlẹ ki Ooni

“Ijala, Ogede ati Ọfọ̀ ni a maa fi n rọ ọna fun Ooni, ki awọn ẹmi buruku le yago fun wa bi Kabiyesi ba ti n bọ .”

Bakan naa ni Onijala Ooni fikun pe yatọ si pe oun maa n ji ni idaji lati l ji Kabiyesi lori ibusun, ko si ibi ti Ooni n lọ, ti ko ni mu oun lọwọ.

“A dijọ maa n rin irinajo ni. A maa n rọ ọna fun Ooni ni ohun Ijala kikankikan pẹlu awọn ogede ati ọfọ.

Bi Kabiyesi ba ti n bọ, ni a maa pe awọn ogede yii tori awọn ẹmi buruku to wa ni ọna, ki wn le ya fun wa, ti Kabiyesi ba ti n bọ.”