Keir Starmer di Olóòtú ìjọba tuntun ní UK, kéde pé iṣẹ́ ìyípadà bẹ̀rẹ̀ lọ́gán

Keir Starmer

Asaaju ẹgbẹ oselu Labour nilẹ UK, Keir Starmer ti di Olootu Ijọba tuntun ni orilẹede naa bayi.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti ẹgbẹ oselu rẹ jawe olubori ninu idibo gbogbo gboo to waye lọjọbọ, ti wọn si kede esi rẹ lọjọ Ẹti.

Keir lo ti kọkọ lọ se ago laafin si Ọba ilẹ Gẹẹsi, Ọba Charles kẹta, ko to wa bawọn eeyan orilẹede UK sọrọ fun igba akọkọ.

Ninu ọrọ rẹ, Keir ni oun yoo maa jijagudu fun isejọba rere titi ti awọn araalu yoo fi ni igbagbọ ninu ohun ti ijọba lee se.

Bakan naa ni Olootun ijọba tuntun ọhun tọkasi awọn aseyọri isejọba to kogba wọle eyi ti Rishi Sunak dari rẹ.

Keir Starmer n ba awọn araalu sọrọ fun igba akọkọ bii Olootu ijọba UK

Oríṣun àwòrán, PA Media

"Maa se agbega awọn ohun eelo amayedẹrun nilẹ Gẹẹsi"

Ọlọla Keir lo farahan fun igba akọkọ ni ile Olootu Ijọba to wa ni ojule kẹwa, Downing Street lẹyin ti Ọba Charles Kẹta sọ fun pe ko lọ se agbekalẹ ijọba tuntun.

Keir Starmer ninu ọrọ rẹ salaye lasiko to n bawọn eeyan ilẹ naa sọrọ fun igba akọkọ pe igbesẹ lati mu iyipada rere ba ilẹ UK bẹrẹ lọgan.

Amọ o gba pe igbesẹ naa ko le rọrun rara bii igba ti eeyan fi ẹran jẹ ẹkọ.

O wa mẹnuba idi to fi yẹ ki ijba pese ọpọ ile ẹkọ ati ilegbe ti agbara mẹkunnu yoo ka.

Bakan naa ni Starmer fi ọwọ idaniloju sọya pe ijọba oun yoo jẹ isejọba to n sisẹ sin awọn araalu.

O si tun sọrọ nipa idi to fi yẹ ki wọn se atunto agbekalẹ orilẹede naa lọna to yẹ.

Olootu Ijọba tuntun nilẹ UK naa wa tọkasi awọn ipenija to n koju awujọ agbaye eyi ti ko jẹ ki eto aabo to peye wa.

Rishi Sunak, Olootu ijọba Gẹẹsi to fidi rẹmi ninu ibo kọwe fipo silẹ, sọrọ idagbere

Rishi Sunak

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak ti jade farahan gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n reti rẹ lati sọrọ idagbere rẹ.

Lẹyin eyi lo tun kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii Olootun Ijọba.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti adari ẹgbẹ oselu Labour ti jawe olubori ninu ibo gbogbo gboo to waye nilẹ UK, Ọlọla Keir Starmer, se kede pe Ilegbe awọn Olootu ijọba ni UK yoo too ni olugbe tuntun.

Sunak sọ pe oun yoo n lọ ba Ọba Gẹẹsi, Ọba Charles kẹta, lati kọwe fi ipo ọhun silẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ gẹgẹ bi Olootu ijọba.

Nibi ti Sunak ti n ba awọn eeyan sọrọ

Oríṣun àwòrán, PA MEDIA

"Ẹyin eeyan orilẹede mi, ẹ ma binu"

O sọ pe awọn eeyan ti fi erongba wọn lori idi ti wọn ṣe fẹ ayipada si ipo ọhun.

O ni gbogbo ohun to wa ni ikawọ oun, loun ṣe lati fi ara jin fun iṣẹ toun gba, ṣugbọn ti awọn eeyan ti wa safihan idi ti ijọba ṣe gbọdọ yipada.

“Si orileede, mo maa fẹẹ kọkọ sọ pe ‘ẹ ma binu si mi’.

“Mo ti fun iṣẹ yii ni ohun gbogbo to wa ni ikawọ mi, ṣugbọn ẹ ti fi han sita pe ijọba ilẹ Gẹẹsi gbọdọ yipada, ati pe ẹyin ni idajọ to ṣe pataki.”

O rawọ ẹbẹ si awọn oludije ati awọn olupolongo ti wọn ti “ṣiṣẹ takuntakun”, to si ni ẹgbẹ naa ko ṣe daadaa to.

“Mo ti gbọ gbogbo ibinu yii, ijakulẹ ati ti pe mo gba gbogbo ohun to ṣokunfa ijakulẹ yii,” Sunak tẹsiwaju.

O wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn oludije ẹgbẹ Tory ati awọn olupolongo ibo fun akitiyan wọn, to si ni o dun oun gidi bi ọpọ awọn akẹgbẹ oun ko ṣe nii jokoo ni ‘House of Commons’ mọ.

Sunak ni oun yoo kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oṣelu Tory, ṣugbọn to ni kii ṣe loju ẹsẹ loun yoo ṣe bẹẹ - ati pe o digba ti eto ba ti wa nilẹ fun ẹni ti yoo gba ipo lọwọ oun.

“O ṣe pataki wi pe, lẹyin ọdun mẹrinla nipo ijọba, awọn Conservative gbaradi, wọn si tun kopa gẹgẹ bi alatako lọna to ba ofin ati ilana mu pẹlu ọkan akikanju.”

"Orileede yii ti wa lagbara sii"

Bakan naa lo tẹsiwaju pe ojuṣe toun gba nigba toun di Olootu ijọba ni lati mu ki eto ọrọ aje fi ẹsẹ mulẹ.

O ni alekun ti pada si ohun ti wọn n fẹ, bẹẹni owo ori ọja ti ja silẹ, ti idagbasoke si ti pada sipo.

Sunak sọ pe orileede naa ti wa lagbara sii, to si ti di ohun aritọka si fun Windsor Framework post-Brexit ni ijọba Northern Ireland.

O fi kun pe ohun iwuri ni awọn aṣeyọri toun ṣe jẹ foun, to si loun nigbagbọ pe ilẹ Gẹẹsi ti tayọ kọja sisọ, to si tun dara ju ti ọdun 2010 lọ.

Bakan naa lo tun ki ẹni ti yoo gba ipo lọwọ rẹ, Sir Keir Starmer, ẹni to sọ pe aṣeyọri rẹ yoo tan kaakiri orileede wọn.

O ni wọn ti duro gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu alatako gidi, to si ṣapejuwe awọn olori ẹgbẹ Labour gẹgẹ bi awọn to ni ọkan akikanju toun bọwọ fun gidi.

“Oun pẹlu awọn mọlẹbi rẹ yẹ lati bu ọla fun nipa oye, pẹlu bi wọn ṣe n bọ si igbe aye tuntun lẹyin ilẹkun.”

Bẹẹ lo lọ ki awọn akẹgbẹ rẹ, to si fi idunnu han si wọn, to fi mọ iyawo ati awọn ọmọbinrin rẹ.

“Mi o le dupẹ lọwọ wọn yan fun akitiyan wọn ati ifẹ ti wọn fi han si mi lati sin orileede mi.

“Lara awọn ohun ti mo le maa tọka si ni bi ilẹ Gẹẹsi ṣe faaye gba oun lati di Olootu ijọba laarin iran meji ti asiko ti awọn babanla oun de ilẹ naa.

O wa ṣapejuwe ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi orileede to dara julọ lagbaye.

Aafin Buckingham fontẹ lu ikọwefipo silẹ Sunak

Aafin ilẹ Gẹẹsi, Buckingham ti fontẹ lu ikọwefipo silẹ Rishi Sunak.

Ọba ilẹ Gẹẹsi la gbọ pe o tẹwọ gba iwe naa.

Ninu atẹjade, aafin naa sọ pe;

"Ọnarebu Rishi Sunak MP ti ba Ọba sọrọ laarọ oni, to si ti jọwọ iwe ifiposilẹ rẹ gẹgẹ bi Olootu ijọba, ati alakoso eto iṣuna, eyi ti ọlọlajulọ si ti tẹwọ gba."

Àkọlé fídíò, UK Election: Wo ìdí tí àwọn èèyàn adúláwọ̀ ṣe mú ìdìbò ilẹ̀ UK tó ń bọ̀ ní ọ̀kúnkúndùn

Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party jáwé olúborí nínú ìdìbò UK

Olootu ile Gẹẹsi tuntun

Ọpọ nnkan lo ti ṣẹlẹ ni nnkan bii wakati meloo sẹyin.

Bi iwọ ba ṣẹṣẹ n ji lori ibusun rẹ, awọn ohun wọnyi lo ni lati mọ nipa eto idibo ilẹ Gẹẹsi to waye.

Pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu Labour ṣe ṣetan lati ṣakoso ilẹ Gẹẹsi bayii – pẹlu bi wọn ṣe pidan wọn nipa bibori aga mẹrindinlọgbọnlelọọdunrun (326) ti Westminster – Olootu ilẹ Gẹẹsi ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Sir Keir Starmer sọ fun awọn alatilẹyin rẹ pe: “O ti ṣe e”.

Nigba to n sọrọ ṣaaju Sir Keir, Olootu to fẹẹ gbe ipo silẹ, Rishi Sunak gba pe oun kuna, to si n sọ f’awọn eeyan rẹ wi pe oun gba ijakulẹ naa.

Ẹgbẹ oselu Labour Party si ti jawe olubori ninu eto idibo gbogbo gboo naa to waye nilẹ UK lọjọbọ.

Awọn esi ibo naa to ti n jade sita ti fihan pe Ọlọla Keir Starmer ni yoo jẹ Olootu ijọba tuntun nilẹ UK.

Awọn esi ibo yii lo fopin si isejọba ọlọdun mẹrinla ti ẹgbẹ oselu Conservative, ninu eyi ti Olootu ijọba marun ti dari orilẹede naa.

“Maa sọ orilẹede yii di ọtun”, ti maa si fi “ifẹ ilẹ UK se akọkọ, ti ifẹ ẹgbẹ oselu ti mo ti jade yoo si se ipo keji.”

Rishi Sunak, tii se Olootun ijọba ilẹ Uk to n fipo silẹ lo gba pe oun ti fidi rẹmi ninu eto idibo naa ni deede aago marun ku ogun isẹju ni owurọ ọjọ Ẹti.

Bakan naa lo tun faramọ pe ẹgbẹ oselu Labour lo bori idibo naa pẹlu afikun pe oun ti pe Ọlọla Kier lati ki pe o ku oriire.

Ninu ọrọ ijaweolubori rẹ, lẹyin ti wọn kede esi ibo naa, asaaju ẹgbẹ oselu Labour naa seleri lati “sọ orilẹede naa di ọtun”, ti oun yoo si fi “ifẹ ilẹ UK se akọkọ, ti ifẹ ẹgbẹ oselu ti oun ti jade yoo si se ipo keji.”

Agbẹjọro ajafẹtọẹni tẹlẹ ati agbefọba naa ni idi lati maa yọ - ẹgbẹ oselu rẹ ni yoo ni ijoko ile asofin to pọ julọ.

Isẹgun nla ni awọn esi ibo naa jẹ fun ẹgbẹ oselu Labour.

Ile asofin nilẹ Gẹẹsi, ti a tun n pe ni House of Commons ni ijoko awọn asofin ọtalelẹgbẹta o din mẹwa, ati awọn asofin ti iye wọn jẹ eyi.

Ijoko ikọọkan wọn lo n soju ẹkun idibo kọọkan tabi agbegbe kan to wa lorilẹede

Ọpọ awọn alẹnulọrọ ti Tories ni wọn ti padanu ipo wọn, to fi mọ Penny Mordaunt, Grant Shapps ati Jacob Rees-Mogg, bo tilẹ jẹ pe Jeremy Hunt ri anfaani diẹ lati pada si ipo rẹ.

Olori Lib Dem, Sir Ed Davey naa tun n fi oju sọna fun aṣeyọri nla, gẹgẹ bi eyito ga julọ lati ọdun 2019.

Ẹfọri lo jẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour ni ẹkun Islington North, nibi ti adari wọn tẹlẹ, Jeremy Corbyn ti leke gẹgẹ bi ẹni to da duro.

Ni igbakẹjọ ibeere, alakoso Reform UK, Nigel Farage naa tun bori ipo aṣofin, to si sọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ pe ẹgbẹ naa n bọ pada lati koju Labour ninu eto idibo to tun n bọ.

A ni opo iroyin to wa nilẹ lati mu wa fun un yin laarọ oni, fun idi eyi, ẹ duro pẹlu wa.

Aṣeyọri nla fun ẹgbẹ oṣelu Labour

Oṣelu, eee. Aṣeyọri nla ni eyii jẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour.

Ohun ti awọn eeyan sọ nibi ti wọn ti wa – the doldrums; ni pe esi ti wọn n mu lọdun 2019 ko dara, ati pe lati ọdun 1935 ni ko ti dara.

Ipin ibo wọn – nipa agbeyẹwọ lori bi wọn ṣe bori ile ti ko wọpọ yii – ko jẹ tuntun.

Sir Keir Starmer ni yoo jẹ Olootu nigba ti yoo ba fi di asiko ounjẹ ọsan, nigba ti wọn yoo ba lọ si adugbo Downing, nibi ti awọn eeyan pọ si

Ẹ ranti pe Olootu Keir Starmer ati Chancellor Rachel Reeves ni awọn eeyan ko ni pẹ ẹ mọ kaakiri, ati pe ijọba tuntun yoo koju gbogbo iṣoro ati adojukọ atijọ, eyi to ko awọn ti wọn gba ipo lọwọ wọn sinu wahala.

Igbe aye to le koko – eto iṣuna ijọba, ẹru gbese owo ori, ile aye to lewu, eyi ti ko si bi eeyan ṣe le pọ to le parẹ.

Laarin wakati diẹ, ilẹ Gẹẹsi maa too ni Olootu kẹrin laarin ọdun meji.

Awọn ohun apanilẹrin nipa bi Labour ṣe bori

Labour ti bẹrẹ sii rin lọna ti yoo mu wọn, eyi to fẹẹ mu wọn ja ẹgb

E Tory lulẹ kaakiri orileede naa. Ere wọn lori bi awọn eeyan ṣe gbaruki ti wọn n jẹ ti alawada pẹlu bi wọn ṣe n bori aami ayo mọkanlelogun pẹlu atilẹyin nla.

Wọnyi ni awọn ipo ti wọn padanu, eyi ti wọn ko tii padanu ri;

Aldershot - Conservative since 1918

Altringham - 1924

Chichester - 1924

Dorking - 1885

Tunbridge Wells - 1931

Ọ̀pọ̀ olùdìbò tú jáde láti kópa nínú ìbò sílé aṣòfin nílẹ̀ UK

Awon alakoso eto idibo

Ọ́pọlọpọ olugbe ni orilẹede United Kingdom (UK) lo tu jade lonii lati kopa ninu idibo yan awọn asofin ti yoo soju wọn nile asofin apapọ ilẹ naa ati ẹgbẹ oselu ti yoo gbe ijọba kalẹ.

Aago meje aarọ ọjọbọ oni ni wọn si awọn apoti idibo jakejado ilẹ UK, tawọn eeyan si ni anfaani lati dibo wọn.

Aago mẹwa alẹ ni eto idibo naa yoo wa sopin.

Awọn agọ idibo lo wa kaakiri awọn ẹkun idibo to to ọtalelẹgbẹta o din mẹwa (650) jakejado ilẹ England, Wales, Scotland ati Northern Ireland.

Kaadi idanimọ mejilelogun lo wa lati fihan ki oludibo to ni aaye lati dibo, to fi mọ iwe irinna, iwe aṣẹ lati wa ọkọ ati awọn iwe aṣẹ miran to le ni ọgọta

Eto idibo apapọ akọkọ ree, ti awọn oludibo lati ilẹ England, Wales ati Scotland yoo nilo lati fi kaadi idanimọ wọn han lojukoju, ko to di pe wọn dibo.

Kaadi idanimọ mejilelogun lo wa, to fi mọ iwe irinna, iwe aṣẹ lati wa ọkọ, iwe aṣẹ arugbo tabi awọn alaabọ ara lati wọ bọọsi, ati awọn iwe aṣẹ miran to le ni ọgọta.

Kaadi idanimọ mẹsan ọtọọtọ lo wa ki eeyan to le dibo ni Northern Ireland, eyi ti awọn oludibo yoo ṣafihan rẹ ko to di pe wọn dibo lati ọdun 2003.

Yatọ si eyi, awọn to ba fi orukọ silẹ lati dibo ṣugbọn ti wọn ko ni iwe aṣẹ gidi lati gba iwe aṣẹ ọfẹ miran lati dibo, eyi ni wọn pe ni ‘voter authority certificate’.

Agọ idibo

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ireti wa pe wọn yoo kede esi ibo ijoko ile asofin akọkọ nigba to ba ku diẹ ki aago mọkanla alẹ lu

Awọn oludibo ni England, Scotland ati Wales ti wọn ti sọ awọn kaadi idanimọ wọn nu, tabi ti awọn jaguda ti ji kaadi idanimọ wọn gbe naa, le sare lọ gba iwe pajawiri lati dibo, eyi ti wọn pe ni ‘emergency proxy vote’, titi di agogo marun-un irọlẹ ọjọ idibo, lati le jẹ ki awọn oludibo to fi roukọ silẹ le ba wọn dibo.

Awọn to lọ gba iwe idibo, ṣugbọn ti wọn ko tii da a pada le lọ daa pada ni ibudo idibo abẹle wọn lasiko ti eto idibo ba pari lagogo mẹwaa alẹ.

Bakan naa ni wọn tun le fa a le awọn alakoso lọwọ lasiko ti iṣẹ n lọ lọwọ.

Lẹyin naa ni eto kika ibo tawọn eeyan di, yoo bẹrẹ lọgan.

Ireti wa pe wọn yoo kede esi ibo ijoko ile asofin akọkọ nigba to ba ku diẹ ki aago mọkanla alẹ lu.

Amọ ti wọn yoo kede gbogbo esi ibo naa ko to di aago mẹsan aarọ ọla ọjọ Ẹti.

Ileesẹ iroyin BBC, gẹgẹ bi awọn ileesẹ iroyin agbohunsafẹfẹ miran, ni wọn ko ni gba laaye lati jabọ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ipolongo ibo tabi ọrọ idibo lasiko ti eto idibo ba bẹrẹ lonii.